Wo bí àwọn gbajúmọ̀ ṣe ń fi ogun Gaza pa owó wọlé sí àpò ara wọn

An Israeli woman mourning victims of a Hamas attack

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Grigor Atanesian
    • Role, Global Disinformation Team
    • Author, Grigor Atanesian
    • Role, Akọroyin
    • Reporting from, West Africa

Awọn gbajumọ kan ti bẹrẹ si n fi awọn aworan to le ba eeyan ninu jẹ sita loju opo X wọn, lara awọn aworan ti wọn n fi lede naa lo wa lara eyii yi awọn eeyan wo julọ lagbaye nipa ogun naa.s

Awọn gbajumọ naa, ti wọn ko mọ pupọ ninu ohun to n ṣẹlẹ lagbegba ọhun lo n sẹ awọn itu ti Hamsa n pa pẹlu awọran ti ẹrọ AI ya. Pupọ ninu wọn si ni ẹgbẹgbẹrun eeyan n tẹle loju opo ikansiraẹni lori iytakun agbaye.

Amọ ṣa ni ṣe lawọn gbajumọ naa n fi awọn ohun ti wọn n pin pa owo si apo ara wọn, gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ.

Lati ajafẹto nipa oju ọjọ si alatako orilẹ-ede Israel

Lara awọn gbajumọ naa ni Jackson Hinkle, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun wa.

Hinkle n pe ara rẹ ni MAGA (Make America Great Again), to si tun jẹ ololufẹ Aarẹ Russia, Vladimir Putin.

Lati oṣu ti ogun Gaza ti bẹrẹ ni awọn to n tẹle Hinkle ti le ni miliọnu meji si, ohun to n fi lede si ni awọn eeyan wo, ti wọn pin, ti wọn tun fẹran julọ loju opo X.

Idagbasoke oju opo rẹ naa da lori awọn ohun to n fi lede; eyii to jẹ awọn iroyin ẹlẹjẹ nipa ogun naa atawọn aworan to le ba eeyan ninu jẹ, eyii to n ṣafihan awọn ọmọde to farapa atawọn ile to dawo.

Bo tilẹ jẹ pe awọn aworan naa ko dara to, ọpọ eeyan lo fẹran lati maa wo ati lati pin iru rẹ.

Ayẹwo lati ileeṣẹ kan to maa n ṣewadii awọn iroyin ẹlẹjẹ lori ayelujara pẹlu AI, Logically, fi han pe ogun miliọnu igba lawọn eeyan ti pin awọn aworan ti Hinkle n fi lede.

Oun naa lo tun n kọ ida 75% ninu ọgọrun awọn iroyin ti awọn eeyan n pin julọ nipa Israel ati Gaza.

Ṣaaju ogun Gaza, Hinkle kii da si ọrọ ogun Israel ati Palestine, ọpọ eeyan si mọ ọ gẹgẹ bii ẹni to n ṣegbe lẹyin ijọba Russia.

Ṣaaju lo ti maa n fi ọrọ lede nipa Ukraine, Nazi, Russia ati Aarẹ Volodymyr Zelensky.

Amọ lẹyin ti Hamsa kọlu Isreal lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, lo bẹrẹ si n fi awọn iroyin to tako orilẹ-ede Israel lede.

O n fi orilẹ-ede Israel we ẹgbẹ agbesumọmi al-Qaeda.

 Jackson Hinkle cited a non-existent investigation by an Israeli newspaper
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O pin awọn aworan ati fidio ti BBC ṣe ayẹwo rẹ, ti a si ri aridaju pe o le ṣi eeyan lọna nipa ohun to n ṣẹlẹ loju ogun naa.

Ọkan lara rẹ ni fidio atijọ kan nibi ti Israel ti ju ado oloro si Gaza, eyii to n pin gẹgẹ bii ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ.

Omiran ni iroyin to sọ pe eeyan 900 pere lo ku lasiko ti Hamas kọliu Israel, nigba to jẹ eeyan 1,200 lo ku.

Koda, Hinkle sọ pe kii ṣe Hamas lo kọlu Israel lọjọ keje, oṣu Kẹwaa.

O ni kii ṣe Hamas lo ṣekupa awọn eeyan to n lọ sibi ayẹyẹ ‘Supernova Festival,’ o ni ṣe ni wọn pade iku wọn lọwọ ibọn ọlọpaa Israel.

“Hamas kọ lo jẹbi akọlu ọjọ keje, oṣu Kẹwaa” gẹgẹ bii ohun to kọ soju opo X rẹto ṣi wa nibẹ titi di akoko yi.

Amọ irọ nla ni, aworan ti BBC fidi rẹ mulẹ ṣafihan bi Hamas ṣe n dana ibọn ya awọn eeyan

Ninu ifọwerọ pẹlu BBC, Hinkle sọ pe ododo ni gbogbo ohun ti oun n fii lede.

O ni oun ko ṣe awọn ohun ti oun n ṣe nitori owo tabi ere kankan nitori o san ki eeyan k sidi ododo ju ko wa laaye lori irọ.

Awọn mii bii Hinkle

Kii ṣe Hinkle nikan lo n ṣe irufẹ nnkan bayii.

Mario Nawfal, to n fi ilu Dubai ṣebugbe ni gbajumọ miran to n ṣe irufẹ nnkan bẹẹ.

Bo tilẹ pe ko gbe sẹyin iha kankan ninu ogun naa, oun naa maa n pin iroyin nipa ogun ọhun fun eeyan miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun to n tẹle loju opo X.

Oniruru iroyin ẹlẹjẹ ni oun naa ti pin fun awọn lolufẹ rẹ.

Nigba ti BBC kan si lati sọrọ lori awọn iroyin ẹlẹjẹ to pin kiri, o kọ lati fun ileeṣẹ wa lesi.

 This false claim has been viewed over 18 million times

Awọn gbajumọ meji kan l’Amẹrika, Collin Rugg ati Dom Lucre, ni ẹgbẹgbẹrun awọn eeyan ti bẹrẹ si n tẹle loju opo X lẹyin ti wọn bẹrẹ si n sọrọ nipa ogun Gaza.

Bi Rugg ṣe n fi iroyin ẹlẹjẹ lede nipa awọn ọmọ ogun Hezbollah to n rekọja si Isral naa ni Dom Lucre n fi fidio atijọ lati Gaza lede nipa rogbodiyan naa.

Nigba ti McGee (to n pe ara rẹ ni Dom Lucree) ba BBC sọrọ, o ni oun ti dẹkun ati maa pin awọn iroyin nipa ogun naa, ati pe oun ko pin awọn iroyin naa ṣaaju lọna ati pa owo wọle.

Ni ti ọgbẹni Rugg, o kọ lati ba BBC sọrọ.

Pipa owo wọle lati ara nnkan ti awọn eeyan n sọ

Shayan Sardarizadeh, lati ẹka BBC Verify, n tọpinpin awọn nnkan ti awọn eeyan n fi lede nipa ogun Gaza, o si n tu aṣiri awọn to jẹ irọ nibẹ, paapaa loju opo X.

O ni oju opo ikansraẹni lori itakun agbaye maa n san owo fun awọn eeyan kan, ogun si pese ọpọ anfani fun awọ n eeyan lati maa ri ọrọ gbe jade.

O ni “Labẹ iṣakoso Elon Must, oju opo X n fun awọn eeyan lowo loṣoṣu lori iye ti wọn ba pa lori awọn ohun ti wọn n gbe jadeninu eyii ti ipolowo ọja ti farahan.

Wayi o, BBCi kan si ileeṣẹ X nipa awọn to n fi oju opo rẹ gbe iroyin ẹlẹjẹ jade lọna ati pa owo wọle.

X kọ lati dahun si ibere wa.