N35m náírà ni yóò ná wa láti gbé òkú ọmọ Nàìjíríà Emmanuel wálé láti Philippines- Ìjọba

Aworan Chibuikem Emmanuel

Oríṣun àwòrán, Chibuikem Emmanuel

Ile-iṣẹ to n moju to ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria ti wi pe yoo na awọn to miliọnu marundinlogoji naira lati gbe oku ọmọ Naijiria ti wọn pa si Philippines, Chibuikem Emmanuel, pada sile.

Emmanuel ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn afurasi ọmọ ilẹ China kan lu pa ni ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwa ọdun yii, gẹgẹ bi ọkunrin kan, Michael Ojuola, ṣe kọ si oju opo X rẹ.

Ojuola to pe ara rẹ ni ọrẹ Emmanuel lo kọọ si oju opo X rẹ pe wọn pa oloogbe naa ni ipakupa.

Ojuola wi pe “wọn di ọwọ rẹ, wọn fi aṣọ bo o loju ati ẹnu, wọn si na titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ”.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni adari ẹka to n moju to awọn to n ṣoju Naijiria nilẹ okeere nileeṣẹ fun ọrọ ilẹ okeere, aṣoju Enya Francis wi pe ileeṣẹ naa n kan si awọn aṣoju Naijiria nilẹ Philippines ti wọn si wa lori ọrọ iṣẹlẹ ọhun.

Atẹjade kan latọwọ Abdur-Rahman Balogun to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ naa wi pe Francis sọ ọrọ yii lakoko to n fesi sawon ibeere ti awon sẹnetọ ni fun-un lori iṣẹlẹ ọhun.

Francis wi pe “Naijiria yoo nilo to miliọnu mọkanlelọgbọn si marundinlọgbọn lati gbe ara oloogbe naa wale, anọ a ko nilo nju miliọnu mẹwa si mẹẹdogun lati sinku silẹ Philippines”.

O fi kun pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni awọn n san nile igbokupamọ si lojoojumọ, eleyii to fi yẹ ki wọn yanju ọrọ naa ni kia.

Àwọn afurasí ti wà nílé ẹjọ́ - Dabiri-Erewa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaga ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun (NiDCOM), Abike Dabiri-Erewa ti fi to awọn igbimọ tẹẹkoto ile aṣofin agba lori ọrọ awọn ọmọ ilẹ yii loke okun, ibaradọrẹ ijọba sijọba ati ọrọ ilẹ okeere pe ẹni to gba Emmanuel siṣẹ lorilẹ-ede Philippines ati awọn marun miran ni wọn ti fi ẹsun ipaniyan kan.

Lakoko to n jabọ igbiyanju ileeṣẹ rẹ fun awọn igbimọ ọhun ti Sẹnetọ Victor Umeh dari, Dabiri-Erewa wi fun wọn pe ileeṣẹ aṣoju ilẹ Naijiria ni Phillipines lo ti fi ọrọ naa to gbogbo awọn to yẹ leti nilẹ naa, ti ọga agba ajọ ọlọpaa nibẹ si ti gbọ sii pẹlu.

O wi pe awọn ọlọpaa to n ṣewadi ọrọ naa lo ti pari iwadii ti wọn si ti jabọ iwadii wọn fun ileeṣẹ ipẹjọ nilu Mandaue ti awọn naa si ti panupọ pe ẹsun ipaniyan ni abọ iwadii naa jẹ.

Dabiri-Erewa wi pe “wọn ti gbe ọrọ naa de ile-ẹjọ ti wọn si ti gba aṣẹ lati fi panpẹ ọba mu ọga oloogbe naa ati awọn miran.

Ẹsun ipaniyan, ikonilẹru ati idasilẹ iṣẹ ti ko gboore ọfẹ ijọba nilẹ Philippines ni wọn fi kan wọn.”

À n bẹ̀ yín ni, ẹ bá wa gbé òkú àbúrò mi wale - Ẹ̀gbọ́n Emmanuel

Ẹgbọn Emmanuel kan, Blessing Essien, lo ti rawọ ẹbẹ sijọba lati bawọn da oku aburo rẹ pada si Naijiria.

Essien lo bẹ ẹbẹ yii niwaju awọn igbimọ tẹẹkoto ile aṣofin agba to n wadi bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹ.

O wi pe Emmanuel ni ọkunrin kan ṣoṣo ti awọn obi ohun bi, yoo si dun mọ awọn ninu ti wọn le gbe e pada wale fun isinku ni ibamu pẹlu aṣa ilẹ Igbo.