Ìgbẹ́jọ́ Godwin Emefiele, gómìnà CBN tẹ́lẹ̀ tún kọsẹ́, ìdí rèé

Emefiele n wọ ile ẹjọ kan nilu Abuja

Oríṣun àwòrán, others

Igbẹjọ gomina tẹlẹ fun Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele tun fi ẹsẹ kọ gbongbo ọna lọjọru nitori iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ to n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria.

Ni ile ẹjọ giga apapọ to wa ni olu ilu Naijiria, Abuja lo ti yẹ ki igbẹjọ naa tẹsiwaju ṣugbọn didarapọ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lẹka eto idajọ, JUSUN darapọ mọ iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ to bẹrẹ lọjọ Aje ko jẹ ki ẹjọ naa le tẹsiwaju.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lẹka eto idajọ, JUSUN pẹlu paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati darapọ mọ iyanṣẹlodi ti NLC ati TUC pe lori bi awọn janduku kan ṣe din dundu iya fun aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni ipinlẹ Imo ni ọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2023.

Gbagbagba ni awọn iloro to wọ ile ẹjọ naa wa ni titi pa lowurọ Ọjọru ti awọn akọroyin de ibẹ.

Ni ọsẹ to kọja ni Onidajọ Olukayọde Adeniyi gba oniduro fun Emefiele lọsẹ to kọja.

Lọsẹ to kọja kan naa lo si paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS o jọwọ rẹ fun awọn agbẹjọro rẹ to fun ni aṣẹ lati maa mu u wa si ile ẹjọ fun igbẹjọ rẹ.

Wahala to de ba Emefiele

Emefiele ni ile ẹjọ giga kan l'Abuja

Oríṣun àwòrán, others

Gomina agba tẹlẹ fun banki apapọ Naijiria, CBN naa, Godwin Emefiele wọ gbaga wahala ni kete ti aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu yọọ nipo loṣu kẹfa.

Ọjọ keji ni awọn agbofinro DSS lọ gbe e si ahamọ ki wọn to fi oju rẹ ba ile ẹjọ ni ọjọ kẹtala oṣu keje ọdun 2023.

Ẹsun nini ibọn ati ohun ija oloro ni ikawọ ni wọn fi kan an niwaju onidajọ Oweibe, ṣugbọn Emefiele ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an naa.

Nigba to di oṣu kẹjọ ni DSS ba tun yi biri ti wọn si ni awọn ko tun fi ẹsun naa kan an mọ.

Ni kete ti wọn tu u silẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa ni ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ba tun gbe lọjọ yii kan naa.

EFCC kuna lati gbe Emefiele wa si ile ẹjọ lọjọ Aje ọsẹ to kọja ki ile ẹjọ to paṣẹ pe wọn gbọdọ fi han lọjọru ọsẹ to kọja kan naa fun igbẹjọ lori gbigba beeli rẹ, eleyi ti EFCC gbọran si.

Onidajọ Adeniyi gba beeli Emefiele lọsẹ to kọja naa, ti ireti si wa ṣaaju iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ pe yoo yọju sile ẹjọ lọjọru.