Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC yóò jókòó ṣe ìpàdé pọ̀ láti yanjú ọ̀rọ̀ ìyanṣẹ́lódì

Aworan awọn oṣiṣẹ nibi iwọde

Oríṣun àwòrán, NLC

Ijọba apapọ lorileede Naijiria ti kesi awọn aṣoju agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ,NLC ati TUC to gunle iyanṣẹlodi lati wa sibi ipade kan lọsan Ọjọru.

Eredi ipade yi ni bi wọn yoo ṣe wa wọrọkọ fi ṣada lori iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ jakejado Naijria lọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Naijiria Vanguiard ti ṣe jabọ, ileeṣẹ oludamọran si aarẹ lori ọrọ aabo,NSA lo pe ipade yi.

Lọjọ Iṣẹgun ni ẹgbẹ NLC ati TUC jijọ kede pe iyanṣẹlodi yoo bẹrẹ ti o si da lori ọrọ bi awọn janduku kan ti ẹgbẹ NLC lo n ṣiṣẹ fun ijọba ipinlẹ Imo ṣe dawọ jọ lu aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ,Joe Ajaero ni Owerri lọjọ Kini oṣu Kọkanla.

Wọn pinnu lọjọ Keje oṣu Kọkanla lati gunle iyanṣẹlodi ti ijọba ko ba wa nkan ṣe si awọn nkan ti wọn beere fun.

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ Kọkanla si ni ọjọ pe lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ọhun.

Yatọ si bawọn kan ṣe dawọ jọ da baniya fun aarẹ NLC Ajaero, awọn nkan mii naa wa ninu ẹhonu to ṣokunfa iyanṣẹlodi yi.

Lara wọn ni pe ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn fẹ ki wọn san gbese owo oṣu ti ijọba ipinlẹ Imo jẹ oṣiṣẹ ati bi ijọba ipinlẹ naa ṣe ka awọn ẹgbẹrun mọkanla oṣiṣẹ si ipo ayederu oṣiṣẹ ijọba.

Bẹẹ ni wọn lawọn fẹ ki wọn mojuto owo ifẹyinti ti wọn ko tii san ati sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ ffun oṣiṣẹ eyi tofin gbe lẹhin ni Naijiria.

Wọn tun sọ pe ijọba Imo kede awọn oṣiṣẹ fẹyinti ẹgbẹrun mẹwaa kan gẹgẹ bi ayederu oṣiṣẹ fẹyinti.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Bawo ni iyanṣẹlodi naa ṣe n lọ si

Lọjọ akọkọ ti o yẹ ki iyanṣẹlodi yi gbera sọ, iroyin taa ri lati ọwọ awọn akọroyin fi han pe ko fi tara tara gbalẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ṣe gbero.

Lawọn ipinlẹ kan awn oṣiṣẹ ko yọju si ibiṣẹ bẹẹ si ni wọn ti awọn ọfisi kan pa.

Nibomiran taa kan si bii ipinlẹ Osun ati olu ilu Naijiria Abuja, awọn oṣiṣẹ kan keti ikun si aṣẹiyanṣẹlodi yi ti awọn ile ifowopamọ si wa ni ṣiṣi.

Ni Eko lilọ bibọ ṣi n waye tawọn oṣiṣẹ ijọba si n ba iṣẹ wọn lọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ naa fesi si bi iyanṣẹlodi yi ko ṣe kari bi wọn ṣe gbero ti wọn si ni bẹẹ naa lo yẹ ko ri amọ igbesẹ ti nwaye lati ri pe aṣẹ yi di imuṣẹ jakejado laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Wọn ni ''gẹgẹ bi baalu to fẹ gbera, idiwọ ati ifasẹyin diẹ yoo waye amọ bo ba ti gbera tan ko ni si idiw kankan''

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2