Àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ dá ìyanṣẹ́lódì wọn dúró lẹ́yìn ọjọ́ méjì

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress HQ/X
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria ti da iyanṣelodi wọn duro lẹyin ọjọ meji ti wọn gunle iyanṣelodi ọhun lati fẹhonu han lori bi awọn eeyan kan ti lu aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero ni alubami nipinlẹ Imo.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ kede igbesẹ yii lalẹ Ọjọru lẹyin ti wọn ṣe ipade pọ pẹlu oludamọran ààrẹ lori eto abo, Nuhu Ribadu.
Ní ọjọ kinni oṣu Kọkanla yii ni aarẹ ẹgbẹ NLC pẹlu awọn olori mii ninu ẹgbẹ oṣiṣẹ gbero lati ṣe ifehonuhan niluu Owerri lori ohun ti wọn pe ni fifi ẹtọ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Imo dun wọn.
Amọ, ki ifehonuhan ọhun to bẹrẹ daadaa awọn ọlọpaa ti mu Ajaero ti awọn afurasí tọọgi t'awọn eeyan ni wọn n ṣiṣẹ fun gomina Hope Uzodimma si lu u ni alubami.
Eleyii lo jẹ ki ẹgbẹ oṣiṣẹ pe fun iyonipo ọga ọlọpaa to ṣaaju awọn ọlọpaa to mu Ajaero ki o si tun foju wina ofin.
Lẹyin naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC bẹrẹ iyanṣelodi lọjọ Aje tii ṣe ọjọ kẹtala oṣu Kọkanla yii
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








