Ikú kẹ̀, mọ wà láàyè o! Kò sí ikú lójú mi – Pásítọ̀ Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others
Pasitọ Ijọ irapada, The Redeem Christian Church of God, Enock Adeboye ti ni alaafia ni oun wa, pe nkankan ko se oun.
PasITọ Adeboye lọ sọ bẹẹ lasiko to n waasu ni ipagọ ijọ naa to waye ni ilu Eko.
Adeboye ti gbogbo eniyan mọ si ‘’Daddy G.O’’ ni adari agba patapata fun ijọ naa kaakiri agbaye.
Ṣaaju ni baba Adeboye ti sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ pe ki wọn gbadura ki Olorun pa oun ki ilẹ to mọ ti oun ba fi ohunkohun kun Ọlọrun sin.
Baba Adeboye ni lẹyin naa ni ọkan lara awọn ọmọ ijọ ohun pe pe ohun fẹ mọ alaafia rẹ, to si ni ohun fẹ gbọ̀ ohun rẹ boya o wa laaye lootọ.
Ni gbagede naa lo ti sọ fun gbogbo awọn ara ijọ rẹ pe nipa ifẹ olugbala ni oun wa laaye.
‘’Mo wa laaye o, Ọlọrun ko pa mi ki ilẹ to mọ, nitori Ọlọrun mọ pe nipa ifẹ rẹ ni mo fi n ṣe ohun gbogbo, oun nikan si ni mo gbẹkẹle’’
Lẹyin ọrọ naa ni gbogbo awọn ọmọ ijọ ho fun ayọ ti wọn si bẹrẹ si ni fo soke.
Awọn nkan miran ti Adeboye sọ...

Oríṣun àwòrán, Others
Saaju ni iroyin ti n fọ kaakiri pe adari ijọ Redeem naa lo n lo oogun abẹnugọgọ ni ijọ rẹ fi kun
Amọ Pasitọ Adeboye lasiko to n waasu ni alẹ Ọjọ Ẹti, to si ni oun fẹ yanana ọrọ naa.
Lẹyin lo ni ki awọn ọmọ ijọ naa gbadura ki Ọlọrun pa oun ki ilẹ to mọ, ti oun ba n fi dudu mọ funfun kun ipe oun.
Amọ o ni ki wọn gbadura to ba jẹ pe oun ko fi nkankan kun Ọlọrun sin, ki agbara ilọpọ meje jẹ ti ti oun.
Awọn eniyan lori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ si ni fesi, ti orukọ baba Adeboye si gba gbogbo ori ayelujara kan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3