Ìdí tí mo fi ta ọmọ-ọmọ mi fún N700,000 rèé

Oríṣun àwòrán, Oyo Police
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Monday Chuckwuka ti ta ọmọ ti ọmọ rẹ sẹsẹ bi fun ẹgbẹrun lọna ọọdẹgbẹrin naira.
Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, CP Adebola Hamzat ti fidi ọrọ naa mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Eleyele niluu Ibadan lọjọ Satide.
Hamzat ni ọwọ tẹ ọkunrin naa ni bi ti o sapamọ si niluu Ibafo, nipinlẹ Ogun.
Monday nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ salaye pe oun pinnu lati ta ọmọ naa nitori oun ko ni agbara lati tọ ọmọ rẹ to bimọ ati ọmọ to bi.
"Mo fi owo ti mo gba lẹyin ti mo ta ọmọ-ọmọ mi gba sọọbu, ti mo si ra ọja si.
"Mo pinnu lati gbe ọmọ naa ta nitori n ko ni agbara lati tọ iya ati ọmọ."
Iyawo Monday, Sarah ni oun ko mọ pe ọkọ oun ni erongba bẹ lọkan ati pe o kan sọ fun pe oun fẹ gbe ọmọ lọ si ọdọ awọn ti yoo se itọju rẹ ni.
"O ni wọn yo da ọmọ naa pada fun lẹyin ọdun meji, kop sọ nnkan fun mi rara ju pe oun fẹ gbe ọmọ lọ si ọdọ ti yoo tọju rẹ."
Arabinrin to ra ọmọ naa, Favour Chukwuka ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.
O ni, "Mo ra ọmọ lẹyin ti awọn tọkọtaya kan ti wọn ri ọmọ bi kan si mi, ẹgbẹrun lọna aadọta naira lo kan ninu owo naa."















