Ojú ogun ni Nàíjíríà wà, ẹ máṣe jẹ́ ká tanra wa jẹ - Adeboye

Pastor Adeboye

Oríṣun àwòrán, pastoreaadeboyeofficial

Alufaa agba ijọ Redeemed Christian Church of God, Enoch Adeboye, ti sọ pe irufẹ ipo ti Naijiria wa lọwọ yii ko yatọ si orilẹ-ede ti ogun n ja.

Adeboye lo sọ ọrọ naa lọjọ Aiku lasiko eto isin idupẹ ijọ naa to maa n waye loṣooṣu, eyiti wọn fi sọri ayẹyẹ ayajọ ọdun kejilelọgọta ti Naijiria gba ominira.

Ọrọ naa jade lasiko iwaasu to pe akori rẹ ni “Alaafia ni ilẹ naa,” to si mu ẹsẹ bibeli rẹ jade lati inu iwe 2 Chronicles 7: 13-14.

"Dipo ki wọn bu iyi fun Ọba laye ode oni, se ni wọn n ji wọn gbe"

Alufaa na sọ pe akoko alaafia ni igba ti ko ba si ogun ati iji, ati pe alaafia to peye ni akoko alaafia to pẹ, to si ni ìjì pin si oniruru ọna.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, laye igba kan, awọn eeyan maa n bu iyi fun awọn ọba alade, amọ bayii ṣe ni wọn n ji wọn wọn gbe.

O ni “Laye atijọ, wọn kii jẹ ki aṣọ ọba kan ẹnikẹni, ayafi ti ẹni naa ba jẹ eeyan pataki laarin ilu.”

“Laye ode oni, awọn ajinigbe le lọ si aafin ọba lati ji ọba gbe, oju ogun ni a wa o, ẹ maṣe jẹ ki ẹnikẹni tan yin jẹ.

"Ẹ maa gbadura fun awọn adari, bi emi naa se n gbadura fun wọn,"

Adeboye tun rọ awọn araalu nibi eto isin naa lati dẹkun ati maa bu atẹ lu akitiyan ijọba.

O ni ṣe lo yẹ ki awọn araalu maa gbadura fun awọn adari dipo ki wọn maa sọrọ kobakungbe nipa wọn.

O ni ko bojumu to bi awọn eeyan ṣe maa n tako awọn alaṣẹ nigba to yẹ ki wọn maa gbadura fun wọn.

Adeboye ni “Ẹ maa gbadura fun awọn adari... Mo n gbadura fun wọn, mo si gbagbọ pe ẹyin naa yoo darapọ mọ mi lati gbadura fun wọn.”

Lẹyin naa lo gbadura pe Ọlọrun yoo fopin si gbogbo laasigbo to n ba Naijiria finra laipẹ.