Olóṣèlú bẹ̀rẹ̀ àpárá tórí ọ̀pọ̀ olùwọ́de lẹ́yìn Peter Obi

Iná APC ń jó àjórẹ̀yìn pẹ̀lú bí àwọn ‘’Obidient’’ sẹ gbòde kan – Bwala
Ẹ̀bùn ọdún Kérésì ní Obi jẹ́ fún Tinubu - Omokri
Agbẹnusọ fun ikọ ipolongo idibo fun Atiku Abubakar, tii se oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ osẹlu PDP, Daniel Bwala ti fi ero rẹ lede lori iwọde to waye ni awọn olu ilu kaakiri orilẹede Naijiria fun oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi.
Ninu ọrọ to fi si oju opo Twitter rẹ, Bwala ni iwọde to waye ni awọn ilu naa, paapaa ni ilu Kaduna fihan pe ina ẹgbẹ oṣelu APC n jo ajorẹyin ni.
Awọn alatilẹyin Obi ti wọn n pe ni Obidient ni wọn ṣe iwọde oni miliọnu kan eeyan kaakiri awọn olu ilu ni Naijiria lati ṣe ayajọ ọjọ ominira Naijiria ni Ọjọ Kini, Osu Kẹwaa, ọdun 2022.
Amọ Bwala lasiko to n sọrọ nipa bi awọn ero naa ṣe pọ to ni Atiku lo jẹ ki Obi di ilu mọọka, eleyii ti o ni o ṣafihan pe APC ti n fidi rẹmi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
‘’Iwọde Peter Obi ni Kaduna fihan pe El-Rufai ti kuna ni ilu rẹ.’’
Bwala ni "Eleyii kii se ẹgbẹ oselu PDP, Labour ni o, ti awọn eniyan si n wọ tẹle wọn bayii.’’
Eyi fihan pe adari nla ni Atiku Abubakar nitori o gbagbọ ninu ẹya Igbo, ti o si jẹ ki Obi di ilu mọọka.
Bakan naa ni Bwala fihan pe Atiku ti fidi rẹ mulẹ pe lẹyin oun, ẹya Igbo ni yoo di ipo aarẹ mu ni Naijiria.
Bakan naa lo fikun un pe o da oun loju pe Obi ti gba iṣakoso iha Guusu orilẹede Naijiria, ti APC nipinlẹ Eko ko si lagbara to bi wọn ṣe ro.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3
O ṣe ni laanu pe Peter Obi ko lee di ipo aarẹ mu ni idibo 2023 - Reno Omokri
Amọ ninu ọrọ rẹ, Reno Omokri ti ni Obi ko le wọle gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun 2023, awọn eniyan kan n tẹle lasan ni.
Omokri fi ero rẹ yii lede loju opo Twitter rẹ lasiko to n sọrọ nipa iwọde ‘’Obidient’’ ọhun.
O ni Obi gan an ni yoo ran Tinubu lọwọ lati ri pe o bori ninu idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.
Reno Omokri ni aarin Atiku ati Tinubu ni ijakadi fun ipo aarẹ ọdun 2023 wa.
O ni ẹbun keresimesi to wa saaju ọdun ọhun ni Obi jẹ fun Tinubu nitori awọn eniyan yoo dibo fun lọgọọrọ.
Amọ o gboriyin fun Obi to ko ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan jọ, ti wọn si tu yaya jade lati ṣe atilẹyin fun
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4

End of X post, 5