Wo awọn ìjọ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí kì í ṣe ọdún Kérésìmesì

Aworan awọn eeyan to jokoo ninu ile ijọsin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu gbogbo ọdun laye, Keresimesi ni wọn fun ni inagije ọdun alarinrin.

Idi eyi ni pe pọpọṣinṣin ọdun naa maa n pọ, ibi gbogbo a maa dan gbinnrin.

Gẹgẹ bi igbagbọ awọn ẹlẹsin Kristi, ọdun Keresimesi n ṣami ìbí Jesu olugbala ni, ẹni ti a gbọ pe wọn bi si ibujẹ ẹran ni ilu Bethlehem, ti ìbí rẹ si yatọ, to jẹ mimọ lati ode ọrun.

Bi wọn ṣe wa ya ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kejila ọdun sọtọ fun ọjọọbi Jesu kaakiri agbaye, awọn ijọ ẹlẹsin igbagbọ kan wa ti wọn ki I ṣe ọdun yii.

Wọn ka a si ohun to lodi si ifẹ Ọlọrun ati itọni Bibeli.

Wọnyi ni diẹ ninu awọn ijọ naa

  • Ẹlẹ́rìí Jehovah

Awọn ti wọn n ṣe ijọ yii ni a mọ si ajẹrii tabi ẹlẹrii Jehova.

Wọn ka Keresimesi si ọdun ibọriṣa, ati pe Bibeli ko fi ẹsẹ rẹ mulẹ, ko si pa Kristẹni laṣẹ lati maa ṣe Keresi.

Ọdun1920 ni wọn dẹkun ṣiṣẹ ọdun naa, nigba ti wọn ṣe iwadii nipa ipilẹ rẹ.

  • Deeper Life Bible Church — Ijọ yii sọ pe Keresi ko si ninu Bibeli, wọn ki i ṣe e.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) — Ijọ yii naa gba pe ọdun ibọriṣa ni Keresimesi, wọn ki i ṣe e.

  • Armstrongite Churches of God

Awọn ijọ bii United Church of God, Living Church of God, Philadelphia Church of God ati awọn mi-in ti wọn yapa lati ara ijọ kan ti a mọ si Worldwide Church of God tẹlẹ lo wa labẹ eyi.

Wọn ki i ṣe Keresimesi, olori wọn Herbert W. Armstrong, kọ Keresi silẹ nitori o ni ọdun ibọriṣa ni, ti ko si akọsilẹ fun un ninu Bibeli.

  • True Jesus Church

Ijọ yii naa maa n kede ajinde Jesu, ṣugbọn wọn ko gba pe Keresimesi wa ninu Bibeli.

Churches of Christ (Restoration Movement):

Awọn naa ki i ṣe Keresimesi, igbagbọ wọn ni pe ko si ninu Bibeli.

Wọn ni ọdun ibilẹ ni, ẹni to ba wu u le ṣe e, ẹni ti ko ba wu, ko fi i silẹ, nitori ko kan ẹsin rara.

  • God's Kingdom Society — Awọn ijọ yii ri ara wọn bii ẹgbẹ́, wọn n ṣe Keresimesi, ṣugbọn ki i ṣe loṣu Kejila.

Oṣu Kẹwaa ọdun ni wọn n ṣe Keresimesi tiwọn.

  • Iglesia ni Cristo

Ijọ to dide lati ara Philippines yii ki i ṣe Keresimesi, wọn ni ko si ninu Bibeli, ọdun ẹbọ ni.

Iglesia ni Cristo yii naa ni a tun mọ si INC, to tumọ si Church of Christ.

  • Awọn miran tun ni:

Free Church of Scotland, Free Presbyterian Church of Scotland, Associated Presbyterian Churches.

Awọn ijọ ilu oyinbo yii gba pe ijọ katoliiki aye ọjọun lo ṣe Keresimesi, wọn ni ko sibi ti Bibeli ti darukọ rẹ.

  • Quakers (Ijọ ẹlẹsin/ akojọpọ ọrẹ)—

Awọn yii gba pe gbogbo ọjọ ni mimọ, wọn maa n yago fun isinmi to ba ti ni ti ẹsin ninu.