Kí ló ń mú káwọn ọmọdébìnrin tètè gúnmú, ṣe nǹkan oṣù lásìkò yìí?
Ibeere to n gba ọkan awọn eeyan lasiko yii ko sẹyin bi ọpọ awọn ọdọ se n tete balaaga lasiko yii.
Ọrọ naa si kan awọn ọmọdrbinrin pupọ tori ọpọ wọn ni kii pẹ, ti wọn fi n yọ loju afra.
Ọpọ obi si lo n kọminu pe ki lo de tawọn ọmọdebinrin asiko yii fi maa n tete gun ọmọ, ti wọn yoo si maa se nnkan osu.
Akọsilẹ fihan pe lasiko yii, awọn ọmọdebinrin n bẹrẹ nnkan osu lati ọmọ ọdun mẹsan si mọkanla eyi ti ko ri bẹẹ lati ẹyin wa.
Idi ree ti BBC News Yorùbá, nínú ètò ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó kan àwọn obìnrin, ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ dókítà ìdí tí àwọn ọmọbìnrin ṣe tèté ń gún ọmú, máà ṣe nńkan oṣù ní ìran tí a wà yìí.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Dokita Samuel Faturoti salaye pe ọpọ nnkan to n mu kawọn ọmọbinrin tete balaga.
"O le jẹ ajẹbi nigba miran, eyiun ti iya to bi ọmọbinrin naa ba tete balaga, o see se ki ọmọ naa tete balaga.
Bakan naa, awọn ounjẹ ti wọn n jẹ lasiko yii bii ẹran, awọn ounjẹ protein ati ounjẹ inu agolo gan le fa a ki obinrin tete balaga.
Awọn ounjẹ yii maa n tete mu ki ọmọ dagba ninu ara, eyi to si tun n mu ki wọn tete balaga.
Awọn ounjẹ to tun dun, tawọn ọmọ ode oni n jẹ, paapaa ni awọn orilẹede to ti goke agba gan tun n jẹ kawọn ọmọde tete balaga.
Yatọ si eyi, awọn kẹmika kan to wa ninu nnkan oloorun didun ti wọn n fin sara bii spray ati perfume gan maa n jẹ ki ọmọde tete balaga."
O wa rọ awọn obi lati mase bẹru bi ọmọdebinrin wọn ba tete balaga amọ ki wọn fun ni ẹkọ ibalopọ tori o seese fun lati loyun, to ba sun mọ ọkunrin.
Ẹkunrẹrẹ ohun ti dokita sọ wa ninu fidio oke yii.






