Wo bí ọmọtuntun jòjòló ṣe le gbé ọlẹ̀ míì sínú látinú ìyá rẹ̀, tí ikùn rẹ̀ yóò sì ga bíi olóyún

Àkọlé fídíò, Foetus in foetus
Wo bí ọmọtuntun jòjòló ṣe le gbé ọlẹ̀ míì sínú látinú ìyá rẹ̀, tí ikùn rẹ̀ yóò sì ga bíi olóyún

Airin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, bí èèyàn bá rìn jìnnà, yóò rí ibi tí wọn ti ń fi odó ìbúlẹ̀ jẹun.

N jẹ o mọ pe o seese kí ọmọdé jòjòló gbe oyún sínú láti inú ìyá rẹ?

'Foetus in Fetu' tàbí 'foetus carrying foetus' ni àwọn oloyinbo ń pè irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí èyí tó túmọ̀ sí pé ọlẹ ń gbé inú oyún.

BBC News Yoruba wa se iwadii ohun to n fa ki oyun kan maa gbe ọlẹ miran sinu, ipa rẹ lori ọmọ tuntun ati ohun ti obi le se ti irufẹ isẹlẹ yii ba waye.

Awọn ọlẹ in oloyun

Bawo ni oyun se maa n gbe ọlẹ̀?

Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò wọpọ, sugbon o máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọlẹ̀ méjì ba wa ninu alaboyun bíi Ibeji.

Bi ọkàn nínú ọlẹ méjèèjì náà kò bá dàgbà bo ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bíi ìkejì rẹ, to si ni àléébù, ó seese kí ọlẹ̀ kejì to ń dàgbà dáadáa gbé ọlẹ̀ tó ní àleebu mì

Ọlẹ̀ tó ní aleebu náà yóò sì máa dàgbà nínú ìkejì rẹ lásìkò tí wọn wá nínú ilé ọmọ iya wọn.

Àmọ́ ọlẹ̀ yìí tún seese kò máa dàgbà nínú ìkejì rẹ bíi oyún, tí àwọn aabọ ẹ̀yà ara rẹ bíi agbari tàbí ẹyin yóò sì máa dàgbà, ọmọ kékeré yóò sì dabi ẹni pé ó gbé oyún sínú.

Kí ni ọ̀nà àbáyọ?

Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà máa n tètè ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò tó di pé oyún inú ọmọdé náà yóò ga fún ayé rí, tí wọn yóò sì ṣe iṣẹ́ abẹ fún un láti yọ ọlẹ̀ abaadi to ń dàgbà nínú ọmọ tuntun náà kúrò.

Tóò, tí ó bá lóyún tàbí ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, jọ̀ọ́ ṣe àkíyèsí ara rẹ tàbí ọmọ tuntun tí ó bá bí aibaamọ ọmọ tuntun náà lè tí gbé ọlẹ̀ sínú: kí ó sì gbé igbesẹ̀ tó yẹ nípa lílọ sì ilé ìwòsàn tó kúnjú iwon fún itoju lasiko.