Wo ohun mẹ́ta tí oríṣi gèlè wíwé ń sọ àti ohun tí ọ̀nà márùn-ún tí a ń gbà dé fìlà ń wí
Ni ilẹ Yoruba, onírúurú ọna mẹta ni àwọn obìnrin ń gba we gèlè.
Wọn máa ń we gele si iwaju, ẹyin tàbí ẹgbẹ.
Ikọọkan ọna mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọn ń gba we gèlè yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn.
Bákan náà ni fìlà dìde, ọ̀nà márùn-ún ni àwọn ọkùnrin ń gba de fila wọn.
Wọn le de fila sì ọwọ́ iwájú, ẹyin, ẹgbẹ́ ọ̀tun tàbí òsì tàbí kí wọn na fìlà náà gogoro sì òkè
Ikọọkan ọna maraarun tí wọn ń gba de fila yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn.
BBC News Yorùbá wà ṣe àkójọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí obìnrin ń gba wé gèlè àti ọ̀nà márùn-ún tí ọkùnrin ń gbà gẹ fìlà pẹ̀lú ohun tí àwọn ìlànà náà túmọ̀ sí.

Ìtumọ̀ kí obìnrin dé gèlè sí iwájú, ẹyin àti ẹgbẹ́?
Ìgbàgbọ́ Yoruba ni pé bí àwọn obinrin to wa nile ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele wọn sì ọwọ́ iwájú.
Ìdí ni pé tiwọn ni ayé ń gbọ́.
Bákan náà, wọn gbagbọ pé àwọn obìnrin tó ti di arúgbó lọ máa ń we gele si ọwọ́ ẹyin.
Èyí túmọ̀ sí pé ọjọ́ wọn tí di alẹ.
Àmọ́ ọmọge to ń wá ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele rẹ sì ọwọ́ ẹgbẹ́.
Ìtumọ̀ ọna márùn-ún tí àwọn ọkùnrin ń gba de fila
Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì ọwọ́ iwájú, ó túmọ̀ sí pé ayé dun jẹ ju ìyá lọ, sì ń bẹ lọ́wọ́ iwájú.
Bí wọn ba gẹ fìlà sì ọwọ́ àlàáfíà, ó túmọ̀ sí pé ọkùnrin bẹẹ tí ní ìyàwó nílẹ̀.
Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì apá ọ̀tún, ó túmọ̀ sí pé apọn ni, kò ti ní ìyàwó nílẹ̀, ó sì ń wá ìyàwó.
Bí ọkùnrin bá sì gẹ fìlà sì ọwọ́ ẹyin, ó túmọ̀ sí pé kò sí ohun tuntun lábẹ́ ọrùn mọ.
Àmọ́ tí ọkùnrin kan kan ṣe fìlà rẹ gogoro, ó túmọ̀ sí pé ó ń sọ fún àwọn èèyàn pé ẹni ńlá ni òun.
Ibo wá ní ẹyin ń kọ ojú fìlà àbí gele yín sí?



