Àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà, Oyewole Olowomojuore, tí a mọ̀ sí Bàbá Gébú, dágbére fáyé

Baba Gebu wọ aṣọ òtútù, dúró sójú títí, gbogbo irun orí àti irungbọ̀n rẹ si funfun

Oríṣun àwòrán, KunleAfod / Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikú tí pa àgbè, bíi ẹni tí kò le è da aro

Ikú tí pa Aluko bíi ẹni tí kò lè pa Osun

Ikú tí pa Lekenleke bíi ẹni tí kò lè pa ẹfun

Ikú tún ti pa àgbà òṣèré miran ni agbo tíátà Yorùbá.

Gbajúmọ̀ alawada àti odu ni agbo tíátà, Ọmọọba Oyewole Olowomojuore, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Gebu lo jade laye.

Gbajugbaja òṣèré tíátà nni, Kunle Afod lo kede ikú Baba Gebu ni ojú òpó ayélujára Instagram rẹ̀.

Ìrọ̀lẹ́ òní ni àgbà ọjẹ òṣèré tíátà náà dágbére fáyé.

Bàbá Gébú joko sori aga, ó wọ aṣọ leesi aláwọ̀ ojú ọrùn, ó sì dé fìlà aṣọ oke aláwọ̀ waini

Oríṣun àwòrán, Baba Gebu/Facebook

Bàbá Gébú wa lara awọn Agba ọjẹ òṣèré tíátà to dúró sínú ẹgbẹ́ àwọn òṣèré ANTP nigba ti àwọn òṣèré kan lọ da ẹgbẹ́ TAMPAN silẹ

Gẹ́gẹ́ bíi Afod tí wí, àìsàn ranpẹ lo ṣe Baba Gebu to fi tẹrí gbasọ.

Oloogbe Olowomojuore wa lara awọn Agba ọjẹ òṣèré tíátà to dúró sínú ẹgbẹ́ àwọn òṣèré ANTP nigba ti àwọn òṣèré kan lọ da ẹgbẹ́ TAMPAN silẹ.

Nígbà ayé rẹ̀, baba Gebu tí kopa ninu ọ̀pọ̀ ere tíátà lórí telifisan àti sinimá.

Lara awọn ere tíátà tí Baba Gebu tí kopa ni Kengbe ọrọ, Aare Agbaye (1983), Anikura (1982) Citation (2020) àti àwọn ere tíátà miran ni orisirisi.

Ìkéde ikú Baba Gebu tí Kunle Afod gbé soju opo Instagram rẹ̀

Oríṣun àwòrán, KunleAfod/Instagram