Ilé ẹjọ́ ju bàbá tí wọn fẹ̀sùn kàn, pé ó lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ẹni tó fipá bá ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún márùn-ún lòpọ̀, sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n

Ọwọ́ tí wọ́n so ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́, tó wà ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ilé ẹjọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Rivers ti fi bàbá kan sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn pé ó lọ̀dí àpòpọ̀ mọ́ afurasí kan tí wọ́n ní ó fi ipá bá ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún lòpọ̀.

Adájọ́ Rita Oguguo fi bàbá náà sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí agbẹjọ́rò rẹ̀ yọjú sílé ẹjọ́ pé òun kò ṣe ẹjọ́ lórí ọmọ òun tí wọ́n fi ipá bá lòpọ̀.

Ó ní òun àti afurasí náà ti fẹnukò láti má ṣe ẹjọ́ mọ́.

Afurasí, tó ń jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ẹy ọ̀kan, ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fipá bá ọmọbìnrin, ọmọ ọdún márùn-ún lòpọ̀ ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin ní ìlú Odagwa, ìjọba ìbílẹ̀ Etche ní ìpínlẹ̀ Rivers.

Afurasí náà ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n kan òun náà.

"O ṣeéṣe kí bàbá ọmọ náà ti gba owó lọ́wọ́ afurasí tó bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ láì bìkítà ọjọ́ iwájú ọmọ náà"

Ilé ẹjọ́ ní àwọn kò faramọ́ ìwé tí bàbá ọmọ náà kọ láti fi sọ pé òun kò ṣe ẹjọ́ mọ́.

c

Adájọ́ Oguguo pàṣẹ pé kí wọ́n fi bàbá ọmọ tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ náà sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ míì máa wáyé.

O ni baba naa yoo wá wí tẹnu rẹ̀ lórí irú ìfẹnukò tí òun àti afurasí náà ṣe.

Adájọ́ ní ẹ̀sùn tí afurasí náà ń jẹ́jọ́ lé lórí jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó lòdì sí abala kejìlélọ́gbọ̀n ìwé òfin Rivers State Child Rights Law ti ọdún 2002.

Kí ni òfin sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti yanjú ìwà ọ̀daràn tó ti wà nílé ẹjọ́ ni wọ́n le fi sí àhámọ́ tí wọ́n sì lè gbe lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn pé ó fẹ́ ṣèrànwọ́ láti bo ìwà ọ̀daràn."

Èyí ni ọ̀rọ̀ tí alágà tẹ́lẹ̀ rí fún ẹgbẹ́ International Federation of Women Lawyers, FIDA tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Rivers, Adata Bio-Briggs sọ.

Ó wòye pé ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ẹbí yóò gbìyànjú láti máa yanjú irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ kúrò nílé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ẹ̀sùn náà bá wà nílé ẹjọ́.

Ó ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí máa ń mú kó ṣòro láti ṣe àṣèyọrí lórí ṣíṣe ẹjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Bio-Briggs ní òbí tó bá gba owó lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn tó bá ṣe irú ìwà ọ̀daràn báyìí náà ń dá ẹ̀ṣẹ̀.

"Tí ẹni tó bá pe ẹjọ́ lórí irú ìwà ọ̀daràn báyìí bá padà lọ sẹ́yìn láti lọ wá ọ̀nà yanjú ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣeéṣe kí wọ́n fòfin gbé òbí bẹ́ẹ̀ kí òun fojú ba ilé ẹjọ́ pẹ̀lú àfurasí bẹ́ẹ̀."

"Nígbà tí ẹjọ́ bá ti wà nílé ẹjọ́, ní ilé ẹjọ́ ni afurasí àti ẹbí ti lè fẹnukò lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe láti pẹ̀tù sí aáwọ̀ tó bá wáyé láàárín wọn, kò yẹ láti gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ láì sí ìmọ̀sí iléẹjọ́.

"Tí afurasí bá gbà pé òun jẹ̀bi, tó sì fẹ́ kí àwọn yanjú ọ̀rọ̀ láì lo òfin, ilé ẹjọ́ ló máa sọ irú nǹkan tí wọ́n máa fún àwọn ẹbí. Kìí ṣe ẹbí ló máa lọ gba owó lẹ́yìn, tó máa wá ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sílé ẹjọ́ pé òun kò ṣẹjọ́ mọ́.

"Ẹbí ò lè sọ pé àwọn kò ṣẹjọ́ mọ́ nítorí ìjọba ni wọ́n ń bá ṣe ẹjọ́ kìí ṣe ọmọdé lásán."

"Ẹbí tó bá gbowó lọ́wọ́ afurasí láì sí ìmọ̀sí ilé ẹjọ́ máa jẹ́jọ́ kan náà pẹ̀lú afurasí"

Bio-Briggs ṣàlàyé pé ilé ẹjọ́ tó wà fún ọ̀rọ̀ mọ̀lẹ́bí nìkan ni ilé ẹjọ́ tó máa ń fi ààyè gba ìdájọ́ láti fi mú àtúnṣe wáyé tó sì sọ pé lábẹ́ òfin tó de ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé, ọmọ náà ní ẹ̀tọ́ tó yẹ láti gbà.

Bákan náà ló rọ àwọn ẹbí tí wọ́n ń kojú irú ìṣòro báyìí láti máa ní ìgbàgbọ́ nínú ilé ẹjọ́ láti rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí wọ́n yé máa gbẹ̀yìn lọ gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

"Kò yẹ láti máa gba owó nítorívó yẹ kí àwọn ọmọ tó bá kojú irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí rí ìdùnnú pé àwọn gba ìdájọ́ òdodo.

"Kí àwọn òbí àti alágbàtọ́ máa fi ààyè fún àwọn ilé ẹjọ́ láti báwọn ṣe ìdájọ́ òdodo, kí àwọn tó bá lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí má ba à má rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n lò."

Bio-Briggs tó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé sọ pé ẹbí tí wọ́n bá rí tó ń gba owó lọ́wọ́ afurasí tí ilé ẹjọ́ kò buwọ́lù ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, tó òun náà yóò sì jẹ́jọ́ kan náà pẹ̀lú afurasí.