Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ẹ̀dínwó bá owó èròjà oúnjẹ́, kí ló fà á?
Yoruba ni tie bi ba ti kuro ninu isẹ, isẹ buse.
Bẹẹ si ni orisa bii ọfun ko si, ojoojumọ lo n gba ẹbọ lọwọ ẹnu.
Ko si ojumọ kan, ti a ko ni fi ọwọ sẹnu lati jẹun amọ bi owo awọn eroja ounjẹ naa se gbe owo lori, lo n kọ ọpọ idile lominu.
Ariwo lori ọwọngogo ọja naa si lo gbode lati igba ti ijọba Tinubu ti yọwọ kuro lori sise eto iranwọ lori owo eroja epo rọbi.
Sugbọn iroyin ayọ lo jẹ fun ọpọ ọmọ orilẹede yii lati ri pe ẹdinwo ti n bao wo awọn eroja ounjẹ naa.

Ki lo fa ẹdinwo owo eroja ounjẹ?
Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori owo eroja ounjẹ ati awọn ọja miran to ti n wa silẹ naa.
Awọn eeyan kan ni tori pe a w ani asiko ojo, ti ikore oko maa n waye ni owo ọja se n lọ silẹ ni akoko yii.
Awọn miran ni oju ọjọ to dara fawọn agbẹ lati gbin ire oko lo faa, ero awọn miran si ni pe eto aabo to gbogbọn si ni .
Amọ sa, awọn miran ni ijọba apapọ lo seto bi wọn se ko ọpọ eroja ounjẹ wọ orilẹede yii wa lati ilẹ okeere eyi to mu ki ẹdinwo ba eroja ounjẹ.
Koda, ẹgbẹ awọn agbẹ lorilẹede Naijiria, All Farmers Association of Nigeria (AFAN), gbagbọ pe fun igba diẹ ni ẹdinwo naa yoo fi wa nitori igbesẹ to n mu adinku bao wo ounjẹ naa yoo sisẹ fun igba diẹ ni.

Se lootọ ni owo ounjẹ ti wa silẹ, iwadii BBC ree:
Idi ree ti BBC News Yoruba fi se abẹwo si awọn ọja ti wọn ti n ta eroja ounjẹ kaakiri ilẹ Kaarọ Oojire.
BBC de Ọja Bodeija nilu Ibadan, Ọja tuntun ni Osogbo, Ilorin ati Abeokuta.
Afojusun wa ni lati mọ bi owo ọja se dinwo si, ka si tun se awari ipa ti ẹdinwo ounjẹ naa yoo ni lori awọn olokoowo ounjẹ.






