Mo fẹ́ padà sí ilé ẹ̀kọ́ láti le ṣe àtúnṣe ọjọ́ ọ̀la mi - Portable

Oríṣun àwòrán, Instagram/Portablebaby
Gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable, ti ni oun ti n gbero lati pada si ile ẹkọ lati le ni oye si i ati lati le mojuto awọn orin to n gbe sita ati okowo rẹ
Portable sọ eyi ninu fọnran kan to gbe sita loju opo ayelujara Instagram nigba to n sọrọ nipa ọna to fẹ gba lati mu ki iṣẹ orin kikọ rẹ tẹsiwaju ati bi o ṣe jẹ ilumọka.
Portable pari iwe ẹkọ giga National Diploma (ND) ni ile ẹkọ gbogbonṣe ipinlẹ Kwara, to si pinnu pe oun nilo lati ka iwe siwaju si, lati le ṣe akoṣo ileeṣẹ rẹ, Zeh Nation.
"Kii se ki n le gba iwe ẹri nikan ni mo se fẹ pada sile ẹkọ, ṣugbọn lati le fi imọ kun imọ, ni oye kun oye ti mo ni tẹlẹ nipa iṣẹ orin"
O ni, "Bo ti lẹ jẹ pe mo ti ni iwe ẹri OND lati ile ẹkọ gbogbo niṣe Kwara, mo si fẹ tẹsiwaju si.
Mo n ran awọn eeyan ati awọn ọmọ mi lọ si ile ẹkọ, lati yẹra fun iroyin pe 'Portable ko lọ si ile ẹkọ'.
Fun idi eyi, mo fẹ pada lọ si ile ẹkọ lati le mojuto ati ni oye nipa okowo orin ṣiṣe daada, paapa fun ileeṣẹ orin mi, Zeh Nation."
Portable, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ni bi oun ṣe fẹ pada si ile ẹkọ ko ni ṣe pẹlu gbigba iwe ẹri nikan, ṣugbọn lati le fi imọ kun imọ rẹ ati lati ni oye kun oye to ni tẹlẹ nipa iṣẹ orin.
Portable, yatọ si pe o jẹ olorin takasufe ti ọpọ eeyan mọ, o tun jẹ ọpọ eeyan ti ẹnu ma n kun lori iwa kan tabi omiran.
Ki lo ti sẹlẹ si Portable tẹlẹ?
Lọdun 2025, Gbajugbaja olorin fuji, Okunola Saheed, ti ọpọ mọ si "Saheed Osupa" fi ọlọpaa mu olorin takasufe, Portable.
Osupa fi ẹsun kan Portable ti ẹsun naa si da lori ibanilorukọjẹ, idunkoko mọni ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni bi ẹsun naa se wuwo to lo faa tawọn fi gba asẹ ni ile ẹjọ Majisireeti Kwara ti awọn si tẹsiwaju lati mu afurasi ọhun.
Bakan naa ni ile igbafẹ kan ti a mọ si Starwood 02 Arena niluu Ilọrin, naa sọ pe, ọlọpaa Kwara mu Portable lori ẹsun ti awọn fi kan-an wi pe o jẹ awọn ni owo ti iye rẹ le ni milliọnu mẹfa naira.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ta a ni Portable, Were Olorin, Idaamu Adugbo?
Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Habib Okikiola ti a mọ si Portable, amọ adugbo Sango Ota ni wọn bi si, to si gbe Mushin Olooṣa dagba.
Ni ipari ọdun 2021 ni Habeeb Okikiọla kan lu agbami orin takansufe kikọ, nigba ti orin to kọrin pẹlu gbajumọ olorin Ọlamide ati gbajumọ onijo kan, ti ọpọ mọ si Pocolee.
Orin Zeh to kọ naa, ti di gbajugbaja kaakiri agbaye, to si ti yi igbe aye rẹ pada.
Lati igba ti orin rẹ naa si ti di aigbọdọ maa kọ nibi ariya ati ile ijo gbogbo ati lẹnu tonile talejọ, Portable ti ṣe alabapade awọn agbaagba onkọrin bii Wizkid ati Davido.
Portable sọ fun BBC News Yoruba pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ orin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko orin Zeh.
Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin, Portable salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo o, lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.















