Wo kókó ẹ̀sùn tí EFCC kà si ọrùn gómìnà àná ní Bayelsa, Timipre Sylva, tí wọn fi kéde pé wọ́n ń wá a

Oríṣun àwòrán, Timipre Sylva/Facebook
Ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti kede pe awọn n wa minisita fun epo rọọbi ti ipinlẹ tẹlẹ, to tun jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Bayelsa, Timipre Sylva.
Atẹjade ti agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale buwọlu fun awọn akọroyin salaye pe ẹsun ti wọn n wa Sylva fun da lori ẹsun pe o ṣe owo to le ni miliọnu mẹrinla Dọla, $14,859,257 mọkumọku.
EFCC ni owo yii lo jẹ pe ileesẹ to n tọpinpin awọn ileesẹ ifọpo nilẹ okeere (Nigerian Content Development and Monitoring Board for Atlantic International Refinery) ati ileesẹ to wa fun ipese eroja epo rọbi, (Petrochemical Limited) lo pese rẹ.
Oyewale tun fikun pe, orukọ Sylva tun ti wa ninu orukọ awọn ti ajọ FBI lorilẹede Amẹrika ati ileesẹ ọlọpaa ajumọse ni agbaye, INTERPOL, nilẹ UK, Canada ati awọn orilẹede mii n wa bayii.
Gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ Sylva, Julius Bokoru ṣe sọ saaju, Sylva ti wa lorilẹede Gẹẹsi lọwọ yii.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe igbẹjọ ti wa fun igba pipẹ, ti minisita tẹlẹ naa si n wa si ọfisi ajọ EFCC ko to di pe o kọ lati wa mọ.
"Idi ree ti wọn fi kede pe wọn n wa lori FBI, Interpol ati awọn awọn ajọ mii."
Oyewale ni EFCC gba aṣẹ lọwọ ile ẹjọ giga ni ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla ọdun 2025, pe ki wọn fi ọwọ ofin mu Sylva.
Adajọ D.I. Dipeolu lo gbe aṣẹ naa kalẹ, to si paṣẹ fun awọn ẹsọ alabo pe ki wọn lọ mu Sylva pe ko wa pese idahun si awọn ibeere ti wọn n bi.
Igbesẹ lati ṣe iwadii lori owo ti Sylva ṣe mọkukọku waye ni oṣu to kọja nigba ileeṣẹ aṣofin kekere fẹnuko lori ẹsun ti owo toto $35m ti ajọ NCDMB ṣe mọkukọku, ti wọn ko si le ohun patọ ti wọn fi ṣe ni agbegbe Niger Delta.
Abadofin yii ni Aṣofin Billy Osawaru gbe wa si ile, ti awọn ti ọrọ kan si ti kọ lẹta si ajọ EFCC ni ọdun 2024 pe ki wọn se iwadii owo ti NCDMB gba, to fi mọ owo Atlantic, ti ajọ naa si kọ lati sọ ohunkohun.
Lẹyin yii ni ile igbimọ aṣofin kekere pasẹ pe ki iwadii waye lori owo ti ajọ naa se mọkumọku, ti wọn si wa fun ile ni esi laaarin ọsẹ mẹrin.
Sylva, Gomina tẹlẹri nipinlẹ Bayelsa ati eekan ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ni ẹnu ti n ku lẹyin ti awọn ologun yawọ ile rẹ ni ọjọ Kẹdọgbọn oṣu kẹwaa pe o lọwọ ninu iditẹgbajọba.
Aburo rẹ, Paga, to tun jẹ oludamọran rẹ pataki ati dirẹba ọkọ rẹ ni ọwọ tẹ, Sylva wa ni oke okun lasiko naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki ni Sylva sọ lori ẹsun yii?
Oluranlọwọ pataki fun Sylva, Julius Bokoru, Sylva wa ni United Kingdom lọwọ yii.
O ni oun iyalẹnu pe oun ti wọn sọ ṣaaju pe o lọwọ ninu iditẹgbajọba ti di ṣiṣe owo ilu mọkumọku lojiji.
O sọ, " Wọn ko ba sọrọ kankan, wọn ko ranṣẹ pe, wọn ṣadede gbe aworan rẹ bọ sita lati fi da wahala silẹ ni igbooro.
"Kodo ohun ti wọn tẹlẹ ni pe o lọwọ ninu iditẹgbajọba, to si di pe o di siṣe owo ilu mọkumọku lojiji."
Ta a ni Timipre Sylva?
Timipre Sylva ni wọn bi ilu Brass, nipinlẹ Bayelsa. O kawe gboye nipinlẹ Bayelsa ati ipinlẹ Eko.
O jẹ asọfin ni ile igbimọ aṣofin ti ipinlẹ Rivers ko to di gomina ipinlẹ Bayelsa.
Sylva kawe gboye ẹkọ fasiti lati ile ẹkọ giga fasiti Port Harcourt, to leke ninu imọ Gẹẹsi ni ọdun 1986.
Irinajo Sylva sinu oṣelu bẹrẹ lodun 1992 nigba to wọle idibo si ile igbimọ aṣofin ti ipinlẹ Rivers ṣaaju ki wọn to yọ ipinlẹ Bayesla jade.
Lasiko ti wọn Aarẹ nigba kan lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan gẹgẹ bii igbakeji aarẹ si Aarẹ Umaru Yar adua, Sylva di oludije sipo goomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Bayelsa, eyi to bori.















