Ní ọjọ́ tí mo gba ọ̀pá àṣẹ Ọba ìlú Eko, ni mo ṣàdúrà pé kí Tinubu di ààrẹ Nàìjíríà - Ọba Akiolu

Ọba Rilwan Akiolu wọ aṣọ òfì, kó ìlẹ̀kẹ̀ sọ́rùn, mú ìrùkẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọba ìlú Eko, Rilwan Akiolu ti sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ pé ní gbogbo ọdún méjìlélọ́gbọ̀n tí òun lò lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá, òun kò fi ọjọ́ kankan gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rí.

Ọba Akiolu sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn Tribune sọ̀rọ̀ láti sàmì ayẹyẹ ọdún méjìlélọ́gọ́rin lórí òkè eèpẹ̀ àti ọdún méjìlélógún tó ti wà nípò Ọba ìlú Eko.

Ó ní nídìí iṣẹ́ ọlọ́pàá, ẹni tó máa ń sọ ọ́ bó bá ṣe ri ni wọ́n máa ń pe òun, nítorí òun ní ìgbàgbọ́ nípa ṣíṣe òótọ́ àti òdodo.

"Iṣẹ́ ọlọ́pàá ló kọ́ mi ní ìkoraẹni ní ìjanu, ìgboyà àti ṣíṣe déédéé.

Ìmọ̀ràn mi fáwọn ọlọ́pàá òde ni pé kí wọ́n máa fi òótọ́ inú ṣiṣẹ́ wọn, kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì jìnnà sí ìwà ọ̀kánjúà."

"Ìpínlẹ̀ Eko nílò àtúntò tó yẹ, mo faramọ́ ìgbésẹ̀ láti sọ Eko di ọ̀tun àmọ́ n kò fẹ́ bí wọ́n ṣe ń lé àwọn èèyàn kúrò nílé wọn"

Ọba tilu Eko wa tẹsiwaju pe "Láti ìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni mo ti máa ń gbàdúrà pé kí n di olórí lọ́jọ́ kan, tí Ọlọ́run sì gba àdúrà mi.

"Ní ìpínlẹ̀ Eko àti Nàìjíríà lápapọ̀, ìwà ọ̀kánjúà àti àìkora ẹni ní ìjanu ló ń ṣe àkóbá fún àwọn èèyàn."

Lórí ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú Eko, Ọba Akiolu ní ìlú Eko jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá, tó máa ń gbe onílé àti àlejò.

Ó fi kun pé ìpínlẹ̀ Eko nílò àtúntò tó yẹ, tí òun sì faramọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba ń gbé láti sọ Eko di ọ̀tun àmọ́ òun kò faramọ́ bí wọ́n ṣe ń lé àwọn èèyàn kúrò nílé wọn.

Ọba Akiolu ní gbogbo àwọn ẹ̀yà tó wà ní Nàìjíríà ni òun ní ìbọ̀wọ̀ fún, tí ìlú Eko sì máa ń fi ààyè gba gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ìlú Eko ṣe ibùjókòó.

"Nígbà tí èèyàn kan kọ̀wé sí mi lẹ́yìn tó kéde ara rẹ̀ bíi Obi ìlú Eko, mo sọ fún pé ọ̀rọ̀ òfin ni, kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ oyè, a sì gbọdọ̀ fún òfin láàyè láti ṣiṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀."

"Jim Ovia fí ọkọ̀ mẹ́rìn àti ọ̀pọ̀ owó lọ̀ mí ṣùgbọ́n mo kọ gbogbo rẹ̀, mo bèèrè fún kíkọ́ ilé ìwòsàn alábọ́dé dípò ẹ̀bùn"

Ọba Akiolu ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni òun ti kọ́ láti ìgbà tí òun ti gba ipò Ọba ìlú Eko.

Ó ní lára ẹ̀kọ́ tí òun kọ́ ni láti súnmọ́ Ọlọ́run ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Ó fi kun pé òun kẹ́kọ̀ọ́ láti yé máa fi igbá kan bọ òmíràn nínú, kí òun sì máa sọ òótọ́ ní gbogbo ìgbà.

"Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí mo jọba ìlú Eko, Jim Ovia fí ọkọ̀ mẹ́rìn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ̀ mí ṣùgbọ́n mo kọ gbogbo rẹ̀.

Mo sì bèèrè fún ilé ìwòsàn alábọ́dé fáwọn èèyàn agbègbè dípò dípò wọn.

"Òun ló fa ilé ìwòsàn alábọ́dé tó wà ní ààfin mi yẹn.

Irú àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn olórí máa fẹ́ láti fi lélẹ̀ nìyẹn dípò pípa owó sí àpò ara wọn.

"Ní ọjọ́ tí mo gba ọ̀pá àṣẹ Ọba ìlú Eko, ni mo ṣàdúrà pé kí Tinubu di ààrẹ Nàìjíríà"

Ọba Akiolu ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kìí ṣe olóṣèlú, òun mọ̀ pé àwọn olóṣèlú kìí bá ara wọn ṣọ̀tá.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ yan Tinubu gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà.

"Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2003 tí mo gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Eko ni mo sọ fún Ọlọ́run pé Tinubu máa di ààrẹ Nàìjíríà lọ́jọ́ kan."

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump sọ lórí ikú àwọn Kristẹni ní Nàìjíríà, Ọba Akiolu ní àwọn èèyàn kan ni kò ṣe òótọ́ pẹ̀lú Trump.

Ó ní ọ̀kan náà ni àwọn Mùsùlùmí àti Kristẹni ní Nàìjíríà, tó sì jẹ́ pé àwọn méjéèjì ni ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí ń ṣe jàmbá fún.

Ó sọ pé láti ìgbà ìṣèjọba ààrẹ Jonathan ni òun ti gbà á nímọ̀ràn láti gba àwọn òṣìṣẹ́ si ṣùgbọ́n tí inú òun dùn pé Nuhu Ribadu ni olùbádámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ààbò báyìí nítorí ó ní ìmọ̀ tó pọ̀ nípa orílẹ̀ èdè yìí.

Ta ni Ọba Akiolu?

Rilwan Babatunde Osuolale Aremu Akiolu, tii se Ọba ilu Eko ni wọn bi ni ọjọ kọkandinlọgbọn osu Kẹwa ọdun 1943.

Ọjọ kẹrinlelogun osu Karun ọdun 2003 ni Akiolu jẹ ọba Eleko tilu Eko.

Lẹyin to pari eto ẹkọ rẹ, Akiolu wọ isẹ ọlọpaa ni ọdun 1970, to si sisẹ kaakiri titi to fi gba oye igbakeji ọga agba ọlọpa pata nilẹ wa lọdun 1999.

O sisẹ ọlọpaa fun ọdun mejilelọgbọn gbako, to si fi ẹyin ti lọdun 2002.

Ni ọjọ Kẹtalelogun osu Karun ọdun 2003 ni awọn afọbajẹ nilu Eko yan Akiolu bii ọba.

Lẹyin naa ni ijọba ipinlẹ Eko fi ontẹ lu gẹgẹ bii ọba Kọkanlelogun fun ilu Eko.

Oba Adeyinka Oyekan lo waja, ti Ọba Akiolu fi jẹ ọba lẹyin rẹ.