Ọba Ladoja ké sí Trump láti yọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ Nàíjíríà torí agbéṣùmọ̀mí kò mọ ìyàtọ̀ láàrin Mùsùlùmí àti Kristẹni

Oríṣun àwòrán, Rashidi Ladoja/Facebook
Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ti sọrọ lori isẹlẹ lo n fa awuyewuye lorilẹede Naijiria bayii, eyi to ni se pẹlu ikede aarẹ Amẹrika, Donald Trump lati wa gbe awọn Kristẹni ni Naijiria nija.
Ọba Ladoja da si ọrọ naa lásìkò tó gbàlejò ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni, Pentecostal Fellowship of Nigeria, PFN, Bíṣọ́ọ̀bù Francis Wale Oke ní ààfin rẹ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump fi kàn pé ,wọ́n ń pa àwọn Kristẹni ni Naijiria pẹ̀lú èròńgbà àti pa wọ́n run, Ọba Ladoja ni àwọn agbéṣùmọ̀mí kò mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn Mùsùlùmí àti Kristẹni nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ láabi wọn.
Ó ní àwọn agbéṣùmọ̀mí máa ń rí gbogbo èèyàn bíi ẹni tí wọ́n le ṣe ìkọlù sí.
"Trump, yọwọ́ lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà torí àwọn agbéṣùmọ̀mí kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹlẹ́sìn kan sí òmíràn"
Àtẹ̀jáde kan tí akọwe feto iroyin fun Ọba aláyé náà, Adeola Oloko, fi léde lọ́jọ́ Àìkú, rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dìde, kí wọ́n fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ láti gbógun ti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí títí tó fi máa di ohun ìgbàgbé.
Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn agbéṣùmọ̀mí ti dá ẹ̀mí wọn légbodò, tí ọ̀pọ̀ dúkìá náà sì ti ṣòfò lórí àwọn ìkọlù náà.
Ó fi kun pé, ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí, pàápàá obìnrin àtàwọn ọmọdé, ni kò nílé lórí mọ́ látàrí ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Ọba alayé náà wá pàrọwà sí Ààrẹ Donald Trump láti yọwọ́ lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà bó ṣe ṣèkìlọ̀ pé àwọn agbéṣùmọ̀mí kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹlẹ́sìn kan sí òmíràn.
"Ìdí nìyí tí mo fi ń rọ Ààrẹ Pentecosatal Fellowship of Nigeria, tó jẹ́ ẹ̀ka CAN, láti pàrọwà sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n ń bínú lásìkò yìí láti fi ọwọ́ wọ́nú nítorí ipele tí Nàìjíríà wà báyìí ṣì máa di ohun ìgbàgbé.
Ki ni Aarẹ Amẹrika sọ ti Olubadan se n parọwa?
Àrọwà Olubadan yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump fẹ̀sùn kàn pé àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam ń pa àwọn Kristẹni lọ́nà àìtọ́ ní Nàìjíríà.
Lára ẹ̀sùn tí Trump fi kàn ni pé ìpànìyàn náà ń wáyé lójúnà àti pa àwọn Kristẹni run, tó sì ní pé Amẹ́ríkà kò ní fọwa lẹ́rán láti máa wo kí ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀síwájú.
Trump ní òun máa kó àwọn ọmọ Amẹ́ríkà wọ Nàìjíríà lójúnà àti ṣe ìdádúró bí wọ́n ṣe ń pa àwọn Kristẹni.
Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà sọ pé Amẹ́ríkà kò ní ìmọ̀ kíkún lórí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.
Ọ̀rọ̀ tí Trump sọ yìí ló ti ń fa awuyewuye káàkiri Nàìjíríà, bí àwọn ṣe ń ṣe àtìlẹyìn fún Trump ni àwọn míì ń sọ fún Trump láti ṣe pẹ̀lẹ́ lórí bí ó ṣe máa dá sí ọ̀rọ̀ ààbò Nàìjíríà.
Àwọn kan ní ohun tó yẹ kí Trump ṣe ni láti ṣe ìrànwọ́ fún Nàìjíríà láti gbógun ti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń bá Nàìjíríà fínra.















