Ọ̀dọ́mọbìnrin 15 gba ìtúsílẹ̀ lóko iṣẹ́ aṣẹ́wó l'Ondo

Oríṣun àwòrán, ONDO POLICE COMMAND
O kere tan, awọn ọdọbinrin mẹẹdogun, ti wọn fa mọra, ti wọn si tan wọn jẹ pe ki wọn wa sisẹ amọ ti wọn ni wọn n fi wọn se owo nabi, ni ileesẹ ọlọpaa Ondo ti gba silẹ.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Olusola Ayanlade, fi sita lọjọ Aiku, lo ṣisọ loju ọrọ yii.
Bakan naa lo salaye pe ọwọ sinkun awọn ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi to n fi awọn obinrin naa se okoowo nabi.
Atẹjade naa salaye pe ileesẹ ọlọpaa Ondo ti sawari awọn olokoowo nabi kan ti wọn gbajumọ bii isana ẹlẹẹta, ti wọn maa n ko awọn ọdọbinrin sisẹ nabi nigba ti wọn n dibọn pe awọn fẹ wa isẹ fun wọn, paapaa lori ayelujara.
Ayanlade ni ẹka ileesẹ ọlọpaa naa to wa fun iwadi nipa awọn ohun ija oloro ati agbekalẹ aato lo gbera lati tan ina iwadi wọn si isẹlẹ naa ni kete ti awọn kan fi ẹsun naa to wọn leti.
"Bi wọn se gbọ nipa isẹlẹ naa ni awọn osisẹ ta n pe ni SWAT yii mu ọkunrin kan, Jayeola Joshua, ni adugbo Alagbaka nilu Akure, pẹlu eeyan meji miran.
Bakan naa, aayan ti n lọ lati mu awọn afurasi yoku ti wọn jẹ alabasisẹpọ wọn, eyi si se afihan aayan ileesẹ ọlọpaa lati daabo bo awọn araalu."
Atẹjade naa wa fikun pe iwadii awọn nibẹrẹ isẹlẹ naa fihan pe awọn ẹgbẹ imulẹ to n fa oju awọn ọdọbinrin mọra naa wa kaakiri awọn ipinlẹ yika orilẹede Naijiria.
"Awọn eeyan yii si lo maa n seleri asan pe awọn yoo gba awọn ọdọbinrin naa sisẹ to lowo lori pupọ.
Lara awọn isẹ ti wọn si maa n fi tan awọn ọdọbinrin naa jẹ ni isẹ sise ọmọ ọdọ ninu ile, isẹ pinpin ounjẹ lagbo ariya ati lilọ soke okun fun isẹ aje."
Ileeṣẹ ọlọpaa fikun pe "ni kete ti awọn de ilu Akure, awọn eeyan mẹẹdogun to ko agbako awọn ikọ afinisowonabi naa ni ọwọ tẹ, awọn ọdọbinrin naa si lo wa laarin ogun ọdun si ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.
Awọn ọdọbinrin naa ni wọn ko sinu ile kan ni adugbo Alagbaka, tii se ibudo ti wọn ti n fi awọn obinrin naa sisẹ ibi ọhun."
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ti wi, yatọ si pe igbesẹ yii fun ikọ naa lanfaani lati yan awọn ọdọbinrin naa jẹ, se ni awọn afurasi ọdaran naa tun n lo ilakaka awọn ọdọbinrin ọhun lati sisẹ, maa fi wọn huwa ko tọ.
O fi kun un pe itẹsiwaju iwadii fi han pe wọn tun tan awọn ọmọbinrin yii lati maa fi fọto ati fidio ihoho wọn ranṣẹ.
Awọn foto ati fidio naa ni wọn yoo si pada fi ṣọwọ si awọn onibaara to n wa ẹni ti wọn yoo ba lo pọ.
" Eekan ninu awọn afurasi yii ni a gbọ pe o n gba eyi ti pọju ninu owo ti wọn ba pa, wọn yoo si maa dibọn pe eto ori ayelujara lasan ni awọn n ṣe. — Wọn n fi eyi tu awọ eeyan jẹ, ṣi wọn lọna, wọn si n daṣọ bo iṣẹ aburu gan-an ti wọn n ṣe."
Bẹẹ ni atẹjade naa wi.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa gbọ pe wọn diidi gba ile ti wọn n lo fun iṣẹ to lodi yii ni, ki wọn le ri aaye ti wọn yoo ti maa ṣiṣẹ ibi naa.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti paṣẹ ki wọn wa ẹni to kọ ile naa wa, lati wa sọ ti ẹnu rẹ.
Bí kíkó àwọn èèyàn lọ fún ìlòkulò ṣe ń gbilẹ̀ si ní Naijiria
Kiko awọn eeyan lọ fun ohun ti ko tọ lati ibi kan si ibomiran ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ni Naijiria, koda, lara awọn ipenija ti orilẹede naa n koju ni.
Gẹgẹ bi ajọ International Organisation for Migration,ṣe ṣalaye, o to ẹgbẹrun mọkanla (11,000) obinrin ọmọ Naijiria ti wọn ko lọ soko ẹru nipa gbigba agbami oku Mediterranean ni 2016.
Eyi tun pọ si i pẹlu bo ṣe kuro ni 1,454 to wa ni 2014.
Pupọ ninu awọn obinrin naa ni wọn si fipa mu lati maa ṣiṣẹ aṣẹwo.
Abọ iwadii UNHCR kan ti wọn ṣe ni 2018, fi han pe o to ẹgbẹrun mejidinlogun (18,000) ọmọ Naijiria ti wọn de Europe nipa gbigba agbami okun Mediterranean ni 2017.












