Iye ṣúgà mélòó ni ara nílò láti dènà níní ìtọ̀ ṣúgà?

Àwọn obìnrin méjì tí wọ́n gbé abọ́ oúnjẹ dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Global Journalism team, World Service
    • Author, Near East Visual Journalism team, World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ó dára láti mọ iye ṣúgà tí ara nílò lójúmọ́ nítorí ó máa ń rọrùn láti jẹ ju iye ṣúgà tí ara nílò lọ tí èèyàn kò sì ní fi iyè si.

Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé ṣúgà jẹ́ ohun tí èèyàn nílò láti wà ní ìlera pípé àmọ́ bó ṣe ní ìwúlò tó náà ni kò tún gbọdọ̀ pọ̀jù.

Tí ṣúgà bá pọ̀jù lára, ó le ṣokùnfà àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, àìsàn ọkàn kódà tó fi mọ́ jẹjẹrẹ.

Káàkiri àgbáyé ni àwọn èèyàn ti ń gbìyànjú láti mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe ń sanra pẹ̀lú bí ara àsanjù àti àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ṣe ń fi ojoojúmọ́ pọ̀ si.

Ìwádìí kan tí The Lancet ṣe sọ pé tó bá máa fi di ọdún 2025, ìdàjì àwọn àgbàlagbà ni wọ́n máa sanra ku bí ó ṣe yẹ lọ nígbà tí ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn ọmọdé tó wà ní àgbáyé ló máa sanra ju bí ó ṣe yẹ lọ.

Lára àwọn nǹkan tó máa ń ṣe ìdíwọ́ fún àwọn èèyàn láti mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe ń sanra ni àwọn ṣúgà tó máa ń wà nínú mílìkì, búrẹ́dì, àtàwọn oúnjẹ míì tí à ń jẹ lójúmọ́.

Èyí ló jẹ́ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò iye ṣúgà tó yẹ kí èèyàn máa jẹ àtàwọn nǹkan tó yẹ láti máa ṣe láti mú àdínkù bá ìpalára tó le ṣe fún ara.

Obìnrin tó wà níwájú àwọn nǹkan aládùn

Oríṣun àwòrán, BBC, Getty Images

Kí ni àwọn oúnjẹ tí kò ní ṣúgà túmọ̀ sí?

Yógọ́ọ̀tì àtàwọn ẹlẹ́rìndòdò tí à ń yọ lára èso máa ń fara jọ pé wọ́n kò ní ṣúgà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ìyàlẹ́nu ibẹ̀ ni pé tí èèyàn bá ń jẹ àwọn oúnjẹ yìí, ó ṣeéṣe kí iye ṣúgà tí èèyàn yóò jẹ lójúmọ́ ju iye tí àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization sọ pé kí èèyàn máa jẹ lọ.

Gíráàmù ọgbọ̀n ṣúgà ló tọ́nà fún àgbàlagbà láti jẹ. Èyí jẹ́ àpapọ̀ ṣúgà tó ń wá nínú àwọn oúnjẹ, nǹkan mímu, oyin, àtàwọn oúnjẹ míì.

Bí ara ṣe máa ń fọ́ àwọn ṣúgà sí wẹ́wẹ́ yàtọ̀ síra, tó spi níṣe pẹ̀lú iye ṣúgà tó bá wà nínú oúnjẹ kan.

Tí ṣúgà tó wà lára èèyàn bá lọ sókè fún ìgbà pípẹ́, ìṣòro kan tó máa ń wáyé ni ni pé insulin èèyàn bẹ́ẹ̀ kò ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

Bákan náà ni àwọn oúnjẹ inú agolo máa ń dá kún iye ṣúgà tó máa ń wà lára nítorí ọ̀pọ̀ àwọn oúnjẹ náà ni wọ́n máa ń fi nǹkan tí yóò jẹ́ kí wọ́n le pẹ́ sí èyí tí ọ̀pọ̀ rẹ̀ sí máa ń jẹ́ ṣúgà àti iyọ̀.

Káàkiri àgbáyé, ọ̀ps èèyàn ló ń jẹ ṣúgà ju bí ó ṣe yẹ lọ pẹ̀lú gbogbo ìpolongo lórí ìpalára tó ń ṣe fára.

Ọtí ẹlẹ́rìndòdò tó wà nínú gíláàsì tí obìnrin kan gbé dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ ètò ìlera àgbáyé sọ pé àwọn oúnjẹ tó ní ṣúgà ni wọ́n ń jẹ jùlọ ní Amẹ́ríkà, àti pé China, India, Pakistan àti Indonesia náà ti ń tọpasẹ̀ èyí.

Ìwádìí ní ó ṣeéṣe kí China, India àti Amẹ́rikà ní àwọn èèyàn tó sanra àsanjù láàárín ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.

Nílẹ̀ Africa, ìwádìí náà ní àwọn èèyàn tó sanra àsanjù ni wọ́n máa lé kún pẹ̀lú ìdá kan láìpẹ́ jọjọ.

Síbẹ̀, ìwádìí náà ní àwọn èèyàn le ṣe àmójútó èyí láti mú àdínkù bá iye èèyàn tó le lùgbàdì ara àsanjù àti láti ṣàmójú ìlera ẹni.

Àjọ WHO sọ pé ó dára láti máa jẹ oúnjẹ tí ṣúgà inú rẹ̀ kò pọ̀ pàápàá èyí tí èèyàn nílò láti tún bu ṣúgà sí.

Wọ́n ní kò yẹ láti máa jẹ ju ṣíbí mẹ́fà ṣúgà lọ lójúmọ́.

WHO ní ó sàn láti máa ṣe àyẹ̀wò iye ṣúgà tó wà lára lóòrè kóòrè.

Àwọn dókítà máa ń lo nọ́mbà BMI láti fi mọ́ bí èèyàn ṣe sanra sí nípa lílo bí èèyàn ṣe ga sí àti ìwọ̀n tó gbé.

Báwo ni èèyàn ṣe le mọ iye ṣúgà tó wà nínú oúnjẹ?

Láti mọ iye ṣúgà tó wà nínú oúnjẹ, a ṣe àkójọ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ní àwọn oúnjẹ tó ní ṣúgà ọgọ́rùn-ún kan. Èyí yóò jẹ́ láti jẹ́ ka mọ iye ṣúgà tó wà nínú oúnjẹ kan nípa fífi ṣíbí kan wọn gíráàmù mẹ́rin.

Ní àwọn oúnjẹ carbohydrates, kcal mẹ́rin (4 kcal) ni èèyàn nílò lójúmọ́.