Wo nǹkan márùn-un tó ti ṣẹlẹ̀ látìgbà tí Trump ti lóun yóò gbèjà àwọn Kristẹni ní Naijiria

Aare Bola Tinubu ati Aare Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aare Bola Tinubu ati Aare Donald Trump
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Latigba ti Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ti ni oun yoo ko awọn ọmọ ogun America waa koju awọn to n pa Kristẹni nipakupa ni Naijiria ni ọrọ naa ti n tan kalẹ si i kaakiri agbaye, o kọja Naijiria nikan.

Trump gbe ọrọ yii kari to bẹẹ to ni ọrọ Naijiria ti kuro ni ojubọrọ.

Sọrọsọrọ ori Tẹlifiṣan kan to ṣe alagbọrandun ọrọ yii, Bill Maher, lo ni Boko Haram ti pa ju eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan (100,000) lọ lati 2009.

O ni wọn ti jo ṣọọṣi ẹgbẹrun mejidinlogun (18,000) nina.

Bi ijọba apapọ ati lẹkajẹka ṣe n sọ pe eyi ko ri bẹẹ, wọnyi lawọn nnkan to ti waye laaarin asiko ti Trump bẹrẹ si I dunkooko ogun mọ Naijiria.

Tinubu ṣepade pẹlu awọn olori ologun, paṣẹ aabo to rinlẹ

Nigba ti Aarẹ Trump bẹrẹ idunkooko rẹ lai dakẹ, Aarẹ Naijiria, ṣepade pẹlu awọn olori ogun orilẹede yii.

O paṣẹ fun wọn pe ki wọn koju ibikibi ti aabo ba ti n mẹhẹ ni Naijiria.

Aarẹ ni ko si akoko lati fi ṣofo rara, o ni ejo yoowu to ba gbori dide lasiko yii, ki wọn fọ ọ lori kia ni.

Olori ẹṣọ alaabo sọrọ akinkanju:

Olori ẹṣọ alaabo ni Naijiria, Ọgagun Olufemi Oluyede, sọ pe ohun ti Trump sọ pe wọn n pa Kristẹni nipakupa ju awọn ẹlẹsin miran lọ ni Naijiria ko ri bẹẹ.

Ọgagun Oluyede sọ pe iṣoro igbesunmọmi ni Naijiria n koju ju, ki i ṣe ọrọ ẹsin.

"Ko sẹni to n fiya jẹ Kristẹni ni Naijiria. Ai si aabo la n koju, paapaa igbesunmọmi, o si ti pẹ to ti n ba wa finra."

Olori ogun Olufemi Oluyede lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin niluu Abuja.

O ni Naijiria nikan kọ lo n koju iru iṣoro yii lagbaaye, kari aye ni.

O fi kun un pe orilẹede yowu to ba ṣetan lati ti Naijiria lẹyin,awọn ṣetan lati ba wọn ṣiṣẹ pọ.

Awọn aṣofin America gboriyin fun Trump

Lati ṣatilẹyin fun aarẹ wọn lori iṣekupa Kristẹni ni Naijiria ti Trump fẹẹ ja fun, aṣofin kan l'America, Ted Cruz, ti n polongo ọrọ yii tipẹ, ko si yee ṣe bẹẹ.

Loju opo X rẹ, o kọ ọ sibẹ pe: "Lati 2009, o le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Kristẹni (50,000) to ti ku, o si le ni ṣọọṣi 18,000 ti wọn ti dana sun pẹlu ileewe Kristẹni ẹgbẹrun meji."

Aṣofin Cruz fẹsun kan awọn alaṣẹ Naijiria , o ni "wọn kọti ọgbọn si bi wọn ṣe n pa Kristẹni, abi ko jẹ pe wọn n ṣatilẹyin fun awọn alakatakiti ẹsin onijihadi to n pa Kristẹni"

Cruz pẹlu awọn eeyan rẹ bii Riley Moore ati Tom Cole, ti wa lori irin nipa bi America yoo ṣe ka Naijiria si ọkan lara awọn orilẹede ti ko ṣee gba ojubọrọ fun.

BBC ṣewadi ohun ti Trump n sọ

Ẹka to n tan imọlẹ si iroyin ti ki I ṣe ododo ni BBC, iyẹn Disinformation Unit, ṣe iṣẹ iwadii lorii pe ṣe loootọ ni wọn n pa awọn Kristẹni run ni Naijiria.

Abajade iwadii BBC fi han pe ko si akọsilẹ fun ohun ti aṣofin Ted Cruz ati awọn eeyan rẹ sọ nipa Naijiria, ati pe ọrọ wọn naa ko ṣee fidi ẹ mulẹ rara.

Loṣu Kẹsan-an ni Cruz mẹnuba a ninu abọ iwadii kan lati ọwọ International Society for Civil Liberties and Rule of Law (InterSociety) – eyi ti ki i ṣe ti ijọba.

Ibẹ ni wọn ni awọn ti wadii ohun to n ṣẹlẹ nipa titẹ ẹtọ eeyan loju ni Naijiria.

Bakan naa lo tun fi awọn oju opo kan ranṣẹ si BBC lati wadii ọrọ naa, ṣugbọn gbogbo ẹ naa lo ni i ṣe pẹlu InterSociety.

Awọn InterSociety ko fun wa ni ibi ti wọn ti ri onka ipaniyan ti Cruz atawọn eeyan rẹ gbe kalẹ, eyi to jẹ ko ṣoro lati fidi iye iku ti wọn n kede maa mulẹ.

Tinubu sọrọ nipa idunkooko Trump fun igba akọkọ

L'Ọjọbọ to kọja, Aarẹ Bola Tinubu ṣe alaga ipade apapọ awọn alaṣẹ, nibi ti wọn ti jiroro lori idunkooko Trump.

Nibi ipade naa ni Tinubu ti ni o da oun loju pe Naijiria yoo bori.

O ni orilẹede yii yoo bori America to n pe e ni ilẹ ti ko ṣee gba ojubọrọ fun. Yoo si tun bori ogun to fa ihalẹ Trump.

Tinubu ṣapejuwe Naijiria bii ilu ti kaluku ti n ri ara wọn bii mọlẹbi kan naa.

O bẹ awọn ajọ agbaye lati ti Naijiria lẹyin, ki ilu naa le bori igbesunmọmi.

Bi ijọba Naijiria ṣe le bọ́ lọ́wọ́ America

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi Naijiria yoo ba bọ lọwọ idaamu ati ipaya ti America fẹẹ ko o si, onimọ nipa eto aabo kan, Ọmọwe Buhari Ubandawaki, ṣalaye pe afi ki Naijiria tunra mu lori ọrọ aabo rẹ.

Ọmọwe Ubandawaki sọ pe paapaa kikoju awọn agbegbe iku ti awọn Boko Haram wa, ibi ti awọn agbebọn wa ati awọn agbegbe ewu gbogbo.

"O yẹ ki awọn ologun Naijiria maa kọlu awọn ẹlẹgiri naa pẹlu aridaju ati agbara ni, yoo jẹ ki araalu nigbagbọ ninu wọn. "

Onimọ nipa aabo naa lo sọ bẹẹ.

Ubandawaki kilọ pe idunkooko ni bi America ṣe loun yoo kọlu Naijiria, ilẹ olominira to da duro.

O ni bi Naijiria ba gba iru rẹ laye, o ti fi aaye silẹ fun awọn alagbara ilẹ okeere mi-in lati wọle si I lara niyẹn.

Ubandawaki sọ pe Naijiria gbọdọ kọ ipinnu America, ko si so okun aabo rẹ le dan-in-dan-in fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

"Bi Naijiria ba le koju awọn iku ile bii Bello Turji atawọn mi-in to n daamu Naijiria labẹnu, yoo jẹ ki araalu ni igbekẹle ninu ijọba.

Yoo si jẹ ki awọn orilẹede agbaye naa mọ pe a le da koju iṣoro aabo to n waye lemọlemọ."

Ubandawaki lo ṣalaye bẹẹ.

Ṣé ìjọba Naijiria ti ṣe to?

Ọmọwe Ubandawaki sọ pe ijọba Naijiria ko ti i ṣe to lẹka aabo.

  • O ni o yẹ kijọba ran ikọ ologun to pọ lọ si awọn agbegbe ti aibalẹ ọkan wa.
  • Ki wọn fi owo kun owo ti wọn yoo fi ra nnkan eelo ogun igbalode.
  • Ki wọn ra awọn ẹrọ bii drone, ki wọn ra baaluu ogun to le kọlu ibi ti awọn ẹni ibi naa n sa pamọ si.
  • Naijiria nilo ajọṣe pẹlu awọn orilẹede alamuleti, niwọn igba to jẹ ẹnu ibode ni awọn ikọlu yii ti n waye ju.
  • O yẹ ki ijọba ri si igbayegbadun awọn ẹṣọ alaabo, ki ori wọn le maa ya siṣẹ bo ṣe sọ.