Wo àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó yẹ kí o mọ ìdáhùn sí nípa ọdún Kérésìmesì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Òní ni ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, tí àwọn Kristẹni káàkiri àgbáyé máa ṣe ọdún ìbí Jésù, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbà gẹ́gẹ́ bí olùgbàlà.
Lásìkò ọdún yìí ni àwọn Kristẹni máa ń ṣe àjọyọ̀ tó fi mọ́ wíwọ aṣọ tuntun, síse oúnjẹ aládùn, pínpín ẹ̀bùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè ló máa ń jẹ jáde nípa ọjọ́ òní èyí tí BBC gbìyànjú láti wá ìdáhùn sí.
Ọjọ́ wo gan ni wọ́n bí Jésù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
BBC wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí lọ́dọ̀ onímọ̀ ẹ̀sìn Kristẹni tó tún jẹ́ alága ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Joseph John Hayab.
Ó ní òótọ̀ ibẹ̀ ni pé wọn kò bí Jésù ní ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá.
Ó sọ fún BBC lọ́dún 2024 pé wọn ò tilẹ̀ bí Jésù nínú oṣù Kejìlá rárá. "Òótọ́ ibẹ̀ nìyẹn."
Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ Kristi gbàgbọ́ pé kò sí eni tó mọ ọjọ́ pàtó tí wọ́n bí Jésù, tí wọ́n kàn sì mú ọjọ́ kan láti máa fi ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni.
Ìlú wo ni wọ́n bí Jésù sí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lórí ìbí Jésù, ìtàn fi hàn pé ìlú Bethlehem ni wọ́n bí Jésù sí èyí tó jẹ́ orílẹ̀ èdè Palestine lónìí àmọ́ Roman Empire ló wà nígbà náà.
Kí ló dé tí wọ́n ń ṣe ọjọ́ ìbí Jésù nínú oṣù Kejìlá?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní sẹ́ńtúrì kẹrin, àwọn ara Róòmù àtàwọn ara ilẹ̀ Yúróòpù kan máa ń lo oṣù Kejìlá láti fi àjọ̀dún àwọn ayẹyẹ tí kìí ṣe ti ọmọlẹ́yìn Kristi. Wọ́n wá ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbí Jésù, tí wọ́n sì ri pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àsìkò yìí.
Wọ́n wòye pé nígbà tí àwọn ayẹyẹ náà níṣe pẹ̀lú ẹ̀bùn pínpín pé kí ló dé tí àwọn náà kò lè fi ayẹyẹ ọja ìbí Jésù sí ìgbà náà?
Ní àsìkò yẹn, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kejìlá àti ọjọ́ Kẹfà oṣù Kìíní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe àwọn ayẹyẹ náà.
"Wọ́n wò ó pé nígbà tó jẹ́ àsìkò kan náà ni wọ́n ṣe yípadà sí ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdọọdún," Ẹni ọ̀wọ̀ Joseph Hayab sọ.
Ta lo bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìtàn fi yéwa pé ní sẹ́ńtúrì kẹrin ní Roman Empire ni ayẹyẹ ṣíṣe Kérésìmesì ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 336 AD láyé Ọba Constantine tó kéde ẹ̀sìn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí wọ́n máa ma sìn níbẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, Ẹni ọ̀wọ̀ Joseph Hayab sọ pé ní ọdún 1931 ni ọdún Kérésìmesì di ohun tí wọ́n ń ṣayẹyẹ rẹ̀ bó ṣe wà lóde òní káàkiri àgbáyé.
Kí ni pàtàkì ṣíṣe ọdún Kérésìmesì?
Pásítọ̀ James Mobel Wuye, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe ìjíròrò láàárín àwọn Mùsùlùmí àti Kristẹni sọ pé ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ náà jẹ́.
Ó sọ pé ẹni tó bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo gbọdọ̀ máa rántí ikú Jésù tó jẹ́ olùgbàlà, kí wọ́n sì máa dúpẹ́ fún-un.
Ó fi kun pé lásìkò ayẹyẹ ni orírúuurú ohun máa ń wáyé, tí àwọn èèyàn míì máa ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn wọn.
"Wọ́n máa jẹun, jó, kọrin, yọ ayọ̀, tí wọ́n sì máa tan ìfẹ́ láti fi ṣàmì ọjọ́ náà."
Pásítọ̀ Wuye wá rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún àwọn ìwà kò tọ́ lásìkò yìí nítorí ó jẹ́ àsìkò ìjọ́sìn àti ìronúpìwàdà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ló dé táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kan kìí ṣe ọdún Kérésìmesì?
Bí àwọn ọmọlẹ́yìn kan ṣe ń ṣe àjọyọ̀ ọdún Kérésìmesì lọ́jọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, àwọn kan kìí ṣe ọdún yìí.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn ajẹ́rìí Jèhófà kìí ṣe ọdún Kérésìmesì nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé Bíbélì kò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù tàbí ohunkóhun Kérésìmesì.
Ọmọ ìjọ Ajẹ́rìí Jèhófà kan, Sunday Paul sọ pé kò sí nínú Bíbélì pé ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ni wọ́n bí Jésù.
Ìdí kan gbòógì rèé táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kan kìí fi ṣe ayẹyẹ ọdún náà yàtọ̀ sí àwọn ìjọ Àgùdà àtàwọn míì tí wọ́n ka ọjọ́ náà kún ọjọ́ pàtàkì nínú ẹ̀sìn wọn.















