Àlàyé rèé lórí bí nọ́mbà NIN àti ìwé ẹ̀rí CAC ṣe le rọ́pò nọmbà owó orí rẹ lọ́dún tuntun

Ọwọ́ èèyàn kan mú káàdì idanimọ NIN lọwọ

Oríṣun àwòrán, FIRS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si owo pipa wọle fun ijọba apapọ Naijiria, Federal Inland Revenue Service (FIRS), ti kede pe nọmba idanimọ NIN ni yoo jẹ nọmba ẹri owo ori sisan, Tax ID, fun awọn araalu, bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2026.

Ọrọ yii lo n jade laarin ariyanjiyan awọn ọmọ Naijiria lori ofin to sọ pe gbogbo awọn to n lo banki gbọdọ ni nọmba owo orin ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti FIRS sọ, apapọ 123.9 miliọnu ọmọ Naijiria lo ni nọmba NIN nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025.

Ninu atẹjade kan loju op X rẹ, o ni fun awọn ileeṣẹ ti wọn ti forukọsiẹ lọdọ ajọ CAC, nọmba RC ti wọn ti ni tẹlẹ ni yoo di nọmba Tax ID wọn bẹrẹ lati ọdun to n bọ.

Amọ o fikun pe igbesẹ naa kii ṣe ohun ọtun nitori o ti wa ninu iwe ofin eto iṣuna lati ọdun 2019.

FIRS fi kun pe nọmba idanimọ owo ori tuntun naa yoo mu ko rọrun fun ijọba lati mọ awọn to n san owo ori, ati pe bi awọn to n san owo naa ṣe n san an yoo han kedere.

O ni "Tax ID ọhun ni yoo ko gbogbo TIN ti ajọ FIRS ati IRS pọ soju kan naa.

"Fun awọn araalu, nọmba NIN yin ni yoo di Tax ID laisi wahala kankan, nigba ti awọn ileeṣẹ to ti forukọsilẹ yoo maa lo nọmba CAC RC wọn gẹgẹ bii nọmba owo ori.

Ile ijọba FIRS

Oríṣun àwòrán, FIRS

"Ẹ ko ni nilo kaadi pelebe ti ẹ o maa mu kiri, nọmba idanimọ owo ori Tax ID naa yoo ti so pọ mọ orukọ yin."

Nigba to n sọrọ lori ofin owo ori tuntun ti yoo gberasọ lọjọ kinni, ọdun 2026, adari ajọ to n ri si ọrọ naa, Taiwo Oyedele, sọ pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe gbogbo apo iṣuna araalu ni banki lo gbọdọ ni nọmba TIN ko to di ọdun to n bọ.

Gẹgẹ bii alaye rẹ, abala kẹrin ofin NTAA kan an nipa pe gbogbo awọn to yẹ fun lati maa san owo ori gbọdọ ni nọmba idanimọ Tax ID.

Ati pe owo ti wọn san gbọdọ wa lati inu owo to n wọ apo wọn nipa iṣẹ tabi owo ti wọn ṣe.

O ṣalaye pe awọn ti kii pa owo wọle bii awọn akẹkọọ atawọn ti wọn ṣi wa labẹ obi tabi alagbatọ wọn ko nilo Tax ID kankan.

Oyedele fi kun pe gbogbo awọn to n lo banki fun owo wọn lati ọdun 2020 ni wọn ti ni nọmba idanimọ owo ori to so mọ akanti naa lati akoko igba naa wa.