Boxing Day: Kí ni ìdí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ kejì ọdún Kérésì ní Boxing Day?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Itan 'Boxing Day' yii bẹrẹ lakoko ti Ọbabirin Victoria wa lori aleefa niwọn ọdun 1800.
Boxing Day ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.
Orisun orukọ naa bẹrẹ pẹlu bi awọn ọlọla ṣe maa n di ẹbun sinu apoti, ti wọn si maa n pin fun awọn alaini lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ ọhun jẹ ọjọ ti awọn ẹrú kii ṣe iṣẹ kankan, ti awọn olowo wọn si maa n fun wọn ni ẹbun ọdun Keresi ninu apoti.
Awọn ẹbun ọhun ni awọn ẹru naa maa n gbe lọ fun awọn ara ile wọn, ki wọn fi ṣafihan bi awọn olowo awọn ṣe mọ riri iṣẹ ti wọn ṣe ni odidi ọdun kan to.
Boxing Day' tun jẹ ọjọ ti awọn orilẹ-ede kan bii Hungary, Germany, Poland ati Netherlands maa n ṣe ajọyọ ọjọ to tẹle ọjọ ọdun Keresimesi.
Ipa tí ìjọ kó
Ninu iwe itan, awọn ile ijọsin naa kopa ninu ṣiṣagbekale ọjọ 'Boxing Day'to wa fun pinpin ẹbun fi mọ riri ara ẹni.
Lẹyin ti wọn ba ti gba owo ọrẹ lọwọ awọn ijọ laarin ọdun, wọn maa n ko owo naa sinu apoti, wọn a wa ṣi apoti owo ọrẹ yii lọjọ keji ọdun Keresi, ti wọn a si pin owo inu rẹ fun awọn talaka
Ọjọ́ wo ni Boxing Day?
Boxing Day jẹ ọjọ keji, ọdun Keresimesi, o si maa n bọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, ninu oṣu Kejila ọdun.
Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ isinmi lorilẹ-ede Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede miran lagbaye.
Lorilẹ-ede wa nibi, ọjọ yii jẹ ọjọ faaji ati ọjọ igablejo loriṣiriṣi fun ọpọ eeyan.
Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ ti awọn eeyan ma jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku ounjẹ ti wọn se lasiko ọdun.















