Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí yóò ṣe máa fi ọkọ̀ aráàlú tí kò dáa mọ́ pa owó wọlé ní 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ lati maa pa owo wọle lori awọn ọkọ ti wọn n paarọ si nnkan miran, bẹrẹ lati ọdun 2026.
Gẹgẹ bii ohun ti ijọba sọ, ṣiṣe eyii le pa owo ti iye rẹ to N150b lọdọdun fun oun.
Ninu atẹjade kan ti adari ajọ National Automotive Design and Development Council, NADDC, Joseph Osanipin fi lede, o ni awọn ọkọ ti ọjọ ti lọ lori wọn lawọn yoo paarọ si nnkan mii lọna ati pa owo wọle fun ijọba.
Osanipin ṣalaye pe "lawọn orilẹede to ti goke agba, ti o ba ra ọkọ tuntun, lasiko ti o ba n forukọ rọkọ naa silẹ lo maa san owo ti wọn maa fi sọ ọkọ naa nu ti ọjọ ba ti lọ lori rẹ.
"Ti ọjọ ba ti lọ lori ọkọ naa tan, eeyan kan lo maa ṣeto bi wọn yoo ṣe sọ ọ nu ati ibi ti wọn maa sọ ọ si."
O ṣalaye pe oun ti ijọba Naijiria yoo ṣe yoo fara pẹ nnkan bẹẹ, to n tumọ si pe ẹni to ba ara ọkọ yoo san owo perete ti wọn yoo fi ju ọkọ naa sọnu ti asiko ba to.
Alaga NADDC ọhun fi kun pe igbesẹ naa dara pupọ amọ ọpọ ọmọ Naijiria ni yoo kọkọ ta ko o.
O tẹsiwaju pe ọpọ araalu ni Naijria lo yan lati maa ra ẹya ara mọto to jẹ tokunbọ dipo tuntun, eyii ti yoo mu ki nnkan ti awọn fẹ ṣe rọrun fun awọn.
Osanipin fidi rẹ mulẹ pe iwadii awọn fi han pe ida 85% awọn ẹya ara ọkọ ti awọn eeyan ko lo mọ lo ṣi wulo, owo gọbọi lo si wa nibẹ.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe "kaka ki eeyan kan fi ọkọ rẹ kalẹ sẹgbe titi ko maa jẹra nibẹ, wọn le gbe ọkọ naa wa ki wọn si pa owo gọbọi lori rẹ.
"Ti a ba bojuto igbesẹ naa daada, ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira la o maa pa lori rẹ lọdọdun."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, yatọ si pe wọn n pa ọkọ da, igbesẹ ọhun yoo tun pese ọpọlọpọ iṣẹ yanturu fawọn ẹlomii.
Ikede yii lo n waye lẹyin iroyin to sọ pe iye ọkọ akero ti awọn eeyan n ko wọ Naijiria pọ si lọdun yii.
Iroyin ni iye ti ijọba pa wọle lori ọkọ akero ti wọn ko wọ Naijiria ni oṣu mẹsan an akọkọ ọdun 2025 le ni N1.01tn lati nnkan bii N894bn to wa tẹlẹ.















