Ìwọ̀nyí làwọn orí adé àti olóṣèlú tó jáde láyé ní Naijiria àti l'Afrika lọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, Olubadan/Buhari/Awujale
Oniruru nnkan lo ṣẹlẹ lọdun 2025 yii, eto iṣile, kiko ọmọ tuntun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ bi nnkan rere wọnyii ṣe n waye naa lawọn eeyan mii fi ilẹ ṣaṣọ bora.
Iwọyi lawọn eeyan jankan to jade laye ni Naijiria ati nilẹ Afrika lọdun 2025 yii.
1. Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari
Muhammadu Buhari ni Aarẹ Naijiria lọpọ ọdun sẹyin gẹgẹ bii Aarẹ ologun, aye si royin awọn iṣẹ ribiribi to gbe lasiko naa.
Nigba ti yoo di ọdun 2015, Buhari tun pada wọle gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu iranlọwọ Bola Ahmed Tinubu.
Ara ni ọpọ ọmọ Naijiria lasiko ijọba rẹ ọhun ko to gbe agbara silẹ lọdun 2023.
Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 yii ni Buhari dagbere faye lẹyin aisan to n ba finra niluu London.
Ẹni ọdun mejilelọgọrin ni Buhari ki ọlọjọ to de.
2. Oba Sikiru Adetona

Oríṣun àwòrán, Oba Sikiru Adetona
Oba Sikiru Adetona ni Awujale ilẹ Ijebu fun nnkan bii ọdun mejilelọgọta.
Igba Ọba Adetona san awọn eeyan ilẹ Ijebu ko to tẹri gbaṣọ lọjọ kan naa ti Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ku.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Karun un, ọdun 1934 ni wọn bi Oba Sikiru Adetona.
Titi di asiko yii, wọ ko tii yan awujalẹ mii, koda awuyewuye ṣi n lọ lọwọ lori ẹni ti oye naa kan.
3. Oba Owolabi Olakulehin
Oba Owolabi Olakulehin ni Olubadan kẹtalelogoji ti ilẹ Ibadan.
Kebiesi waja lẹyin ọdun kan ti wọn gori apere awọn babanla wọn.
Lẹyin ti Oba Owolabi Olakulehin waja lọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2025 yii ni wọn kede pe Ọba Rashidi Ladoja ni ipo Olubadan kan.
Ọjọ karun un, oṣu Karun un, ọdun 1935 ni wọn bi Oba Owolabi Olakulehin.
4. Doyin Okupe
Inu oṣu Kẹta, ọdun 1952 ni wọn bi Adedoyin Ajibike Okupe, ti ọpọ mọ si Doyin Okupe.
Oloṣelu ni, dọkita si ni pẹlu, o tun jẹ ọkan lara awọn to da ile iwosan Royal Cross Medical Centre silẹ.
Ṣaaju ni aisan jẹjẹrẹ ti n ba Okupe finra ko to dagbere faye lọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2025 yii.
5. Peter Rufai
Lẹyin ọdun 1990 ni Peter bẹrẹ si n gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu Naijiria gẹgẹ bii aṣole, irawọ rẹ si milẹ titi lasiko rẹ.
Lẹyin aisan ranpẹ lo dagbere faye niluu Eko lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
6. Raila Odinga
Ọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 1945 ni wọn bi Raila Amolo Odinga niluu Maseni, lorilẹede Kenya.
O jẹ oloṣelu, oun si ni olootu ijọba orilẹede naa laarin ọdun 2008 si ọdun 2013.
Ile iwosan Devamatha ni Odinga ku si lorilẹede India lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 yii.
7. Alufaa Uma Ukpai

Oríṣun àwòrán, Uma Ukpai
Uma Ukpai jẹ gbajumọ pasitọ ti awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ iranṣẹ n gboṣuba kare ni Naijiria ati loke okun latari awọn iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ti lo o fun.
Yatọ si iṣẹ oluṣọ agutan, o tun jẹ ẹleyinju aanu ṣaaju iku rẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025.
Ngũgĩ wa Thiong'o
Ọdun 1938 ni wọn bi Ngũgĩ wa Thiong'o niluu Kamirithu, lorilẹede Kenya.
Ṣaaju iku rẹ o gbajumọ fun iwe kikọ, ọpọ akẹkọọ kaakiri ilẹ Afrika lo si ka iwe rẹ















