Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Greenbook, áàpù tí NAFDAC ṣe láti fi dá ayédèrú oògùn mọ̀

Oogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti oògùn lílò ní Nàìjíríà, NAFDAC ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ áàpù kan,The Greenbook, èyí tí yóò máa ṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn láti mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn oògùn tó jẹ́ ojúlówó àti ayédèrú.

Adarí àjọ NAFDAC, Mojisola Adeyeye níbi ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ̀ méjì kan lórí áàpù náà tó wáyé ní ìlú Port Harcourt, ìpínlẹ̀ Rivers, ló kéde èyí.

Áàpù Greenbook náà yóò jẹ́ ọ̀nà láti gbógunti àwọn tó máa ń ṣe ayédèrú oògùn ní Nàìjíríà, tí yóò sì ṣe ìrànwọ́ fáwọn tó ń ra oògùn.

Adeyeye, ẹni tí adarí ẹ̀ka tó n ṣe àmójútó ìtọpinpin , Fraden Bitrus ṣojú fún sọ pé, áàpù ọ̀hún yóò jẹ́ àkọsílẹ̀ nípa àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè oògùn ní Nàìjíríà lórí ayélujára.

Àwòrán áàpù Greenbook

Oríṣun àwòrán, NAFDAC

Ó ní àwọn èèyàn yóò ní àǹfààní láti ṣe àyẹ̀wò orúkọ iléeṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ra oògùn rẹ̀ lórí áàpù náà àti láti ṣàyẹ̀wò nọ́mbà ìdánimọ̀ iléeṣẹ́ náà pẹ̀lú NAFDAC.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ́, ó jẹ́ kó di mímọ̀ nípa ìdí tí àwọn lájọlájọ àti iléeṣẹ́ ṣe nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú NAFDAC lórí áàpù ọ̀hún bí ó ṣe ní pé àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ayédèrú oògùn ti ń pọ̀ si.

"Greenbook NAFDAC jẹ́ irinṣẹ́ kan gbòógì láti fi dá àwọn ayédèrú oògùn mọ̀. Tí orúkọ oògùn kan kbá ti wà nínú Greenbook, ó túmọ̀ sí pé oògùn náà ní àkọ́ọ́lẹ̀ pẹ̀lú NAFDAC, tó sì dára láti lò."

Ó fi kun pé Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ nílẹ̀ Africa àti ìkejì káàkiri àgbáyé tó ń ṣe àmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí láti fi gbógunti ayédèrú oògùn.

Áàpù náà wà lórí ìkànnì 'Apple Store' fún àwọn tó n lo iphone, bákan nàá ló wà lórí Google Play Store fún àwọn tó n lo Android, láti gbà á sórí fóònù.

Bẹ́ẹ̀ náà ló sọ pé lóòrè kóòrè ni àwọn yóò máa ṣàtúnṣe sáwọn orúkọ oògùn lórí áàpù náà bí àwọn bá ṣe ń fi orúkọ wọn sílẹ̀.

Adeyeye sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé oògùn nìkan ló ṣì wà lórí áàpù náà báyìí, táwọn yóò máa fi orúkọ àwọn èròjà ìṣaralógé sí orí rẹ̀ tó bá yá.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Kọmíṣánnà fétò ìlera ìpínlẹ̀ Rivers State, Adaeze Oreh ṣàtẹnumọ́ ìfarajìn ìpínlẹ̀ Rivers láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú NAFDAC nídìí gbígbé ogun tí pípèsè ayédèrú oògùn.

Níbi ètò náà ni wọ́n ti ṣàfihàn bí áàpù náà ṣe ń ṣiṣẹ́ fáwọn iléeṣẹ́ ìpoògùn tó wà níbẹ̀.