Kókó ohun tí Peter Obi àti Gómìnà Bala Mohammed sọ nínú ìpàdé ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n ṣe

Peter Obi àti gómìnà Bala ń ba ọwọ́

Oríṣun àwòrán, X/@SenBalaMohammed

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023, Peter Obi ṣe àbẹ̀wò sí gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi, Bala Mohammed níbi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ láti jíròrò lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.

Ní ilé ìjọba (Ramat House) tó wà ní ìpínlẹ̀ Bauchi ni ìpàdé náà ti wáyé lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹta ọdún 2025.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bèèrè pé kí ni ó fa ìpàdé láàárín Peter Obi tí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti Gómìnà Bala tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP?

Ìbéèrè tó gba ẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ṣe ìpàdé náà kò dá lórí ètò ìdìbò ọdún 2027?

Lẹ́yìn tí Peter Obi ti fìdí rẹmi sọ́wọ́ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu níbi ètò ìdìbò ọdún 2023 níbi tó ti gbé ipò kẹta, Peter Obi kò sinmi láti máa ṣe àbẹ̀wò sáwọn èèkàn olóṣèlú káàkiri Nàìjíríà.

Bí ó ṣe ń ṣàbẹ̀wò sáwọn gómìnà, náà ló ń ṣe àbẹ̀wò sáwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan káàkiri Nàìjíríà.

Kí ló dé tí Obi ṣàbẹ̀wò sí Gómìnà Bala?

Peter Obi àti gómìnà Bala

Oríṣun àwòrán, X/@SenBalaMohammed

Gẹ́gẹ́ bí Gómìnà Bala ṣe sọ lẹ́yìn ìpàdé náà, ó ní bí ìṣọ̀kan yóò ṣe wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìlú mìíràn láti mú Nàìjíríà gòke àgbà ni ìpàdé náà dá lé lórí.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó hàn gbangba pé onírúurú ìpèníjà ló ń kojú Nàìjíríà lásìkò yìí, ó sọ pé àwọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè yìí àmọ́ kò sọ bóyá àwọn sọ̀rọ̀ lórí ètò ìdìbò ọdún 2027.

Àtẹ̀jáde tí Gómìnà Bala fi síta ló ti ṣàlàyé pé òun jẹ́ kí Peter Obi mọ̀ nípa ìfarajìn òun sí mímú àgbéga bá ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti pé jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè rere wà lára nǹkan tí yóò tẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà síwájú.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nipa Peter Obi, Gómìnà Bala ní òun fẹ́ràn bí kò ṣe kó àárẹ̀ ọkàn àti bó ṣe ń ṣe ìjọba rẹ̀.

Ó ní bó ṣe ń lọ káàkiri Nàìjíríà láti jíròrò pẹ̀lú àwọn àgbà olóṣèlú jẹ́ nǹkan tó máa ń dùnmọ́ òun.

Gómìnà Bala sọ pé kókó òun tí Peter Obi fi ṣàbẹ̀wò sí òun ni láti kí òun lórí àwọn àjálù tó wáyé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí àti láti jíròrò pẹ̀lú òun lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.

Bákan náà ló ní ó jẹ́ ọ̀nà láti túnbọ̀ lékún lórí gbígba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà.

Lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú Peter Obi ni mínísítà fétò ìsúná tẹ́lẹ̀ rí, Nenadi Usman, tí wọ́n sì ṣe àbẹ̀wò sí Emir ìlú Bauch, Alhaji Rilwanu Suleiman Adamu.

Gómìnà Bala àti Peter Obi lásìkò tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí Emir Bauchi

Oríṣun àwòrán, X/@SenBalaMohammed

Ṣáájú ni Peter Obi ti sọ pé èròńgbà òun ni láti pè fún Nàìjíríà tuntun, tí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ kò sí ní yí ìpinnu òun padà.

Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé, Tinubu ni ó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ààrẹ tó wáyé nínú oṣù Kejì, ọdún 2023.

Láti ìgbà náà sì ni ìrìnàjò ètò ìdìbò ọdún 2027 ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwòye taa ni yóò díje, àtàwọn tí yóò parapọ̀.

Láìpẹ́ yìí ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀ rí, Nasir El-Rufai fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress sílẹ̀ láti lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP.

El-Rufai ní òun fẹ́ kojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́dún 2027 àmọ́ kò ì tíì sọ àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀.

Ìròyìn ní, Peter Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ń wá àwọn tí wọ́n yóò ba ṣe pọ̀ láti lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kúrò nípò àṣẹ lọ́dún 2027.