BBC ṣe ìwádìí ẹ̀sùn pé àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ń pa àwọn ọ̀dọ́ nípakúpa ní Congo

Oríṣun àwòrán, Freddy Mukuza/Facebook
Nnkan o fararọ lorilẹede Congo.
Awọn ọmọ ogun ọlọtẹ M23 n daamu awọn araalu, wọn n fipa ko wọn sinu iṣẹ ologun, iku oro ni wọn fi n pa awọn ọdọ bayii, gẹgẹ bi iwadii ti BBC ṣe.
Nigba ti wọn fẹẹ yinbọn pa ọdọkunrin kan, Freddy Mukuza, ọlọkada to tun maa n kọrin lati tako iwakiwa, niṣoju ọrẹ rẹ kan lo ṣe.
Ọrẹ duro ni nnkan bii ẹsẹ bata aadọta lọọkan, o n wo bi wọn ṣe fẹẹ gba ẹmi lẹnu ọrẹ timọtimọ rẹ.
Nigba to ri i pe awọn M23 ti yinbọn fun Freddy, oun ati awọn ọrẹ wọn mi-in sare lọ sibẹ lati gba a la, iyẹn ni Goma, Ila-oorun ilẹ Olominira Congo.
"Nigba ti a dẹbẹ, a ṣi ba Freddy to n mi, a fẹẹ gbe e lati lọọ tọju ẹ, ṣugbọn awọn ọmọ ogun M23 ko gba fun wa."
Bẹẹ ni ọrẹ rẹ ti a pe ni Justin ṣalaye .
"Nigba ti a n ba wọn fa a pe a fẹẹ gbe e lọ, niṣe ni wọn yinbọn silẹẹlẹ, bii pe wọn n sọ fun wa pe ti a ba kọja ibi ti a wa yẹn, awọn maa pa awa naa ni.'"
Eyi ni awọn ọrẹ naa ṣe sun sẹyin, wọn si n wo lai le ran Freddy lọwọ titi ti ẹmi fi bọ lara ọkunrin ẹni ọdun mọkalelọgbọn (31) naa.
Nigba naa ni awọn M23 too gba wọn laye lati gbe e, nigba to ti di oku.
Ṣaaju ki wọn too pa a, ọkọ akẹru mẹta to kun fun awọn ọmọ ogun ni wọn ya wọ agbegbe ti Freddy n gbe, ni Kasika.
Ọjọ Satide ni ọjọ naa, laaago mẹta ọsan ọjọ kejilelogun, oṣu Keji ọdun 2025.
Freddy ṣẹṣẹ ko de ile ọhun ni, ori ile naa lo n bo lọwọ pẹlu awọn ana rẹ meji ti awọn ologun fi bẹrẹ si I yinbọn.
Wọn pa Freddy, wọn si pa awọn ana rẹ meji mọ ọn.
Ko tun ju bii oṣu kan lọ lẹyin igba naa ni wọn ya wọ Goma, wọn gba apa Ila-Oorun wọle si wọn lara.
Laaarin wakati kan, eeyan mẹtadinlogun si mejilelogun ni wọn ti yinbọn pa, paapaa julọ awọn ọdọkunrin, gẹgẹ bi a ṣe ri i gbọ.
A ti ri awọn ẹri, a si ti gbọrọ lẹnu awọn araalu lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn a ko le darukọ wọn nitori aabo wọn.
BBC beere lọwọ awọn M23 nipa awọn ẹsun yii, ṣugbọn wọn ko dahun rara.
Awọn alaṣẹ Kasika ko ti i fi atẹjade kankan sita lati sọ onka awọn eeyan to ti di oloogbe
Bakan naa ni ko ti I si iwadii kankan to n tọka si pe wọn n tọpinpin ohun tawọn araalu n pe ni ipaniyan rẹpẹtẹ yii.
Ṣugbọn awọn araalu ko yee sọ pe awọn ọmọ ogun ọlọtẹ M23 nikan ni ikọ ologun to n ṣọṣẹ lojuu gbogbo aye bayii ni Goma.
Lati opin oṣu Kin-in-ni ti wọn ti gba ilu naa ni awọn ọmọ ogun M23 ti n ṣe ohun to wu wọn.
Laaarin ọjọ mejidinlogun ti a fi wa lẹnu iṣẹ iwadii yii, ọwọja wọn ti gbale-gboko.
Bẹẹ ni wọn si ti fẹsun ọlọkan-o-jọkan kan wọn ri lawọn agbegbe mi-in naa ni Congo.
''Wọn kò dáṣẹ́ ṣe, Rwanda wà lẹ́yin wọn''

Awọn ọmọ ogun ọlọtẹ yii ki i da iṣẹ wọn ṣe, awọn orilẹede to mule ti wọn bii Rwanda n ṣe atilẹyin fun wọn, gẹgẹ bi UN ati orilẹede America ṣe sọ.
Bo tilẹ jẹ pe Rwanda ti ni ko sohun to jọ bẹẹ, wọn ki i jiyan pe awọn ọmọ ogun awọn wa ni Congo. Wọn ni wọn wa nibẹ lati da aabo bo ara wọn ni.
Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe awọn M23 dajusọ agbegbe Kasika nitori ọga ologun Congo tẹlẹ kan to n gbe ni agbegbe naa ni.
Idaamu pọ ni Congo, awọn to ba BBC sọrọ ṣalaye nipa bi ibẹru ko ṣe jẹ ki wọn gbele aye nirọrun mọ.
Justin, ọrẹ Oloogbe Freddy, ṣalaye pe oun ki I jade mọ, koda, oun ko le lọ sibi iṣẹ oojọ mọ, koun ma lọọ ko sọwọ awọn M23.
Eso ati ẹfọ lo ni awọn n jẹ bayii, bẹẹ loun ti mu awọn ọmọ oun kuro nileewe, nitori ibẹru ologun ọlọtẹ.
Ifipanilopọ tun gbilẹ nibẹ, ṣiṣe owo ilu mọkumọku pọ bii ka a si nnkan.
Ko si aabo, ko sowo niluu, bẹẹ ni ko si ifayabalẹ, ojumọ kan, ipaya kan lo gbode ni Congo.
Apa ijọba Congo ko ka iṣakoso naa, ẹnu awọn adari wọn ko kò, bẹẹ ni ẹnu wọn ko to ọrọ kankan.
Justin to ṣalaye nipa iku ọrọ rẹ, Freddy, ṣe bẹẹ lati jẹ kawọn eeyan maa ranti rẹ, ki wọn si le mọ bi iku oro ṣe n pa awọn eeyan ni Congo lati ọwọ awọn M23.














