Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Ajọ NAFDAC ti ṣe ifilọlẹ aapu tuntun, Greenbook.
Ilu Porthacout ni wọn ti ṣe ifilọlẹ naa l'Ọjọbọ
Wọn ni yoo maa ran awọn onibaara lọwọ lati da ayederu oogun mọ
Lati bii oṣu meloo ni NAFDAC ti n gbogun ti awọn to n ṣe ti wọn si n ta ayederu ogun ni Naijiria
Ékunrẹrẹ iroyin nipa bi aapu naa ṣe n ṣiṣẹ wa ni BBC.COM/YORUBA
………………………………………………………………………
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti buwọ lu bijọba yoo ṣe maa pin owo ori VAT
Ọjọbọ ni awọn aṣofin buwọ lu pe kijọba ipinlẹ maa mu ida 55%, ijọba ibilẹ yoo mu 35%
Latọdun to kọja ni ọrọ owo ori yii ti n ja ran-in nilẹ
Alaye nipa pinpin naa ati bo ṣe kan ọ wa loju opo wa
,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,
'Gomina Abdulfatah Ahmed, ya owo ajọ UBEC to n mojuto ẹkọ alakọọbẹrẹ lasiko ijọba rẹ, ko si da a pada.''
Akọwe Agba SUBEB ni Kwara lasiko naa, Ọgbẹni Dasuki lo sọ bẹẹ nibi igbẹjọ to waye lọjọru
N5.78 billion lo ni Fatai ṣe mọkumọku laarin 2013 si 2019
Fun ẹkunrẹrẹ

