Ọmọ mi ni ìrètí mi, ṣùgbọ́n wọn ò jẹ́ kó sanjọ́ - Ìyá Mojisola Awesu

Oríṣun àwòrán, BBC/Mojisola Awesu
Fatimah Awesu ti o jẹ iya Mojisola Awesu, akẹkọọ ile-ẹkọ Health Technology Offa ti wọn ba oku rẹ lori akitan ni Ilorin, ti pariwo si gbogbo aye ati ijọba ki wọn gba oun ki iya ma jẹ oun gbe.
Fatimah Awesu sọ pe, ọmọ ohun, Mojisola ni oun n woju lati tan iya ati isẹ idile awọn, sugbon wọn da ẹmi rẹ legbodo, wọn fi ina ọmọ jo oun.
Iya yi sọ eyi fun BBC Yoruba ni ile-ẹjọ giga kan ni Ilorin, olu-ilu ipinlẹ Kwara lẹyin igbẹjọ lori iku ọmọ rẹ.
O ni oun o kawe sugbọn oun pinnu lati tọ awọn ọmọ oun ki wọn si ni ẹkọ to ye koro.
O fi kun-un pe, ipinnu yi lo faa ti oun fi n se orisirisi isẹ lati baale sanwo ile-ẹkọ awọn ọmọ oun.
O ni oun gbalẹ ta, lọta, gba owo alajẹsẹku, ati bẹẹ bẹẹ lọ lati ran Mojisola ni ile-iwe, ni ireti wi pe to ba yege to bẹrẹ isẹ yoo ran oun lọwọ lori awọn aburo rẹ, lai mọ pe aye o ni jẹ ki oun jere rẹ.
Pẹlu omije loju, iya yi wa rọ ijọba lati gbe oun nija lori ẹjọ naa ki awọn to sisẹ ika yii ma lọ lai jiya ẹsẹ wọn.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́
Saaju ni ibẹrẹ igbẹjọ, Fatimah Awesu to duro gẹgẹ bi ẹlẹri kẹta salaye fun ile-ẹjọ bi irin-ajo naa se ri nigba to dipe ago ọmọ rẹ ko lọ mọ.
O ni oun n gbe ni iluu Sango-Ota, nipinlẹ Ogun.
Igba to n dahun ibeere latẹnu agbẹjọro alatako, DPP Mohammed Akande, Fatimah sọ pe ago mẹrin idaji ni oun tẹ ọkọ leti wa si ilu Offa.
"Ni ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, ni mo bẹrẹ si ni pe nọ́mbà Mojiṣọla ti ko lọ, ẹru bami, mo si ke si Alfa kan, Alfa Ismail to jẹ ọmọ Ọffa sugbọn ti a jọ n gbe ni Sango-Ota.
"Alfa yii naa pe nọmba rẹ, igba ti ko lọ lo wa kesi awọn eeyan rẹ lọffa lati bawa waa lọ.
"Esi ti wọn fun wa ni pe ka gbera ka maa bọ ni ilu Offa, ilẹ ti su nigba naa, sugbọn ni afẹmọju ọjọ keji, ni nnkan bii ago mẹrin, agbera lọ si ilu Offa.
"Igba ti a de Offa, awọn ọlọpaa tun gbe wa lọ si olu ileesẹ ọlọpaa Kwara to wa ni Ilorin.
Ibẹ na ti fi fọto oku Mojisọla han ọrẹ rẹ, Blessing to mẹjọ lọ agọ ọlọpaa nibẹrẹ, lo ba daku rangbọndan koto ji pada saye.
"Bi a se mọ pe wọn ti pa Mojisola ni yẹn o"
Ìdájọ́ Adájọ́

Lẹyin eyi ni adajọ, Ibrahim Yusuf gbe idajọ ranpẹ kalẹ.
O sun igbẹjọ si ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹta.















