"Mo ní ọmọ kan ṣoṣo, mo sì ti pàdánù rẹ̀ sínú ìjàmbá iná tó pa ọ̀dọ́ 59, kò sí ohun tí mò ń ṣe láyé mọ́"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan ni inu n bi nipa isẹlẹ ina to waye ni orilẹede Macedonia, eyi to pa awọn ọdọ mọkandinlọgọta nile ijo kan nibi ti wọn ti n se faaji lopin ọsẹ.
Awọn eeyan yii si lo n wa idahun si ọpọ ibeere to gba ọkan wọn.
Lara iru awọn eeyan yii ni Dragi Stojanov, to padanu ọmọ kan soso to bi sinu ijamba ina ọhun.
"Ẹ jẹ ki n sọ fun yin niwaju gbogbo eeyan, ẹ ka ohun ati aworan mi silẹ, oku ni emi ti ẹ n wo yii, mo ti padanu ohun gbogbo t imo ni… gbogbo ilẹ Yuroopu ni ya mọ eleyii"
"Lẹyin ijamba yii, ki ni mo nilo lati w ani aye fun? N ko nilo aye mọ"
"Mo ni ọmọ kan soso, mo si padanu rẹ."
Amọ aarẹ ilẹ North Gordana, arabinrin Siljanovska-Davkova ni o yẹ kawọn eeyan kan le salaye ohun to waye naa.
"Ko si ọkankan ninu awọn eeyan to lọwọ ninu ijamba ina yii, ti yoo bọ lọwọ idajọ ofin pẹlu idajọ ati ijiya rẹ."
"Ko si ohun to ju ẹmi eeyan lọ, paapaa ẹmi awọn ọdọ."
Ijọba orilẹede naa ti wa kede idaro ọlọjọ meje yika orilẹede naa, ti yoo si sepada pajawiri gẹgẹ bi ara iwadi to n lọ lọwọ lati se awari ohun to fa isẹlẹ naa.
"Arabinrin mi ku, emi ye amọ oun ko ye"
Bakan naa, Marija Taseva n gbadun ara rẹ pẹlu arabinrin rẹ nile ijo Pulse club nilu Kocani, North Macedonia, lorilẹede Amẹrika lọjọ Satide, ni ijamba waye.
Wọn n wo akọrin kan, ti wọn n pe ni DNK, awọn akọrin meji tii se gbajumọ olorin takansufe kan lorilẹede naa,ni ijamba ina ọhun waye.
Eeyan mọkandinlọgọta si lo dagbere faye lasiko ijamba ina to waye ọhun ninu ile ijo yii, tawọn marundinlogọjọ mii si fara pa.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ yii se waye fun ileesẹ akọroyin Reuters, Marija, tii se ẹni ọdun mọkandinlogun ni "Gbogbo eeyan kan sadede n pariwo ni, ti wọn si n kigbe pe ẹ jade kuro nibi, ẹ jade kuro nibi."
Idi ree ti ọpọ eeyan se n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi wọn amọ oju ọna kan soso lo wa fun eeyan bii ẹẹdẹgbẹta lati jade nitori wọn ti ti ilẹkun to wa ni ẹyin ile ijo naa.
"Mi o mọ bo se waye amọ mo kan sadede ba ara mi nilẹ ni, n ko le dide mọ, ti awọn eeyan si n tẹ mi lori mọlẹ."
Amọ Marisa papa dide nilẹ, to si sa lọ sibi ti aabo wa amọ eyi ko ri bẹẹ fun arabinrin rẹ.
"Arabinrin mi ku, emi ye amọ oun ko ye."
Ileesẹ Ọlọpaa ti mu eeyan mẹẹdogun si ahamọ lori isẹlẹ yii, ti Minisita fọrọ abẹle nilẹ naa, Pance Toskovski si salaye pe ẹri wa to mu ifura wa pe iwa gbigba abẹtẹlẹ ati ajẹbanu so pọ mọ isẹlẹ ijamba ina naa.
Èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá iná ilé ijó wọ 59, àwọn tó farapa di 155
Èèyàn tó ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó ṣẹ́yọ ní ilé ijó kan ní orílẹ̀ èdè North Macedonia ti gbẹ̀mí lọ́rùn èèyàn mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59), táwọn márùndínlọ́gọ́jọ (155) míì sì farapa.
Àwọn aláṣẹ sọ pé nǹkan bíi aago méjì àbọ̀ òru ni iná náà bẹ̀rẹ̀ ní ilé ijó Pulse Club ní Kocani, ìlú kan tó wà ní ọgọ́rùn-ún kìlómítà sí ìlú Skopje, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn gbajúmọ̀ olórin kan, DNK ló ń ṣe ayẹyẹ orin kíkọ lásìkò tí iná náà bẹ̀rẹ̀.
Olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè North Macedonia, Hristijan Mickoski sọ pé ọjọ́ ìbànújẹ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún àwọn bí àwọn ṣe pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́.
Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé orílẹ̀ èdè náà, Pance Toskovski sọ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé wọ́n ti pàṣẹ láti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́rin lórí ìjàmbá iná náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bákan náà ló ní ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ ọkùnrin kan, tí iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé kan, Mia náà sì ròyìn pé ẹni tó ni ilé ijó náà ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Fídíò kan ṣàfihàn báwọn olórin ṣe ń kọrin lọ́wọ́ lójú agbo kí iná tó ṣẹ́yọ láti orí àjà tó sì ń ràn kíákíá.
Bákan náà ni BBC tún fìdí fídíò kan tó ṣàfihàn báwọn èèyàn ṣe ń gbìyànjú láti pa iná náà múlẹ̀.
Ó hàn pé ilé ijó náà ṣì kún fọ́fọ́ lásìkò náà, táwọn èèyàn sì ń wo bí wọ́n ṣe máa pa iná ọ̀hún.
Marija Taseva, ẹni ogún ọdún sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Channel 5 TV pé níṣe ni òun ṣubú táwọn èèyàn sì ń tẹ òun mọ́lẹ̀ nígbà tí òun gbìyànjú láti sá jade lásìkò tí iná náà bẹ̀rẹ̀ àmọ́ tí òun padà móríbọ́.
Ó ní àwọn ṣì ń wá ẹ̀gbọ́n òun. Ó ní kò sí ní ilé ìwòsàn kankan lára àwọn ilé ìwòsàn tó wà ní agbègbè àwọn ṣùgbọ́n àwọn kò mọ̀ bóyá ó wà lára àwọn tí wọ́n kó lọ sí Skopje fún ìtọ́jú.
Toskovski tó kọ́kọ́ kéde pé èèyàn mọ́kànléláàádọ́ta ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ti fi kún ọ̀rọ̀ báyìí pé èèyàn márùndínlógójì ni wọ́n ti dámọ̀ lára àwọn tó jade láyé.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní ìjọba ti ń gbèrò láti kéde láti fi kẹ́dùn àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ àti láti ṣe àyẹ̀wò gbogbo àwọn ilé ijó tí wọ́n ti máa ń ṣe ìpéjọ ńlá.
Àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá náà ni wọ́n sọ pé ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí ọdún mẹ́rìnlélógún.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iná tó ṣẹ́yọ nílé ijó gbẹ̀mí èèyàn 51, ọgọ́rùn ún èèyàn míì farapa yánayàna
O kere tan, eeyan mọkanlelaadọta ti jade laye lorilẹede North Macedonia lẹyin ti ina ṣẹyọ nile ijo kan lorilẹede naa.
Yatọ si awọn to jade laye, ijọba ilẹ naa sọ pe ọgọrun eeyan mii lo tun farapa yanayana.
Afẹmọju oni ọjọ Aiku ni ina ọhun ṣẹyọ nile ijo 'Pulse club' to wa niluu Kocani to wa ni nnkan bii ọgọrun kilomita siluu Skopje, to jẹ olu ilu orilẹede naa.
Aworan lati agbegbe naa ṣafihan bi ina ọhun ṣe n jo ti eefin rẹ si n goke.
Iroyin ni nnkan bii aago mẹta oru ni ina ọhun bẹrẹ lasiko ti ẹgbẹ akọrin takasufee, DNK n ṣerẹ lọwọ, ina naa si jo titi di aarọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, nnkan bii ẹgbẹrun kan abọ eeyan lo wa ninu ile ijo naa lasiko ti ina ọhun ṣẹyọ.
Pupọ ninu awọn to wa ninu ile ijo naa lasiko iṣẹlẹ ọhun lo jẹ ọdọ.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹlẹ orilẹede naa jabọ pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn ohun elo ti ina maa n jade lara rẹ ti wọn n lo nile ijo ọhun lo ṣokunfa ina naa.
Wọn ti ko awọn to farapa lọ sile iwosan Kocani fun itọju.















