Ọlọ́pàá yìnbọn pa ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ìdí tí ọlọ́pàá kan, Ajele Oloyede fi gbẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ lásìkò tó wà lẹ́nu iṣẹ́.
Ajele Oloyede, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ti agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola fi léde, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tó ń pèsè ààbò fún iléeṣẹ́ kan tó wà ní Igbesa, ìpínlẹ̀ Ogun.
Odutola ṣàlàyé pé ọlọ́pàá kan láti oríkò iléeṣẹ́ náà tó wà ní Eko, Tolorunloju Stephen ló dé bá Oloyede níbi tó ti gbé orí lé tábìlì tó jókòó sí, ní nǹkan bíi aago kan ọ̀sán kọjá ogún ìṣẹ́jú.
"Ọlọ́pàá náà lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀, kò pẹ́ ni wọ́n gbọ́ ìró ìbọn, tí wọ́n sì bá a nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀"
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ pé Stephen bèèrè lọ́wọ́ Oloyede pé ṣé kò sí nǹkankan tó fi gbórílé tábìlì, tó sì fun lésì pé kò sí ohun tó ṣe òun.
Kò pẹ́ ni Stephen lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tó sì fi báàgì àti ìbọn rẹ̀ sórí tábìlì.
Odutola ní kò pẹ́ ni wọ́n gbọ́ ìró ìbọn, tí wọ́n sì bá Oloyede nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀.
Ó ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbé Oloyede lọ sí ilé ìwòsàn Ota General Hospital, tí dókítà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ si fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti jade láyé.
"Àwọn ọlọ́pàá ti ṣàbẹ̀wò sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, wọ́n ti mú ìbọn tó fi pa ara rẹ̀.
Òkú rẹ̀ ti wà ní yàrá ìgbóòkúpamọ́sí ní ilé ìwòsàn Ota General Hospital fún àyẹ̀wò àti ìwádìí," agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun sọ̀rọ̀.
Ó fi kun pé wọ́n máa gbé ẹjọ́ náà lọ síwájú ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn èyí tó wà olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Eleweran, Abeokuta.















