Ìdí rèé tí a kò fi ní wọ́ Babangida lọ sílé ẹjọ́ lórí ikú bàbá mi - Ọmọ MKO

Aworan MKO ati IBB

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Jamiu Abiola, ọmọ oloogbe MKO Abiola, ti ni ko ni da nkankan fun mọlẹbi Abiola ti wọn b ani awọn n gbe olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ibrahim Babangida lọ si ile ẹjọ lori iku baba wọn.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch, Jamiu ni asiko fun iwadii nipa iku baba wọn ti kọja, ti ọpọ awọn eeyan to mọ nipa ohun to waye ni ọjọ Kejila oṣu Kẹfa ti jade laye.

"A ko nilo lati gbe ẹnikẹni lọ si ile ẹjọ. Ọpọ ọdun ti kọja ati ọpọ awọn to mọ nipa iṣẹlẹ June 12 ti jade laye ," Jamiu ṣalaye.

O fikun pe wiwọ IBB lọ si ile ẹjọ lo yẹ ko waye lasiko saa keji aarẹ Olusegun Obasanjo nigba tie to ijọba awarawa w ani digbi, ti pupọ awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa si wa laye lati ṣalaye ohun ti oju wọn ri ati nnkan to ṣẹlẹ ni pato.

Bẹẹ ba gbagbe, ninu oṣu keji ọdun 2025 fun igba akọkọ, olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ọgagun fẹyinti Ibrahim Babangida, ti kede pe Oloye Moshood Kasimawo Olawale Abiola lo wọle ibo aarẹ ''June 12'' ọdun 1993 eyi to fagile.

Ọgagun Babangida kede ọrọ yii ninu iwe ti o kọ nipa ara rẹ eyi to ṣe ifilọlẹ rẹ l'Ọjọbọ ogunjọ oṣu Keji ọdun yii niluu Abuja.

Abiola dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) lọdun naa.

Babangida sọ ninu iwe naa to pe akọri rẹ ni "Irinajo Lẹnu Iṣẹ (A Journey in Service) pe Abiola la Alhaji Bashir Tofa oludije ẹgbẹ oṣelu National Republican Council (NRC) mọlẹ ninu ibo ọhun.

''Moshood Abiola lo jawe olubori ninu ibo aarẹ ọdun 1993 lẹyin to ni ibo to le ni miliọnu mẹjọ ti o si la Tofa ẹgbẹ NRC to ni ibo miliónu marun un mọlẹ,'' Babangida lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Babangida ni oun ti n gbero lati fagile le esi ibo naa tipẹ.

Babangida ni ''emi ni mo jẹbi gbogbo nnkan to ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko naa ti mo jẹ aarẹ orilẹede Naijiria.''