Àṣírí àwọn ajínigbé àti ọlọ́kadà méjì tó ń ṣe alamí fún wọn tú

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, DefenceHQ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ṣinku ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afunrasi meji ti wọn jẹ ọlọkada ti wọn n ṣeranwọ fun awọn ajinigbe lati ṣọṣẹ nipinlẹ Ondo.

Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Alfried Afolabi, ṣalaye pe ọwọ tẹ ọgbẹni Sunday Komolafe ẹni ọdun mọkandinlogoji, ẹni to jẹ ọlọkada to si ma n ṣe iranwọ fun awọn ajinigbe.

Kọmiṣọna ṣalaye pe afunrasi naa jẹwọ pe ohun ma n ba awọn ajinigbe ọhun ra ounjẹ, bẹẹ ni ohun tun ma n ba wọn ṣọ opopona lati mọ irinkerindo awọn arinrinajo loju popo.

O ṣalaye pe afunrasi naa jẹwọ pe awọn ajinigbe naa ma n fun un lowo ni ibamu pẹlu iye owo ti wọn ba gba lọwọ awọn ti wọn ba ji gbe.

Kọmisọna ṣalaye pe ọgbẹni Komolafe mu wọn lọ ilu Akunu-Akoko, nibi ti ọwọ ti tẹ afunrasi meji mii, Umaru Abubakar Sanda ati Yusuf Ahmadu.

Umaru Abubakar jẹwọ fun awọn Ọlọpaa pe oun lo ma n ṣọ igbo nigbakuugba ti wọn ba ji eniyan gbe.

Kọmisọna Afolabi sọ pe iwadii ti wọn ṣe tọ wọn lọ sọdọ ọgbẹni Lekan Temitope to jẹ ọkan lara awọn ọlọkada to n ṣiṣẹ fun awọn ajinigbe nipinlẹ Ondo.

O ṣalaye siwaju si pe ọwọ tẹ awọn afunrasi ajinigbe meji, Ridwan Salisu, ẹni ọdun marundinlaadọta ati Umar Isyaku ẹni ọdun mọkandinlogun, ti wọn si ba owo to le ni milliọnu mẹfa ni ọwọ wọn.

Kọmisọna salaye pe ni kete ti ọwọ tẹ awọn afunrasi yii, wọn ṣalaye pe owo POS ni owo naa, ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ boya owo POS tabi owo ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn jigbe ni owo ọhun.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipinlẹ Ondo lo ti di oriko itaja fawọn ajinigbe to si fẹẹ dabi ẹni pe ko si ẹnikẹni to n yẹ wọn lọwọ wo, bi wọn ṣe n ṣọsẹ lorekore ni wọn si n gba ọpọlọpọ milliọnu naira lọwọ awọn ti wọn n jigbe.

Laarin oṣu ti a wa yii, iṣẹlẹ ijinigbe bii mẹta lo ti waye to si jẹ pe awọn ajinigbe naa gba owo ki wọn to tu awọn eniyan ti wọn jigbe silẹ.

Ni ọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe ko awọn eeyana mẹsan n ni ilu Abo to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Akure, ti wọn si gba ogun milliọnu nai ra ki wọn to tu wọn silẹ.

Bakan naa, awọn afunrasi ajinigbe ṣakọlu si aba mẹrin nipinlẹ Ondo ti wọn si ṣekupa awọn eniyan nibẹ, ti ọpọlọpọ awọn eeyan mii si farapa.

Ṣugbọn lẹyin awọn iṣẹlẹ yii, ọlọọpa ti ji giri pẹlu ilẹri pe wọn yoo fọ ipinlẹ Ondo mọ lọwọ iwa ọdaran ati ijinigbe.

Kọmisọna ọlọpaa Ipinlẹ Ondo wa gboriyin fun ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun, fun ileri rẹ lati ṣagbekale awọn ohun elo igbalode fun wọn ki wọn le kapa iṣẹlẹ ijinigbe nipinlẹ Ondo.