Kókó ọ̀rọ̀ tí Alaafin Oyo tuntun sọ l'ọdun Ìtúnu Àwé lẹ́yìn tó dé Adé Sango tán ní Koso

Alaafin Oyo tuntun, Ọba Akeem Abimbola Owoade, ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ara wọn jin fun Ọlọrun, ki wọn si tun maa dupẹ lọwọ Eleduwa fun bi o ṣe dawọn si.
Alaafin Owoade to gba ade Sango ni Koso lọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta niluu Oyo sọrọ yii ninu ọrọ ikini ku ọdun to fi ranṣẹ sawọn musulumi to n ṣe ọdun itunu awẹ.
Ninu atẹjade iṣẹ ikini ku ọdun itunu awẹ ti Alaafin fi sita lati ọwọ Ọgbẹni Bode Durojaye to jẹ adari eto iroyin ati ilukoro rẹ, Ọba Owoade sọ pe gbigba ohun ti Ọlọrun Allah ba ti wi n ṣapejuwe iwa igbọran eyi to jẹ ọpakuntẹlẹ oṣu Ramadan.
Ọba Owoade ni asiko itunu awẹ yii pe fun kawọn eeyan maa ṣaanu fawọn alaini lawujọ.
''Ti a ba fẹran ara w ani toootọ, eto iṣejọba yoo lọ deede ni Naijiria, eto idibo wa yoo kẹsẹjari, awọn adari yoo fi ifẹ han sawọn araalu ti wọn n dari.
Eyi gan an ni ọdun itunu awẹ wa fun, eyi si ni mo rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati maa ṣe.
Ifẹ ti yoo maa jẹ ki eeyan kọkọ ro ti ẹlomiran, ti ko si ni maa ro nipa ti ara rẹ nikan,'' Alaafin lo sọ bẹẹ.
Ọba Owoade ni bi ọrọ-aje Naijiria ti n ṣojojo pe fun kawọn musulumi ma ro nipa ara wọn nikan lasiko pọpọsinsin ọdun itunu awẹ to n lọ lọwọ yii.
Alaafin Oyo ni lara awọn ẹkọ to wa ninu oṣu Ramadan ni ki eeyan maa ranti awọn alaini lawujọ.
O ni nipa siṣe eleyii ni a le fi dupẹ lọwọ Eleduwa to n pese fun wa.
Alaafin ni o ṣe pataki lati ma gbagbe ohun ti ọdun Eid-El-Fitri tumọ si bi awọn eeyan ti n ṣayẹyẹ ọdun itunu awẹ.
Ori-ade naa ni ọdun itunu awẹ ju kawọn eeyan kan maa dawọ idunnu nikan lọ, tori asiko to pe fun fifi ifẹ han sawọn ẹlomiran papaa julọ awọn alaini ni asiko ọdun Eid-El-Fitri jẹ.















