Ilẹ̀ rírì tó wáyé ní Myanmar ti gbẹ̀mí èèyàn 1,600

Oríṣun àwòrán, Reuters
Àwọn èèyàn tó ti pàdánù ẹnu wọn nínú ìjàmbá ilẹ̀ rírì tó wáyé ní Myanmar ni wọ́n ní ó ti lé ní ẹgbẹ̀jọ (1,600) táwọn tó sì farapa ti di 3,400.
Ní ọjọ́ Àìkú ni ilẹ̀ rírì tó lágbára wáyé ní orílẹ̀ èdè náà tó sì tún ṣàkóbá fáwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ.
Ilẹ̀ rírì náà ṣọṣẹ́ ní Thailand àti China níbi tí èèyàn mẹ́tàdínlógún ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní Bangkok, olú ìlú orílẹ̀ èdè Thailand nígbà tí ilé alájà ọgbọ̀n tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ dàwó látàrí ilẹ̀ rírì Myanmar.
Èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́rin ni wọ́n ṣì ń wá ní Bangkok, táwọn tó lé ní ọgbọ̀n sì tún farapa.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ilẹ̀ rírì ṣàkóbá fún ni kò rí ọ̀nà láti àwọn ohun èlò ìrànwọ́ tí wọ́n pèsè fún wọn bí ilẹ̀ rírì náà ṣe ti ba ọ̀pọ̀ ọ̀nà àti ohun améyédẹrùn jẹ́.
Òṣìṣẹ́ ètò pàjáwìrì tó bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé ó ṣeéṣe káwọn èèyàn tó bá ìjàmbá náà lọ tún lékún si nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà lábẹ́ ilẹ̀ rírì náà.
Bákan náà ni àwọn tó ń bojú àánú wo ni sọ pé kò sí àwọn èlò ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì tó bẹ́ẹ̀ mọ́ láti fi ṣe ìrànwọ́ fáwọn tó farapa nínú ìjàmbá náà.
Èèyàn tó lé ní 1000 ti kú, ọ̀pọ̀ di àwátì, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó wáyé ní Myanmar

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba Ologun ni Myanmar ti kede pe o ti le ni ẹgbẹrun kan eeyan to ku, ti 2,376 si farapa lẹyin ti ilẹ riri waye lọjọ Ẹti.
Ilẹ riri naa lagbara debi pe, ipa rẹ de orilẹede Thailand to mule ti Myanmar,
Pupọ ninu awọn to ku, to si farapa, lo waye ni ilu keji to tobi julọ nibẹ, Mandalay, eyi to sunmọ ibi ti ilẹ riri naa ti waye.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n ṣiṣẹ karakara. Ikọ kan to n doola ẹmi awọn eeyan ni Mandalay sọ pe, ọwọ ni awọn fi n fa awọn eeyan jade labẹ ilẹ.
Ni Thailand, ile alaja gogoro kan ti wọn n kọ lọwọ ni ọpọ fi oju si, lẹyin to dawo lulẹ nitori ilẹ riri to waye ni Myanmar.
O le ni ọgọrun un oṣiṣẹ abanikọle ti wọn n wa bayii. Wọn ti fidi iku eeyan mẹfa mulẹ.
Awọn olori ijọba Ologun ni Myanmar ti bẹrẹ si rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ awọn orilẹede agbaye.
India ati China to sunmọ wọn si ti nawọ iranlọwọ.
Ileeṣẹ iroyin AFP naa fi iroyin kan lede wí pe eeyan mẹtalelogoji lo ti dawati bayii.
Ọga ọlọpaa ẹkun Bang Sue, Worapat Sukthai, sọ pe oun gbọ tàwọn eeyan to ha sabẹ ile to wo naa n bẹbẹ fun iranwọ lati jade nigba toun de ibi ti wọn ti n kọ ile naa.
Ọfiisi awọn oṣiṣẹ ìjọba ni a gbọ pe wọn fẹ fi ile to dawo naa ṣe ko to wo lulẹ.
Ẹwẹ, lẹyìn iṣẹju mejila ti ilẹ rírì ṣẹlẹ ni Myanmar ni omiran tun waye, gẹgẹ bi ajọ to n rí si ọrọ inu ilẹ lorilẹede Amẹrika ṣe fidi rẹ múlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ojora mu mi gan an nigba ti ilẹ riri ṣẹlẹ"
Akọriyin BBC ni Bangkok sọ pe oun n dana ounjẹ lọwọ ni nigba ti ilẹ riri akọkọ ṣẹlẹ.
"Ẹru ba mi, ojora si mu mi nigba ti ilẹ riri ṣẹlẹ ní Bangkok.
Mi o tiẹ tete mọ pe ilẹ riri ni tori o ti to ọdún mẹwaa tí iru iṣẹlẹ bayii ti waye ni Bangkok.
Bayii ni gbogbo wa ṣe sare jade sita lati wo ohun to n ṣẹlẹ gan an," obinrin naa ṣalaye.
O ni wọn o fi ti ilẹ riri ṣe pẹlu bí wọn ṣe kọ awọn ile to wa nilu Bangkok.
O ni eyi ni yoo jẹ ki iṣẹlẹ naa ṣe akoba to pọ.
Ọpọ ile ni ilẹ riri naa bajẹ niluu Bangkok ti i ṣe olu ilu orilẹede Thailand nigba ti o si ba ọpọ titi jẹ ni Myanmar.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba kede ilu o fararọ
Ijọba ologun to n ṣakoso Myanmar ti ilẹ riri naa ti waye ti kede ilu o fararọ làwọn ẹkun Sagaiing, Mandalay, Magway, Bago, Shan ati ni Naypyidaw.
Ninu atẹjade kan ti BBC ri, ijọba ti paṣẹ iwadii lori ọṣẹ ti ilẹ riri naa ṣe.
Ijọba tun pàṣẹ wi pe k'awọn oṣiṣẹ to n rí si iṣẹlẹ pajawiri tẹsiwaju iṣẹ idoola ẹmi lawọn agbegbe ti ilẹ rírì ọhun ti ṣọṣẹ.
Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọba tẹsiwaju ipade pajawiri ti wọn n ṣe lori iṣẹlẹ naa.















