Mọ̀ nípa àbá òfin ọjọ́ orí olùdíje ààrẹ Nàìjíríà, ìdájọ́ ikú àtàwọn míì tí ilé aṣòfin l'Abuja ń gbé yẹ̀wò

Oríṣun àwòrán, Nigerian House of Representatives/X
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja buwọlu abadofin mejilelọgbọn to da lori oniruuru ọrọ ilu laarin ọsẹ yii fun ipele keji.
Diẹ lara awọn abadofin naa da lori ọjọ ori oludije fun ipo gomina ati aarẹ orilẹede Naijiria, atunṣe ofin idajọ iku, fifagile ofin to daabo bawọn gomina lati ma le ṣewadi wọn lori oye, sisọ awọn olokowo ọmọ ilẹ okeere di ọmọ Naijiria ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn abadofin naa ni pipada si ijọba ẹlẹkun-jẹkun eyi ti olootu ijọba yoo jẹ olori orilẹede Naijiria wa.
Wọnyii ni diẹ lara awọn abadofin ti ile aṣoju-ṣofin l'Abuja buwọlu fun ipele keji:
Abadofin lori ọjọ ori oludije fun ipo gomina ati aarẹ Naijiria
Ile aṣoju-ṣofin fẹnuko lori abadofin to ṣe alakalẹ wi pe ẹnikẹni to ba fẹ dije fun ipo gomina ati ipo aarẹ orilẹede Naijiria ko gbọdọ ju ọgọta ọdun lọ.
Ile si gba aba yii wọle, eyi to jẹ ki wọn buwọ lu u fun ipele keji.
Pẹlu abadofin yii, awọn ọmọ ile aṣoju-ṣofin n gbero lati ṣe ayipada abala 131 ati 177 ninu iwe ofin orilẹede Naijiria eyi to sọ nipa ọjọ ori ti ẹni to ba fẹ dije fun ipo gomina tabi ipo aarẹ ni Naijiria gbọdọ to.
Ti aba naa ba di ofin, awọn oloṣelu bii Atiku Abubakar, Peter Obi, Rabiu Kwankanso to fi mọ Aarẹ Bola Tinubu ko ni koju oṣunwọn lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2027.
Lọwọ yi, ohun ti ofin sọ ni pe ẹnikẹni ro ba fẹ dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria gbọdọ to ọmọ ọgbọn ọdun lọjọ ori, o si gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan, ati pe o tun gbọdọ ni iwe ẹri ile ẹkọ girama.
Abadofin lori sisọ ọmọ ilẹ okeere di ọmọ Naijiria nipa idokowo
Abadofin mii ti ile aṣoju-ṣofin tun buwọlu fun ipele keji ni sisọ ọmọ ilẹ okeere di ọmọ Naijiria nipa idokowo.
Abadofin yii yoo fawọn ọmọ ilẹ okeere ti wọn ti gbọrẹgẹ jigẹ ninu okowo wọn ni Naijiria lati di ọmọ onilu.
Ti aba yii ba le di ofin, ile aṣofin ni yoo jẹ koriya fawọn oniṣowo lati ilẹ okeere lati wa dokowo lorilẹede Naijiria.
Ọpọ awọn oniṣowo alada nla lo ti wa ni Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun amọ ti wọn ko le jẹ awọn anfaani tawọn ọmo Naijiria n jẹ.
Ile aṣoju-ṣofin ni gbogbo iru ni irufẹ awọn eeyan bayii yoo maa janfaani to tọ si wọn gẹgẹ bi ti n kopa lati mu ọrọ aje Naijiria gbooro si.
Abadofin lori pipada si ijọba ẹlẹkun-jẹkun
Lara abadofin mejilelọgbọn ti ile aṣoju-ṣofin l'Abuja buwọlu fun ipele keji naa ni eyi ti yoo da Naijiria pada si eto ijọba ẹlẹkun-jẹkun wa.
Ile n gbero lati ṣe ayipada abala iwe ofin Naijiria lati pese fun ọfiisi olootu ijọba gẹgẹ bii olori ijọba orilẹede Naijiria ati ọfiisi aarẹ gẹgẹ bi olori orilẹede Naijiria.
Ti ẹ o ba gbagbe, iru iṣejọba yii ni Naijiria kọkọ lo lẹyin ti o gbomina lọdun 1960.
Alhaji Tafawa Balewa ni olori ijọba nigba ti Nnamdi Azikwe jẹ aarẹ orilẹede Naijiria.
Adadofin lori atunṣe idajọ iku
Atunṣe idajọ iku naa wa lara awọn abadofin ti ile buwọlu fun ipele keji laarin ọsẹ yii.
Ile aṣoju-ṣofin n gbero lati ṣe atunṣe idajọ iku ni Naijiria ki o le w ani ibamu pẹlu ohun to n ṣelẹ lawọn orilẹede agbaye mii.
Ile aṣoju-ṣofin ni ohun tawọn fẹ ṣe ni pe ki eto idajọ iku maa waye lai si wi pe ẹnikẹni n tẹ ẹtọ ọmọniyan ọmọ Naijiria kankan mọlẹ.
Bakan naa, ni ile tun sọ pe awọn n ṣe atunṣe lori idajọ iku ki eto abo le gbeeru si ati ki adinku le ba iwa ọdaran ni Naijiria.
Abadofin ti yoo jẹ kawọn gomina ati igbakeji aarẹ maa jẹjọ lori oye
Awuyewuye waye lori abadofin ti ile aṣoju-ṣofin jiroro le lori wi pe kawọn gomina, igbakeji wọn ati igbakeji aarẹ maa jẹjọ ti ẹnikẹni ba fẹsun kan wọn lori oye.
Eyi ṣẹlẹ lẹyin ti ile kede idaduro ijokoo lori abadofin naa, eyi to jẹ ki oniruuru ẹgbẹ ajafẹtọọ bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.
Amọ, igbakeji adari ile, Họnọrebu Benjamin Kalu, ṣalaye pe awọn so ijokoo lori abadofin naa rọ tori o nilo kawọn aṣofin fi pẹlẹ pẹlẹ jokoo lori rẹ ni.
O ni ọrọ naa kii ṣe nnkan ti ile le sare gbe igbesẹ lori rẹ bi awọn abadofin mii ti wọn ti wọ ipele keji.















