Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nipa Abisola, ọmọbìnrin Gómìnà Abiola Ajimobi, tó jáde l'áyé

Oríṣun àwòrán, Akin Akinwale/X
Iku o dọjọ, arun o doṣu, iroyin iku Abisola Kola-Daisi, akọbi ọmọbinrin fun gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, oloogbe Abiola Ajimobi si n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi titi di akoko yii.
Laaarọ Ọjọbọ ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹta yii ni iroyin iku Abisola Kola-Daisi, jade si ori ayelujara.
Lati igba ti iroyin iku rẹ ti jadenaa lawọn eeyan ti n ṣe idaro rẹ papaa julọ lori itakun ayelujara.
Wọnyii ni awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Abisola Kola-Daisi to d'oloogbe
Bisola, ti ọpọ tun mọ si ẹlẹyinju aanu jẹ gbajumọ lawujọ awọn oniṣowo lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni oju opo LinkedIn rẹ, oun ni Oludari Agba fun ileeṣẹ Grandex Nigeria Limited, ileeṣẹ karakata kan ti iroyin sọ pe o jẹ ti iya rẹ, Florence Ajimobi.
Bakan naa ni iroyin sọ pe o jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Florence H, ile itaja aṣọ ati bata.
Orukọ inagijẹ ti ọpọ mọ Abisola si ni Abi-KD nigba aye rẹ.
Loootọ, ilu Eko ni wọn bi Abisola si, amọ, ilu California lorilẹede Amẹrika lo dagba si nibi to ti kẹkọọ gboye ninu imọ eto iṣuna ni ile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ California to wa ni Northridge.
Abisola ti figba kan ri ṣiṣẹ nile ifowopamọ, bakan naa lo tun ṣiṣẹ nile iṣẹ epo rọbi ati ile iṣẹ to n ri si kiko ọja wọle ati jade pẹlu ọkọ oju omi.
Lẹyin ti Abisola ṣiṣẹ lọkan o jọkan ile iṣẹ tan ni o bẹrẹ iṣẹ iṣe ara loge to yan laayọ gan an.
Ṣaaju ki o to lọ si orilẹede Amẹrika ni Abisola ti kọkọ lọ ile ẹkọ British School ni Lome lorilẹede Togo nibi to ti kẹkọọ nipa sisọ ede Faranse.
Abisola tun kẹkọọ gboye MBA nile ẹkọ giga fasiti lorilẹede United Kingdom, koda, arabinrin yii ti ọpọ mọ si ẹlẹyinju aanu tun gboye keji nile ẹkọ giga Havard Business School lorilẹede Amẹrika lọdun 2022.
Abisola ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọga agba nile iṣẹ Victoria's Secret lẹyin to pari ẹkọ rẹ lorilẹede Amẹrika, ki o to pada wale fun eto agunbanirọ ni Naijiria lọdun 2008.
Gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu ti ọpọ eeyan mọ ọ si, Abisola da ajọ AKD Foundation silẹ eyi to n lo lati ṣaanu fawọn ọmọ alainiya atawọn ọmọ to n rin igboro kiri lai nile ni Naijiria.
Ẹwẹ, ẹni to jẹ minisita fun eto owo iṣuna ati eto ijọba ni Naijiria, Atiku Bagudu, yan an oloogbe Abisola sipo gẹgẹ bi oludamọran pataki fun un.
Ipo naa lo si wa titi to fi ku.
Abisola, ọmọbìnrin Gómìnà Abiola Ajimobi, jáde l'áyé

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹni to jẹ akọbi ọmọbinrin fun gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, oloogbe Abiola Ajimobi, ti jade laye.
Owurọ Ọjọbọ ni iroyin Abisola Kola-Daisi, jade si ori ayelujara.
Arabinrin Abisola Kola-Daisi, ni iroyin sọ pe o dagbere fun aye lẹni ọdun mẹrinlelogoji.
Iku rẹ waye lẹyin ọdun mẹrin ti baba rẹ, oloogbe Abiola Ajimobi, to jẹ gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, jade laye.
Botilẹ jẹ pe a ko tii le sọ pato ohun to pa oloogbe naa, iroyin sọ pe orilẹede United Kingdom, lo ku si.
Ṣaaju iku rẹ, Bisola jẹ oludamoran pataki fun minisita to wa fun owo iṣuna, Atiku Bagudu.
Bakan naa lo jẹ iyawo fun Kolapo Kola-Daisi, ọmọ ọkan lara awọn oloye agba ilẹ Ibadan.
Oun naa si ni ọmọbinrin to dagba julọ ni awọn ọmọ Abiola ati Florence Ajimobi.
Ọmọ mẹta ni Bisola bi nigba aye rẹ.













