Wọ́n búra fún Abdourahamane Tchiani gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Niger

Aworan Ọgagun Abdourahamane Tchiani

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Aworan Ọgagun Abdourahamane Tchiani
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede Niger ti bura wọle fun Ọgagun Abdourahamane Tchiani, olori awọn ṣọja to ditẹ gbajọba alagbada lọdun 2023, lati dari fun ọdun marun-un.

Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni Niger gbe igbesẹ bibura wọle fun aarẹ ologun naa.

Ọgagun Tchiani lo le aarẹ tẹlẹ ni Niger, Mohamed Bazoum, kuro nipo ni 2023.

Lati ọdun 2023 naa ni Tchiani ti n tukọ Niger, ki wọn too bura fun gẹgẹ bi aarẹ ologun.

Bakan naa ni wọn gbe e ga sipo olori ologun, o si buwọ lu titu awọn ẹgbẹ oloṣelu to n dari tẹlẹ ka.

Nigba to n ṣeleri fawọn eeyan Niger lasiko ibura naa, eyi to waye ni olu-ilu, Niamey, Ọgagun Tchiani sọ pe oun ko ni i ja wọn kulẹ.

Igbesẹ ijọba ọlọdun marun-un yii ṣe e yipada, bi eto aabo ba si ṣe fẹsẹ rinlẹ si ni yoo sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, gẹgẹ bi ajọ to ṣagbatẹru rẹ ṣe sọ.

'Ìdààmú àwọn alákatakítí tó ń ṣẹlẹ̀ ní Niger wà lára ìdí táwọn ológun fi gbàjọba

O ti pẹ ti ikọ alakatakiti ẹsin Islam ti n yọ Niger lẹnu, idaamu ati ikọlu awọn eeyan naa si wa lara idi ti awọn ologun fi gbajọba bi wọn ṣe sọ.

Iditẹgbajọba naa waye lẹyin ti ologun gbajọba ni awọn orilẹede to mule ti wọn bii Mali, Guinea ati Burkina Faso.

Awọn orilẹede mẹrin yii ti lawọn ko ba France to ko wọn lẹru, ṣe mọ.

Wọn ti bẹrẹ ajọṣe pẹlu Russia.

Bakan naa lo jẹ pe gbogbo wọn ni wọn ti yapa kuro lara ajọ ECOWAS, eyi to n ṣoju awọn orilẹede Iwọ-Oorun Africa(West Africa).

Afi Guinea nikan ni ko ya.

Ijọba Ọgagun Tchiani fẹsun kan aarẹ tẹlẹ, Bazoum, pe o huwa iditẹ mọ ilu, o si tẹ eto aabo Niger loju mọlẹ.

Titi di asiko yii ni wọn ṣi fi Bazoum ati iyawo rẹ si ahamọ, ọmọ wọn ọkunrin nikan ni wọn fun lominira loṣu Kinni ọdun 2025.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin ANP ṣe wi, OgagunTchiani sọ pe igba ọtun to de ba Niger yii, wa ni ibamu pẹlu ofin iṣẹdalẹ orilẹede naa.

O lawọn ko ni i fa sẹyin nipa aabo awọn nnkan alumọni ti Niger ni, kawọn araalu le jẹ ọrọ̀ to n bẹ lorilẹede wọn.