Ọwọ́ tẹ babalawó àti àwọn mìí tó pa ọmọdé méjì láti inú ẹbi kan nàá fún ètùtù ọlà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu ibanujẹ ni mọlẹbi Onuche wa bayii, pẹlu bi wọn ṣe n ṣọfọ awọn ọmọ wọn obinrin meji, ti awọn afurasi eletutu ọla pa nipakupa niluu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.
Awọn ọmọdebinrin naa, Chizaram Onuche ati Chidinma Onuche, to jẹ ọmọ ọdun meje, jẹ ibatan nitori pe tẹgbọn-taburo ni awọn baba wọn.
Amofin Linda Ojims to gbẹnu ẹbi naa sọrọ, sọ pe inu ibanujẹ nla ni wọn wa, ti wọn si n beere fun idajọ.
"Ẹnikan ninu iya awọn ọmọ naa wa ninu oyun, lati igba to si ti gbọ iroyin iku ọmọ rẹ ni agọ ara rẹ ko ti ni alaafia mọ."
Amofin Ojims, sọ fun BBC Pidgin pe, ile ijọsin ni awọn ọmọ naa ti n bọ nigba ti ẹnikan lara awọn afurasi ti ọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii, da wọn duro, to sig be wọn lọ si ile kan ti wọn n kọ lọwọ.
Ọwọ ọlọpaa tẹ babalawo ati afurasi mii
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹrin lori ipani ṣetutu ọla ọhun.
Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa nipinlẹ, Grace Iringe-Koko, sọ ninu atẹjade kan l'Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2025, pe ọwọ awọn tẹ Babalawo kan, ọdọmọbinrin kan ati eeyan meji mii pe wọn lọwọ si iku awọn ọmọde naa.
Ọlọpaa sọ pe niṣe ni awọn afurasi ọhun fun awọn ọmọ n ani oogun oorun, ki wọn o to pa wọn ni agbegbe Ogbodo Pipeline, Rukpokwu, nijọba ibilẹ Obio-Akpor.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ṣe wi, babalawo lo fi ọgbọn tan awọn ọmọ naa lọ si ile rẹ, o fun wọn ni oogun mu pẹlu ọti kan ti wọn n pe ni Black Bullet, o pa wọn, to si tun rọ ẹjẹ wọn sinu iko.
Lasiko ti awọn ọlọpaa yabo ibuba awọn afurasi naa, ni wọn ni awọn ba awọn nnkan bii:
- Igo kan ti wọn rọ ẹjẹ awọn ọmọ naa si
- Ọbẹ ile idana kan ti wọn fi pa wọn
- Ofifo agolo ọti black bullet ti wọn fi kun awọn ọmọ naa loorun ki wọn o to pa wọn
- Sibi ti wọn fi gbe ẹjẹ awọn ọmọ naa sinu igo
Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Rivers, CP Olugbenga Adepoju, sọ pe iwadii ti n lọ lati wadii ijinlẹ nipa iṣẹlẹ naa, ati lati mọ boya awọn eeyan mii tun wa to lọwọ si i.
Bakan naa lo sọ pe idajọ ododo yoo waye, ti awọn to lọwọ ninu iku awọn ọmọdebinrin mejeeji yoo fojuwina ofin.
Ipaniyan fun etutu ọla n pọ si ni Naijiria
Laipẹ yii ni ajọ to n ṣe onka ni Naijiria, National Bureau of Statistics (NBS), fi abajade iwadii kan sita, ninu eyi ti wọn ti sọ pe ipaniyan fun etutu ọla to le ni aadọjọ ni awọn ni akọsilẹ nipa rẹ.
Pupọ ninu awọn ipaniyan ọhun si lo n wa lati ọwọ awọn ọdọ, ti oju nnkan lati tete ko ọrọ jọ.
Eyi ni wọn lo waye laarin oṣu mẹfa to kọja.
Lara awọn iṣẹlẹ ipaniyan ọhun ni eyi to waye nipinlẹ Kwara, nibi ti Alfa ẹsin Islam kan, ti pa akẹkọọ ile-ẹkọ awọn olukọ, Kwara State College of Education, Ilorin, Hafsoh Lawal.
Awọn ọlọpaa sọ pe afurasi ọhun pa oloogbe Lawal, to sig e ẹya ara rẹ fun etutu ọla, niluu Ilorin.
Eyi waye ni ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 2025.
Bakan naa ni ọwọ ọlọpaa tẹ pasitọ kan ati awọn eeyan mii fun ẹsun pipa akẹkọọjade fasiti ipinlẹ Eko, Quadri Adedamola Ogunbode.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi ẹ mulẹ fun awọn akọroyin, lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta 2025, pe awọn ti ri oku oloogbe Adedamọla nibi ti awọn afurasi sin in si.
Ṣaaju ni wọn ti mu Pasitọ Whepetoji Babaniyeh, wọn si pada mu Olaoluwa Ajisomo, iya rẹ; Omolara Ajisomo, lori ẹsun pe o ran awọn ọmọ rẹ meji, Teniola ati Olaoluwa Ajisomo, lọwọ lati sa lọ, lẹyin ti wọn ti kọwọ bọ apo ikowosi Oloogbe, ti wọn si ti gba 300,000 ẹnikọọkan nibẹ.
Lọdun 2022, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Naijiria, ke si ijọba apapọ lati kede nnkan o fararọ lori bi ipaniyan fun etutu ọla ṣe n pọ si jakejado Naijiria.








