Èèyàn 24 kú nínú ìjàmbá iná tó tíì l'ágbara jù ní South Korea

Aworan ina to n jo ni South Korea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O kere tan, eeyan mẹrinlelogun lo padanu ẹmi wọn nigba tawọn mẹrindinlọgbọn mii farapa ninu ijamba ina to ṣọṣẹ lorilẹede South Korea.

Ọpọ awọn to fara kaasa julọ ninu ijamba ina ọhun to ṣẹlẹ lẹkun ila oorun guusu orilẹede naa ni iroyin sọ pe ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ati aadọrin ọdun.

Ijọba orilẹede South Korea fidi rẹ mulẹ wi pe, eeyan mejila lo wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ ọrun latari ijamba ina ọhun.

Eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹtalelogun ni a gbọ pe ijamba ina yii ti sọ di alainile lori mọ bayii lẹyin ti wọn sa asala fun ẹmi wọn.

Adele aarẹ orilẹede South Korea, Han Duck-solo, sọ pe ijamba ina to ṣẹlẹ naa lo tii buru julọ ninu itan orilẹede naa.

Ile ijọsin kan to ti pe ọdun 1,300 ni ilu Uiseong ni a gbọ pe wọn ti tete ko awọn nnkan iṣembaye to wa nibẹ kuro lọ si ibomiran lẹyin ti ina mu ile naa.

Bi ijamba ina ọhun ṣe bẹrẹ niyii

Lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni a gbọ pe ina naa bẹrẹ lẹkun Sancheong ki o to ran de ẹkun Uiseong.

Iji lile to n ja lo tun jẹ ki ina ọhun ran de de ẹkun Gyeongbuk, Uiseong, Andong, Cheongsong, Yeongyang ati Sancheong.

Ijamba ina yii tun buru si lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu yii.

Ni ọjọ keji tii ṣe Ọjọru ni baalu ẹlikopita ileeṣẹ panapana kan ja lulẹ lori oke Uiseong nibi ti awabaalu naa ti ku.

Iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣe okunfa ijamba baalu to ja ọhun.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn panapana to fi mọ ẹgbẹrun marun un ọmogun ni wọn ti n gbiyanju lati pa ina naa

''Ijamba ina South Korea da bi ẹni pe aye fẹ parẹ''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijamba ina ninu igbo ko wọpọ lorilẹede South Korea, koda, eyi to ṣẹlẹ yii lo buri julọ ninu itan orilẹede naa.

Bi saare oko 42,000 ni ina ọhun ti bajẹ bayii, ọkunrin kan to n gbe abule Andong sọ fun BBC Korean pe ina ti jo ile oun raurau.

Ẹwẹ, ijọba ti sọ fawọn to farapamọ sile ẹkọ kan ni Andong wi pe ki wọn kuro nibẹ tori ina to n ṣoṣẹ yii maa to jo de ibẹ.

Ọkunrin kan ti ko ju ọgbọn ọdun lọ to n gbe ni Uiseong ṣalaye pe atoke atilẹ ile awọn ile kan ni ina ti jo.

''Awọn agbalagba lo n gbe awọn ile yii, ibẹ ni wọn si ti n gbe fun gbogbo ọjọ aye wọn.

Ni bayii ti ina ti jo ile wọn, ko si ibi ti wọn le lọ bayii,'' ọkunrin naa lo sọ bẹẹ.

Ina yii tun jo ile ijọsin Gounsa to wa lẹkun Uiseong eyi ti wọn ti kọ lati ọdun 618 AD.

Ina to ṣọṣẹ naa tun jo ile ijọsin awọn ẹlẹsin Buddhism.

Awakọ nla kan, Lee Seung-joo, ni oun ri bi awọn oke ṣe n jona nigba toun n wakọ lọ.

O ni ni ṣe lo da bi ẹni wi pe aye n parẹ pẹlu bi ina ọhun ṣe n jọ.

Adele aarẹ Han ni iji lile si n ṣe idina fawọn oṣisẹ panapana ti wọn n gbiyanju lati pa ina ọhun.

Ọgbẹni Han ni awọn n reti wi pe ki ojo rọ ki o le pa ina naa to n ran kaakiri.

Ijọba South Korea tun ti kede pe awọn yoo tubọ gbogun ti sisọ ina si igbo, eyi to jẹ ọkan lara ohun to n ṣokunfa irufẹ ijamba ina bayii.