Kò sí ohun tó ń jẹ́ ìgbìmọ̀ Sharia lábẹ́ òfin Nàìjíríà, ohun tí òfin sọ rèé – Amòfin

Àwòrán àwọn Alfa

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia ti ń da awuyewuye sílẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ìgbìmọ̀ náà ṣe ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní ìpínlẹ̀ Ekiti lóṣù Kìíní, ọdún 2025.

Ìgbésẹ̀ yìí fa awuyewuye káàkiri ilẹ̀ Yorùbá bí àwọn kan ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà, táwọn mùsùlùmí náà sì ń sọ pé àwọn kò tàpá sí òfin Nàìjíríà.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìgbìmọ̀ náà tún ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní ìlú Oyo tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde sì dúnkokò láti wọ ìgbìmọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́.

Ṣé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti buwọ́lu ìgbìmọ̀ Sharia nílùú Oyo ni? Ohun tí a mọ̀ rèé

Àwọn Alfa àti gómìnà Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook/Others

Gómìnà ìpínẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti kéde ìpinnu rẹ̀ láti wọ́ ìgbìmọ̀ Sharia tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ìlú Oyo lọ sílé ẹjọ́.

Gómìnà Seyi Makinde tẹnumọ ọ pé, ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ nìkan ló ní àṣẹ láti dá ohun tó bá jọ mọ́ ọ̀rọ̀ ilé-ẹjọ́ sílẹ̀.

Ó ní ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ náà láti dá ìgbìmọ̀ Sharia sílẹ̀ ní ìlú Oyo jẹ́ ohun tó lòdì sí ìwé òfin Nàìjíríà.

Ìkéde gómìnà yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ Sharia kéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní mọ́ṣáláṣí ńlá ìlú Oyo tó wà ní Akesan.

Agbẹnusọ gómìnà Oyo, Sulaimon Olanrewaju nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde sọ pé ohun tó bá ti jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà ìwé òfin Nàìjíríà.

Ó fi kun pé àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ láti mọ̀ bóyá ìwé òfin Nàìjíríà fi ààyè gba irúfẹ́ ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ó wòye pé ìgbìmọ̀ tó bá ti ń dá sí ọ̀rọ̀ aráàlú gbọdọ̀ ní àtìlẹyìn ìjọba ìpínlẹ̀ nínú bí bẹ́ẹ̀kọ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ títàpá sí òfin.

A ò nílò ilé aṣòfin tàbí ìbuwọ́lù gómìnà láti ṣe ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia - MURIC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, Àwọn olórí ẹ̀sìn Islam nílẹ̀ Yorùbá sọ pé ìgbìmọ̀ Sharia tí àwọn fẹ́ dá sílẹ̀ náà yóò kan máa jẹ́ atọ́nà fún àwọn Mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ogún pínpín, títú ìgbéyàwó sílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà Mínísítà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, Adebayo Shittu tó sọ nínú ọ̀rọ̀ pé láti bíi ọdún mẹ́wàá ni ìgbìmọ̀ yìí ti wà làwọn ìpínlẹ̀ Yoruba kan, tí wọ́n ti ń dá sí ọ̀rọ̀ láàárín àwọn Mùsùlùmí láìsí awuyewuye kankan.

Ó ní àìní ìmọ̀ kíkún nípa ìwé òfin Nàìjíríà ló ń mú kí àwọn gómìnà àti àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọ́ tó ń tako ìgbésẹ̀ náà.

"Ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní ìlànà ẹ̀sìn Islam ni nǹkan tó ń jẹ́ Sharia. Ìwé òfin Nàìjíríà sì fàyè gba èèyàn láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú.

Bákan náà ni Oludasilẹ ajọ MURIC to n ri si ẹtọ awọn musulumi, Ọjọgbọn Ishaq Akintola, sọ fun BBC Yoruba wi pe igbimọ Shari'ah l'awọn n beere fun kii ṣe ile ẹjọ Shari'ah nilẹ Yoruba.

Ọjọgbọn Akintola sọ pe ile ẹjọ Shari'ah maa nilo agbekalẹ ofin ki o to le ṣee ṣe.

O ni igbimọ Shari'ah ti bẹrẹ iṣẹ niluu Ibadan lati ọdun 2002.

Oludasilẹ MURIC ni o jẹ iyalẹnu foun pe Makinde n sọ fun gbogbo agbaye wi pe ko si Shari'ah nipinlẹ Oyo nigba ti o ti bẹrẹ lati ọdun 2002.

"Oja Oba ni igbimọ Shari'ah ti n jokoo niluu Ibadan ti wọn ti n gbẹjọ awọn musulumi.

Igbimọ Shari'ah ti n jokoo ni mosalaasi nla niluu Abeokuta, bakan naa ni igbimọ yii ti n jokoo lagbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko.

Ko kan awọn ọmọlẹyin Kristi rara.

Igbimọ Shari'ah yii ko le dajọ fun ẹnikankan.

Awa naa mọ pe a o le ni ile ẹjọ Shari'ah nilẹ Yoruba lai si ofin ti ile igbimọ aṣofin ati gomina ti buwolu.

Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ láti dá ìgbìmọ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin "Arbitration and Conciliation Act"

Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, amòfin Inibehe Effiong sọ pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ ìgbìmọ̀ Sharia lábẹ́ òfin Nàìjíríà.

Amòfin Effiong sọ pé ilé ẹjọ́ Sharia àti ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Sharia nìkan ni òfin Nàìjíríà fi ààyè gba báyìí tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń lò wọ́n.

Ó ní àwọn ilé ẹjọ́ yìí ni wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ tó bá wà ní ìpínlẹ̀ kan.

Ó sọ pé ìgbìmọ̀ Sharia kìí ṣe ẹ̀ka ìdájọ́ lábẹ́ òfin, tí wọn kò sì ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti ṣe ìgbésẹ̀ tàbí dájọ́ kankan ní ìlànà òfin.

Amòfin náà sọ pé lábẹ́ òfin tó gbé ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ tó le gbọ́ ẹ̀hónú àwọn èèyàn tí wọ́n panupọ̀ láti gbé ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ kìí ṣe bí i ti ìgbìmọ̀ Sharia yìí.

Ó ṣàlàyé pé tí wọ́n bá fẹ́ gbé irú ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kalẹ̀, àwọn èèyàn tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ yóò ní àjọsọ, tó sì máa wà ní àkọ́ọ́lẹ̀ pé àwọn fẹnukò láti jọ tọwọ́bọ àdéhùn láti yanjú àwọn ọ̀rọ̀ lábẹ́ ìgbìmọ̀ náà.

Ó sọ pé èyí ni òfin tó wà lábẹ́ "Arbitration and Conciliation Act" ọdún 2023 yóò dè.

Ó ní àmọ́ èyí kò de ìgbìmọ̀ Sharia tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá èyí tó ń fa awuyewuye láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn.

Ó tẹ̀síwájú pé kò sí òfin ìpínlẹ̀ kankan tàbí ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n fi dá ìgbìmọ̀ Sharia sílẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá.

"Fún ìdí èyí, kìí ṣe ìgbìmọ̀ tí wọ́n dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kìí ṣe iléeṣẹ́ ìjọba, tí wọn kò sì lè máa ri wọ́n gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìjọba.

"Ohun tí wọ́n bá ń ṣe báyìí jẹ́ ti aládàni, tí wọn kò sì lè pa ẹnikẹ́ni ní dandan lórí ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá ní nínú ìgbìmọ̀ náà."

Effiong fi kun pé àwọn tí wọ́n le wà lábẹ́ ìgbìmọ̀ "Arbitration and Conciliation Act" ọdún 2023 gẹ́gẹ́ bí òfin jẹ́ àwọn tí wọ́n ti fún ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí irúfẹ́ ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀, tí ọ̀pọ̀ wọn sì máa ń jẹ́ amòfin.