Ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì mẹ́rin tó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí Akpabio ti di ààrẹ ilé aṣòfin àgbà l'Abuja

Aworan Godswill Akpabio, Oby Ezekwesili atawọn sẹnẹtọ meji mii

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Senate

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oniruuru iṣẹlẹ lo ti waye lati igba ti Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ti bọ sipo aarẹ ile igbimọ aṣofin agba kẹwaa niluu Abuja.

Ọpọ ninu awọn iṣẹlẹ yii lo si ti fa awuyewuye eyi tawọn eeyan n sọ nipa rẹ lori itagun ayelujara.

Irufẹ iṣẹlẹ yii tun waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta yii lasiko ti ijokoo igbimọ ile lori ẹsun iyọnilẹnu fun ibalopọ ti Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Uduaghan fi kan Akpabio n lọ lọwọ.

Sẹnẹtọ Onyekachi Nwebonyi ati minisita eto ẹkọ telẹri ni Naijiria, Oby Ezekwesili, lo sọko ọrọ si ara wọn nibi ijokoo naa.

Wọnyii lawọn iṣẹlẹ gbankọgbi to ti waye nile igbimọ aṣofin kẹwaa l'Abuja lati igba ti Akpabio ti di aarẹ ile.

Faakaja laarin Sẹnẹtọ Nwebonyi ati Ezekwesili

Aworan Sẹnẹtọ Onyekachi Nwebonyi ati minisita eto ẹkọ telẹri ni Naijiria, Oby Ezekwesili

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Senate

Iṣẹlẹ faakaja yii lo waye laarin Sẹnẹtọ Onyekachi Nwebonyi ati minisita eto ẹkẹ tẹlẹ, Oby Ezekwesili lasiko ti ijokoo igbimọ ile lori ẹsun iyọnilẹnu fun ibalopọ ti Natasha fi kan aarẹ ile, Akpabio n lọ lọwọ lọjọ Iṣẹgun to kọja.

Ọrọ naa le debi wi pe awọn mejeeji bẹrẹ si ni pariwo mọ ara wọn ti awọn ti wọn jọ wa ni ijokoo naa si n dawọn lẹkun.

Bi ijokoo naa ṣe n lọ lọwọ ni Sẹnẹtọ Nwebonyi sọ pe ki Ezekwesili dakẹ ẹnu rẹ nigba to fẹ sọrọ nibi ijokoo ọhun.

Arabinrin Ezekwesili si da a pada fun wi pe aṣiwere oun naa.

Bayii ni ọrọ naa ṣe di ariyanjiyan ti o si lu ori itakun ayelujara pa lati ibẹ lọ.

Lẹyin naa ni Arabinrin Ezekwesili sọ pe Sẹnẹtọ Nwebonyi tabuku gbogbo ile aṣofin agba pẹlu bi o ṣe pe oun ni aṣiwere, amọ, Nwebonyi naa da a pada pe Ezrkwesili tabuku gbogbo obinrin pẹlu bi o ṣe ni ki oun gbẹnu lọwọ.

Lẹyin o rẹyin, ijokoo naa ko pada kẹsẹ jari lẹyin ti alaga igbimọ naa, Neda Imasuen, sọ pe ọrọ naa ti wa nile ẹjọ.

O ni eyi si ni ko ni jẹ ni ki ile aṣofin le ṣe nkankan lori rẹ.

Ile aṣofin agba ati Sẹnẹtọ Abdul Ningi

Aworan Abdul Ningi

Oríṣun àwòrán, Abdul Ningi/Facebook

Ni oṣu Kẹta ọdun 2024 ni Sẹnẹtọ Abdul Ningi to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Bauchi fẹsun kan ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja o ṣe oniruuru jibiti ninu eto iṣuna ọdun 2024 eyi ti ile buwọlu loṣu Kejila ọdun 2023.

Ningi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Hausa wi pe owo to le ni N3.7trn ni ko ni koko iṣẹ kan pato to wa fun ninu eto iṣuna ọhun.

Sẹnẹtọ naa ni ninu eto iṣuna N28trn ọdun 2024 ti ile buwọlu, N25trn lo wa fun iṣẹ kan tabi omiran nigba ti N3trn ko wa fun nkankan.

Ọrọ yii di awuyewuye ni ile aṣofin, lẹyin naa ni ọkan lara awọn alẹnulọrọ nile, Opeyemi Bamidele, sọ pe irọ nla ni Sẹnẹtọ Ningi pa fawọn akọroyin.

Sẹnẹtọ Bamidele ni Ningi sọrọ naa lati le jẹ ki ile yọ Akpabio nipo ni.

Lẹyin naa ni gbogbo ile dibo lati da Ningi duro fun oṣu mẹta gbako.

Ifanfa laarin Ali Ndume ati ile

Aworan Ali Ndume

Oríṣun àwòrán, Ali Ndume/Facekook

Iṣẹlẹ mi tun waye nile aṣofin agba l'Abuja loṣu Keje ọdun 2024 eyi to ni ṣe pẹlu Sẹnẹtọ Ali Ndume to n ṣoju ẹkun guusu ipinlẹ Borno.

Sẹnẹtọ Ndume sọ nigba naa pe Aarẹ Bola Tinubu ko mọ nipa iṣẹ ati oṣi to n bawọn ọmọ Naijiria finra tori awọn to n ṣiṣẹ pẹlu rẹ nile iṣẹ ijọba ko ni jẹ ko mọ ohun to n lọ.

Ọrọ bi awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC eyi ti Ndume naa jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ninu.

Ọrọ yii si lo jẹ ki alaga gbogbogbo APC, Abdullahi Ganduje, kọ iwe si ile igbimọ aṣofin agba wi pe ki wọn yọ Ndume nipo.

Lara ẹsun ti wọn fi kan Ndume ni pe o fẹ mu iyapa ba orilẹede Naijiria pẹlu ọrọ to sọ jade.

Bayii ni awọn aṣofin dibo ti wọn si yọ Ndume nipo, Tahir Monguno, sẹnẹtọ mii toun naa wa lati ipinlẹ Borno ni wọn fi rọpo rẹ.

Natasha ati Akpabio

Aworan ijokoo ile aṣofin agba

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wahala sẹlẹ laarin Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Akpabio ati amofin to n ṣoju ẹku idibo aarin gbogbo ipinlẹ Kogi, Natasha Uduaghan ni ogunjọ oṣu Keji ọdun yii lori ọrọ ibi ti Natasha n jokoo si.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin abẹle AIT se ti salaye, wahala naa bẹ silẹ nigba ti akapo ile, Mohammed Monguno ṣo fun ile pe Aṣofin Natasha Uduaghan kọ lati lọ jokoo si aye tuntun ti wọn yan fun.

Sẹnetọ Natasha kọ jalẹ pe oun ko le kuro ni aye to wa tẹlẹ, to si fẹsun kan aarẹ ile igbimọ aṣofin ati ile igbimọ pe wọn tẹ ẹtọ mọlẹ. Eyi lo fa ti Akpabio fi ni ki wọn gbe Natasha kuro ni ile aṣofin.

"N ko bẹru ẹ." Natasha sọ fun Akpabio. "Se ohun to ba fẹ ṣugbọn n ki kuro ni aye mi rara. O le pa ohun mi mọ."

Lẹyin ọjọ naa ni Sẹnetọ Natasha gbe olori ile, Godswill Akpabio ati Mfon Patrick lọ ile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Agbẹjọro rẹ, Victor Giwa sọ pe Patrick kọ nnkan soju opo Facebook rẹ to tabuku si Sẹnetọ Natasha.

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji, ọrọ naa ba ibo miiran yọ nigba ti Amofin Natasha bọ sori tẹlifisan Arise, to si fẹsun kan Akpabio pe o fẹ ba oun ni ajọsepọ, ti oun ko si gba lati se bẹ

O ni eyi lo fa ti olori ile fi fẹ fi aye su ni ile igbimọ aṣofin.

Ẹsun yii lo fa gbas gbos bayii debi wi pe ile aṣofin agba ti paṣẹ idaduro Natasha gẹgẹ bii sẹnẹtọ fun oṣu mẹfa bayii.