Ìjà parí, Pasuma àti Taye Currency parí aáwọ̀ tó wà láàárín wọn

Taye Currency àti Wasiu Pasuma

Oríṣun àwòrán, Taye Currency/Wasiu Pasuma/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀ èèyàn, pàápàá àwọn olólùfẹ́ orin Fújì, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé nǹkan kò lọ déédé láàárín àwọn gbajúmọ̀ olórin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma àti Alhaji Taye Akande Adebisi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Taye Currency.

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni pé bàbá sí ọmọ ni àwọn olórin méjéèjì máa ń ṣe kó tó di inú oṣù Kẹwàá, ọdún 2024.

Ní ọdún tó kọjá ni Taye Currency sọ lóde àríyá kan pé kí ẹnikẹ́ni má pe Pasuma ní bàbá òun mọ́ nítorí bàbá ẹgbẹ́ mọ iye ọmọ tọ bí àti pé Pasuma kò tó òun ún bí lọ́mọ rárá.

Ọ̀rọ̀ Taye Currency yìí fa awuyewuye láàárín àwọn olólùfẹ́ àwọn àgbà olórin náà débii pé wọ́n máa ń kọrin bú ara wọn lójú agbo.

Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ní ìjà ti parí.

Nínú fídíò kan tí Taye Currency fi sójú òpó Facebook rẹ̀ tó sì ti gba orí ayélujára, ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn àgbà olórin náà pàdé ní orílẹ̀èdè Saudi Arabia níbi tí wọ́n ti lọ ṣe Umurah ọdún 2025.

Fídíò nàá ṣàfihàn Taye Currency tó wọ yàrá tí Pasuma jókòó sí, tó sì ń bá àwọn olólùfẹ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa aáwọ̀ náà.

Taye Currency tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Pasuma nínú fídíò náà àmọ́ tó tẹnumọ pé Pasuma kò lè bí òun àti pé ẹ̀gbọ́n ló jẹ́ sí òun.

Ó ní ìdí tí òun fi máa ń pè ní bàbá ni bí ó ṣe fa òun lọ́wọ́ sókè àti pé ẹni tó bá ti gbé èèyàn lọ́dọ̀ àwọn bàbá ni àwọn máa ń pè é.

"Ní ọ̀dọ̀ ti wa, àwa kìí rí èèyàn fín, tí a bá rí ọmọ ọdún méjì tó bá èèyàn lọ bàbá ni a máa ń pè é.

"Mi ò kí ń ṣe ọmọdé o, mo nífẹ̀ẹ́ Paso ni. Ìwọ tó bá fẹ́ máa wú sími nítorí mò ń pe Paso ní bàbá, láti ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n sẹ́yìn ni mo ti wà pẹ̀lú Paso, láti ọdún 1993.

"Ẹni tó bá fa èèyàn lọ́wọ́ sókè, ọ̀gá èèyàn ni, bàbá èèyàn ni, mi ò jiyàn pé Paso kìí ṣe bàbá mi àmọ́ pẹ̀lẹ́ lákọ, ó lábo."

Lẹ́yìn náà ló tẹ̀ kí Pasuma, tó sì kọrin láti fi hàn pé ìjà parí láàárín àwọn méjéèjì, tí wọ́n sì fi ẹ̀rín túká.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn ṣì jọ wà, tí àwọn ń ṣe papọ̀ pẹ̀lú Pasuma láì sí èdè àìyedè kankan mọ́ láàárín àwọn.

Ta ni Pasuma?

Wasiu Alabi Pasuma

Oríṣun àwòrán, Wasiu Alabi Pasuma/Facebook

Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 1967 ni wọ́n bí Alhaji Wasiu Alabi Pasuma tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Paso.

Ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Eko ló gbé dàgbà pẹ̀lí ìyá rẹ̀, Alhaja Kubura Odetola tó máa ń pè ní ìyàwó Anọ́bì.

Ní ọdún 1984 ni Pasuma ní òun bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ orin sílẹ̀ lẹ́yìn tí òun gba ìmísí láti ara orin Wasiu Ayinde.

Ọdún 1993 ni Pasuma gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Recognition" jáde.

Lẹ́yìn ìgbà náà ló sì tún ti gbé àwọn orin tó lè ní ọgbọ̀n jáde.

Lágbolé Fuji, òdú ni Pasuma tí kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn olórin Fuji ló máa ń fẹ́ ṣe bí òun náà.

Lára àwọn tó gbà fún Pasuma ni Taye Currency tí òun náà jẹ́ àgbà olórin Fuji.

Onírúurú àmì ẹ̀yẹ ni Pasuma ti gbà nídìí iṣẹ́ orin Fuji.

Ta ni Taye Currency?

Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Taye Currency/Facebook

Taye Akande Adebisi, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Taye Currency jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orin Fuji.

Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó wà láti ìdílé olórin, Taye Currency ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni òun wà tóun ti ń kọrin.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 1974 ni wọ́n bí Taye Currency ní ìlú Ibadan.

Taye Currency máa ń fi àṣeyọrí rẹ̀ nídìí iṣẹ́ orin sọ iṣẹ́ takuntakun rẹ̀ àti ìrànlọ́wọ́ Wasiu Pasuma.

Ọdún 1999 ló gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ tó pè ní Millenium jáde.