Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ ojú omi àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó rì sínú Òkun Pupa

Oríṣun àwòrán, Sinbad Submarine
Ko din ni eeyan mẹfa to ku tawọn mẹsan an mii si farapa lẹyìn ti ọkọ oju omi awọn arinrin-ajo afẹ kan rì sinu Okun Pupa laaarọ Ọjọbọ ní Hurghada lorileede Egypt.
Olu ileeṣẹ orilẹede Russia to wà ni Egypt salaye ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ pe ero marundinlaadọta lo wa ninu ọkọ oju omi naa táwọn ọmọde si wa ninu wọn pẹlu.
Olu ileeṣẹ orilẹede Russia ọhun gbagbọ pe ọmọbibi ilẹ náà ní gbogbo ero to wa ninu ọkọ oju omi to ri sinu okun naa.
Oṣiṣẹ ìjọba Russia Kan to wà ni Hurghada, Viktor Voropaev, fi ìdí rẹ múlẹ pe ọmọ Russia marun un lo ku ninu ijamba ọkọ oju omi naa eyi tawọn ọmọde meji wa ninu wọn.
Awọn akọroyin BBC ni Egypt sọ pe iroyin fidi rẹ múlẹ wi pe eeyan mẹfa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ohun ti a mọ nipa ijamba ọkọ oju omi Sinbad ree

Oríṣun àwòrán, Sinbad Submarine
O kere tan, eeyan mẹfa lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti mẹsan an mii farapa.
Awọn oṣiṣẹ to n rí si iṣẹlẹ pajawiri ti doola eeyan mọkandinlogoji.
Gomina to n rí si ọrọ okun pupa ni Egypt, Amr Hanafy, ṣalaye pe eeyan marundinlaadọta lo wa ninu ọkọ oju omi naa pẹlu awọn ọmọbibi Egypt marun un.
Hanafy ni awọn ero to wa ninu ọkọ oju omi naa wa lati orilẹede Russia, Sweden, India àti Norway.
O ni awọn ọmọ Russia mẹfa lo ku ninu ìjàmbá ọkọ oju omi naa.
Igbagbọ wa pe ọkọ oju omi Sinbad yii ti n ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun lori okun pupa ki ijamba yìí tó wáyé.
Nibi ti ọkọ ojú omi Sinbad ri si sun mọ ebute okun to wà ni Hurghada nibi ti ọpọ eeyan maa n lọ fun irinajo igbafẹ.
Ko tíì si ẹni to mọ nnkan to ṣe okunfa ijamba ọkọ oju omi Sinbad, amọ, iwadii n lọ lọwọ.
Ijamba ọkọ oju omi wọpọ lórí okun ni Egypt
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọkọ oju omi yoo ri sinu okun pupa lagbegbe Hurghada lorilẹede Egypt.
Ọkọ oju omi kan táwọn arinrin-ajo afẹ wa ninu rẹ ri sinu okun ni Egypt lọdun 2024 nibi ti eeyan mọkanla ti ku eyi ti tọkọ taya ọmọ orílẹ̀-èdè UK wa ninu wọn.
Amọ, eeyan marundinlogoji lo mori bọ ninu iṣẹlẹ naa.
Awọn alaṣẹ orilẹede Egypt ti sọ pe iji líle kan lo ṣokunfa ijamba naa.
Ṣugbọn lara awọn tori ko yọ ti wọn ba BBC sọrọ ti ṣalaye pe awọn kudiẹ kudiẹ wa lori ọrọ abo nípa wiwọ ọkọ oju omi.















