Àwọn ànfààní tó wà nínú àjọ SWDC tí Tinubu ṣèṣẹ̀ buwọ́lu ìdásílẹ̀ rẹ̀ fún ilẹ̀ Yorùbá

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu ofin idasilẹ ajọ ti yoo maa ri si idagbasoke ilẹ Yoruba, SWDC, eyi ti ile aṣofin agba l'Abuja ti fontẹ lu tẹlẹ.

Ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta yii ni aarẹ ile aṣofin agba niluu Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, kede wi pe Aarẹ Tinubu ti buwọlu abadofin fun idasilẹ ajọ naa.

Ajọ SWDC wa fun idagbasoke awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba nipa ṣiṣe oniruuru akanṣe iṣẹ kaakiri ẹkun naa.

Ijọba apapọ yoo maa fun ajọ yii lowo lati ṣe oriṣiiriṣii akanṣe eto idagbasoke kaakiri ilẹ kaarọ o jiire.

Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja ṣalaye pe gbogbo ẹkun mẹfẹẹfa to wa lorilẹede Naijiria lo ti ni ajọ ti yoo maa ri si idagbasoke wọn bayii, lẹyin ti Tinubu buwọlu ofin idasilẹ ajọ SWDC ati SSDC eyi ti yoo maa ri si idagbasoke ẹkun guusu-guusu orilẹede Naijiria.

Anfaani to wa ninu ajọ idagbasoke SWDC fun ilẹ Yoruba

Lakọkọọ, ileeṣẹ aarẹ ni idasilẹ ajọ SWDC yoo ṣe iranwọ lẹka dida ileeṣẹ silẹ kaakiri awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba.

Ileeṣẹ aarẹ ni ajọ SWDC yoo jẹ ki awọn ileeṣẹ ati ọrọ aje gbooro si nilẹ Yoruba.

Ninu ọrọ rẹ, oludamọran aarẹ lori ọrọ ile aṣofin agba, Ọgbẹni Basheer Lado, sọ pe idasilẹ ajọ SWDC yoo ro awọn eeyan lagbara kaakiri ilẹ Yoruba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbẹni Lado tun sọ pe bi Aarẹ Tinubu ṣe buwọlu ofin idasilẹ ajọ ti yoo maa ri si idagbasoke nilẹ Yoruba yoo jẹ ki ijọba le pese ohun amayedẹrun fun araalu lawọn ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Bakan naa ni o tun fidi rẹ mulẹ pe idasilẹ ajọ SWDC yoo mu adinku ba iṣoro airiṣẹṣe papaa julọ fawọn ọdọ tori eto naa ni i ṣe pẹlu ipese iṣẹ.

Eleyii to tun dabi rẹ ni pe idasilẹ ajọ SWDC yoo mu ilọsiwaju ba awujọ kaakiri ilẹ Yoruba.

Otunba Gbenga Daniel, sẹnẹtọ to n ṣoju ila oorun ipinlẹ Ogun to ṣagbatẹru abadofin naa sọ pe idasilẹ ajọ SWDC yoo ṣe oniruuru anfaani fawọn eeyan ilẹ Yoruba.

''Aṣeyọri nla ni idasilẹ ajọ SWDC jẹ tori o n ṣapejuwe igba ọtun fun gbogbo ilẹ Yoruba.

Idasilẹ ajọ yii yoo jẹ ki ọrọ pọ si nilẹ Yoruba tori idagbasoke ti yoo mu wa,'' Otunba Daniel lo sọ bẹẹ.

Otunba Daniel ni pẹlu bawọn ọmọ Yoruba ṣe mọ nipa owo siṣe daadaa, o sọ pe ajọ SWDC yoo ran wọn lọwọ lati jẹ ki okowo wọn gbooro si.

O fikun ọrọ rẹ pe ajọ SWDC yoo jẹ ki gbogbo aye ri ilẹ Yoruba gẹgẹ bii ẹkun to n kopa gboogi ninu ilọsiwaju ati idagbasoke Naijiria.

Bayii ni idasilẹ ajọ SWDC ṣe waye

Loṣu Kẹsan an ọdun 2024 ni ile aṣofin agba niluu Abuja fọntẹ lu abadofin fun idasilẹ ajọ SWDC ti yoo maa ri si idagbasoke ẹkun iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria.

Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ ri, Otunba Daniel, sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ila oorun ipinlẹ Ogun lo ṣagbatẹru abadofin ọhun.

Awọn aṣofin to pọju nile aṣofin agba lo buwọlu aba naa, ti ile si fi ṣọwọ si ile aṣoju-ṣofin fun ibuwọlu ti wọn naa.