Ìjíròrò láti dáwọ́ oogun dúró láàárín Israel àti Hamas tún gbérasọ

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Sebastian Usher
- Role, BBC Middle East analyst
- Reporting from, Jerusalem
- Author, Anna Lamche
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ikọ̀ ológun Hamas tin í àwọn faramọ́ ìpè láti fòpin sí oogun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Gaza èyí táwọn orílẹ̀ èdè tó ń dá sí oogun náà ń pè fún.
Ìgbésẹ̀ ọ̀tun yìí yóò pèsè fún Hamas láti tú àwọn èèyàn Israel márùn-ún tó wà ní àhámọ́ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì máa sinmi oogun fún àádọ́ta ọjọ́.
Khalil al-Hayya, tó jẹ́ adarí ikọ̀ Hamas tó dàgbà jù sọ pé àwọn ti buwọ́lu ìwé tí Egypt àti Qatar fi ránṣẹ́ sí àwọn lórí ìpè náà.
Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ pé àwọn ti rí ìlànà náà, tí àwọn náà sì ti fi nǹkan tí àwọn ń fẹ́ ṣọwọ́ sáwọn olùlàjà náà pẹ̀lú àjọṣepọ̀ US.
Tí wọ́n bá buwọ́lu àdéhùn náà, ní ọjọ́ Àìkú tó jẹ́ ọjọ́ ọdún Eid-el-fitr ni dídáwọ́ oogun dúró náà yóò bẹ̀rẹ̀.
Lọ́jọ́ àbámẹ́ta ni Netanyahu sọ pé òun ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olùlàjà náà, táwọn nǹkan tí àwọn bèèrè fún sì jẹ́ ohun tí US fọwọ́ sí àmọ́ kò tu iṣu dé ìsàlẹ̀ kòkò àwọn nǹkan náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni US kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Israel ṣe ìkọlù orí ilẹ̀ sí Rafah, tí wọ́n sì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú jíju àdọ olóró sẹ́kùn Gaza láti ojú òfurufú lẹ́yìn tí ìkọlù ọ̀tun bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìfẹnukò dídáwọ́ ogun dúró tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kìíní.
Nígbà tí wọ́n sinmi ogun nígbà náà, Hamas tú àwọn èèyàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó jẹ́ ọmọ Israel tó wà ní àhámọ́ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì fi àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́ta sí àhámọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wà pé gbogbo kọ́ ló wà láyé mọ́.
Ṣáájú ni Hamas ti kọ́kọ́ gbà láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí bí wọ́n ṣe máa tú àwọn èèyàn Israel tó kù ní àhámọ́ wọn sílẹ̀ àti bí wọ́n ṣe máa fòpin sí oogun náà pátápátá àmọ́ ìjíròrò ọ̀hún kò bẹ̀rẹ̀ rárá.
Israel àti US wòye pé kí wọ́n fi ọjọ́ kún ìgbà tí wọ́n máa dá oogun dúró ní ipele àkọ́kọ́ àmọ́ láì sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ kan pàtó ti oogun náà máa parí.
Israel fẹ̀sùn kan Hamas pé wọ́n kọ̀ láti gbà láti fi ọjọ́ kún ìdádúró oogun náà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ju àdó olóró sí Gaza padà lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹta.
Kò dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rùn-ún èèyàn tó ti jáde láyé láti ìgbà náà gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń ṣe àkóso rẹ̀ ṣe sọ.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn ẹbí àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ Hamas ń fẹ̀sùn kan Netanyahu pé ó ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn wéwu pẹ̀lú bí ó ṣe gbé gbómi ìjà míì kaná pẹ̀lú Hamas.
Ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ Hamas ni Elkana Bohbot tí Hamas gbé fídíò rẹ̀ jáde láìpẹ́ níbi tó ti ń bẹ̀bẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ rẹ̀.
Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni oogun bẹ̀rẹ̀ nígbà ikọ̀ Hamas ṣe ìkọlù sí Israel níbi tí wọ́n ti pa èèyàn 1,200, tí wọ́n sì fi 251 sí àhámọ́.
Israel náà da padà pẹ̀lú ṣíṣe ìkọlù padà, tí wọ́n sì ti pa èèyàn tó lé ní 50,000 gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń ṣe àkóso rẹ̀ ṣe sọ.















